Adájọ́ kú sórí òrùlé Ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́yìn tí wọ́n ní ó pa ìyàwó rẹ̀, tún bá òkú rẹ̀ sún lójú àwọn ọmọ wọn

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Adajọ Evans Zinzombe ti ṣekupa ara lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn n wa a lori ẹsun pe o ṣekupa iyawo rẹ, to si tun ba oku iyawo naa sun niwaju awọn ọmọ wọn.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Zimbabwe fi si ori ayelujara ni adajọ ọhun, ti orukọ rẹ n jẹ Evans Zinzombe, ẹni ọdun mẹrinlelogoji pokunso lori orule ile ijọsin kan to wa ni Bulawayo.

“Iwadii wa fihan pe Adajọ Evans Zinzombe ti a n wa lori ẹsun pe o ṣekupa iyawo rẹ, Phelomina Madika, ẹni ọdun mejilelọgbọn lọjọ keje, ọsu kejila ọdun 2022 ti ṣekupa ara rẹ.

Kini o fa ija tọkọtaya naa?

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Onidajọ Evans ati iyawo rẹ ni ede aiyede kan, eyi to mu ki awọn mejeeji maa sun yara ọtọtọ ninu ile wọn.

Lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, Evans yọlẹ wọ inu yara iyawo rẹ, to si fun un lọrun pa ki o to wa baa ni ajọsepọ niwaju awọn ọmọ meji to wa pẹlu iya wọn.

Igbakeji Kọmisọna ileeṣẹ ọlọpaa, Paul Nyathi ni awọn ọmọ meji naa duro ti iya wọn lẹyin ti baba wọn sa lọ titi owurọ ọjọ Keji, ti awọn si kede pe awọn n wa ọkọ iyawo naa.

Sugbọn oku adajọ Evans ni awọn dede ri lori orule ile ijọsin kan.