Àlátakò jáwé olúborí nínú àtúndì ìbò ààrẹ ní Argentina, àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ bá mújó jó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oloṣelu to n tako ijọba ni orile-ede Argentina, Javier Milei, ti gbe’gba oroke ninu atundi ibo sipo aarẹ nilẹ naa.
Milei ni alatako rẹ ninu eto idibo ọhun to jẹ minisita fun eto ọrọ-aje lorilẹ-ede naa, Sergio Massa, ti pe lati kii ku oriire.
Bakan naa ni aarẹ tẹlẹ ri nilẹ Amẹrika, Donald Trump, ti ki Milei ku oriire, to si wi pe yoo mu ki Argentina o pada ti orilẹ-ede to ga.
Eto idibo to gbe Milei wọle lo waye lakoko ti Argentina n koju iṣoro ọrọ aje ati ọwọn gogo awọn ọja.
Awọn afojusun Milei lakoko ipolongo ibo lo dun mọ awọn araalu to fẹ ayipada ninu, paapaa ju lọ yi to ti sọ pe ohun yoo mu atunto ba banki apapọ ilẹ naa.
Ijawe olubori Milei lo ya awọn onwoye ibo lẹnu nio bo ṣe na oludije to ni atilẹyin ijọba to wa lori aleefa pẹlu ibo to ju idamẹwa gbogbo ibo ti wọn di.
Pẹlu ibo bii ida aadọrun inu ọgọrun ti wọn ti ka, Milei lo ti ni bii ida mẹrindinlọgọta, ti Massa si ni bii ida mẹrinlelogoji ninu ọgọrun.
Ninu ọrọ rẹ si awọn alatilẹyin rẹ nilu Buenos Airess lẹyin to gbọ pe oun ni yoo di aarẹ tuntun, Milei wi pe “atunṣe Argentina bẹrẹ lati oni lọ. Oni ni opin de ba ifasẹyin orilẹ-ede Argentina.
“Argentina yoo pada sipo to tọ sii lagbaye ti ko yẹ ko padanu tẹlẹ. A maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn orilẹ-ede to ku lagbaye lati jẹ ki aye o dar sii.”
Massa to padanu ibo aarẹ, ti ki Milei ku oriire
Kete ti ọgbẹni Massa naa gbọ pe oun ti fidi rẹ’mi lo wi pe “ bo tilẹ jẹ pe irufẹ esi ti a n reti kọ niyii, mo ti pe Javier Milei lati kii ku oriire.
“Lati ọla lọ, ojuṣe mimu ọjọ-ọla Argentina wuyi ti di ti Milei.”
Eto idibo ọhun lo ṣoro fun ẹnikẹni lati sọ ẹni ti yoo jawe olubori lakoko ipolongo ibo ko too di pe Milei fakọ yọ.
Lara ileri ti Milei ṣe lakoko ipolongo ibo ni pe oun yoo sọ owo ti wọn n na ni Argentina di dọla ilẹ Amẹrika, leyi ti awọn onimọ nipa ọrọ-aje ti juwe bii ohun ti yoo tunbọ ko idaamu ba orilẹ-ede naa.
Argentina ni o maa n ri afikun ida ogoje lori owo-ọja lọdọọdun, ti meji ninu eeyan marun si n gbe ninu oṣi.
Ifibo yan Milei ti kii ṣe oloṣelu taara ni awọn onwoye ti wi pe o tunmọ si pe awọn ọmọ orilẹ-ede Argentina fẹẹ gbiyanju ohun ọtun boya yoo san wọn ju oṣelu atẹyinwa lọ.















