George Bush àgbà kúrò nílé ìwòsàn lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́

Oríṣun àwòrán, @Georgebushtwitter
George Bush àgbà di èrò ilé ìwòsàn lọ́jọ́ kejì tó sìnkú aya rẹ̀, Barbara tí wọn jọ gbé pọ̀ fún odidi ọdún mẹ́tàléláàdọ́rin
Ilé iṣẹ́ George Bush àgbà ti fi àtẹ̀jáde síta pé, àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn Methodist Hospital ti fi ààrẹ àná fún ilẹ̀ America sílẹ̀'.
O jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlẹláàdọ́rún.
Wọn ni ara George Bush àgbà ti bàlẹ̀. O tí ń bà àwọn ẹbí àti olùtọ́jú rẹ̀ nílé ìwòsàn sọ̀rọ̀ bí ó ti yẹ









