Dino Melaye wà lọ́nà Abuja fún ìtọ̀jú ara rẹ̀

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @dino_melaye

Àkọlé àwòrán, Dino Melaye gba Abuja lọ fún ìtọ́jú tó péye

Adajo Ajanah Nasir, fún ìpínlẹ̀ Kogi, ti tú Dino Melaye sílẹ̀ pé kó lọ gba ìtọ́jú nile ìwòsàn National Hospital ni Abuja

Àkọlé fídíò, Dino Melaye wà lọ́nà Abuja fún ìtọ̀jú ara rẹ̀

Agbẹnusọ fún Sinetọ Dino Melaye, Ogbẹni Gideon, ṣalaye fun BBC Yorùbá pé, Dino Melaye ti wa lọna Abuja bayii nitori pe ile ẹjọ ti fi i silẹ ko lọ gba itọju ni Abuja.

O ni Adajọ ni ki Dino ṣì wà labẹ ìpamọ́ awọn ọlọ́pàá ni Abuja.

O ni àwọn agbejoro Dino Melaye yoo pada si Lokoja lọ́jọ́ Ajé tó m bọ̀, ki won le lọ gba onídúro ọmọ Melaye bí o ti yẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ogbeni Gideon ni ìdí ti Adajọ Ajanah ṣe pàṣẹ yìí ni pe ilé ìwòsàn àwọn ọlọ́pàá ti wọn gbe Dino si ni Lọkọja kò ni ohun eelò to tó láti fi tọ́ju Dino