Boko Haram: Afurasí agbébọn tó lè ní 300 ní àríwá Nàìjíríà gbà itusilẹ lọ́wọ́ ológun

Nigeria Army

Oríṣun àwòrán, Nigeria army/Facebook

Àkọlé àwòrán, Iko ologun

Awọn ọmọde okoolenigba ati mẹta ti mẹwa ninu wọn jẹ obinrin lo ti gba itusilẹ kuro lọgba ẹwọn Maiduguri lati ọdọ ileeṣẹ ologun Naijiria.

Igbesẹ yi waye lẹyin ti wọn ri aridaju pe wọn ko ni ohunkohun niṣe pẹlu awọn ẹgbẹ agbesunmọmi lagbegbe naa.

Ninu atẹjade kan ti BBC ri gba lati ọwọ ajọ to n risi eto ẹkọ awọn ọmọde labẹ ajọ isọkan agbaye,UNICEF, ileeṣẹ ologun fa awọn to gba itusilẹ yi le ileeṣẹ to n risi ọrọ obinrin ati idagbasoke ni Maiduguri ati awọn oṣiṣẹ UNICEF lọwọ.

Lara awọn ọmọ wọn yi la ti ri awọn ti o ti sọnu to bi ọdun mẹrin si marun un tawọn mọlẹbi si rope wọn ti ku ti pẹ.

''Itusilẹ awọn ọmọ yi gẹgẹ bi ohun ti Peter Hawkins aṣoju UNICEF sọ jẹ ''igbesẹ nla to dun mọ wa ti o si yẹ ki a dunnu si''

O tẹsiwaju pe '' o y ki awọn ọmọde wọn yi ni igbeaye ti ko ni wahala ninu ati pe bayi o yẹ ki a fun wọn ni itọju to peye lẹyin ti ikọlu to waye mu idiwọ ba igbe aye wọn''

O ti pe ọdun mẹwa bayi ti ikọlu Boko Haram ti n waye lariwa Naijiria ti eleyi si ti mu inira ba igbe aye ọgọrọ awọn eeyan lagbegbe naa.

Pupọ ninu awọn to ba kuro lọwọ ologun bayi a ma gba idanilẹkọ ni ile atọnisọna Bulumkutu Rehabilitation Center ni Maiduguri ti wọn a si pada ronupiwada ki wọn to daramọ awọn mọlẹbi wọn.

Lati ọdun 2016, eeyan to le ni gbẹrun mẹta ti a ri ọmọde to fẹ sunmọ ẹgbẹrun meji ninu wọn (Ọkunrin 1,125,obinrin 618)