UI Bursar: Alákoso owó ní Olùyẹ̀wé owó wò wa fọ́ lójú nígbà tó ń ṣe ìṣirò báa ṣe náwó

Oríṣun àwòrán, @willamazen
Alakoso owo Fasiti ilu Ibadan, Micael Alatise ti sọ nile aṣofin kekere pe Fasiti naa ko fi iwe iṣuna rẹ ransẹ si ile ọhun latari pe oluyewe owo to yẹ ko ṣe iṣẹ naa fọ loju lẹnu iṣẹ.
Alatiṣe lo sọ ọrọ naa niwaju igbimọ to n ri si bi awọn ileeṣẹ ijọba ṣe n na owo, ti aṣojuṣofin Oluwole Oke jẹ alaga rẹ.
O ni idi ti Fasiti Ibadan ṣe kuna lati fi eto bi o ṣe nawo ṣọwọ si oluyẹwe owo wo ijọba ni pe, oluyẹwe owo wo to yẹ ko ṣe iwe naa fọ loju lẹnu iṣẹ, to si ku lẹyin naa.
Esi yii jẹ iyalẹnu fun awọn aṣofin nitori pe oluyẹwe owo wo ti wọn n sọ nipa rẹ ọhun ṣi n gba owo iṣẹ titi di ọdun to kọja.
Ọrọ ọhun kọkọ pa awọn aṣofin lẹrin, ṣugbọn wọn koro oju lẹyinorẹyin lori awijare alakoso owo Fasiti naa.
Awọn aṣofin naa wa n bere pe, ti oluyẹwe owo wo Fasiti ọhun ba fọ loju, ṣe gbogbo ileeṣẹ rẹ lo fọ loju ni, ti ko ṣe fi iwe bo ṣe nawo ranṣẹ lati nnklan bi ọdun mẹwaa sẹyin.
Wọn ni ti ọga ileeṣẹ to n yẹwe owo wo ba fọ loju, ko yẹ ki iṣẹlẹ naa da iṣẹ ijọba duro.
Alaga igbimọ ọhun, Oluwole Oke wa pe fun iwaadi kikun lori ileeṣẹ naa, ati iwaadi to jinlẹ lori bi iṣu ṣe ku ti ọbẹ si bu lori eto iṣuna Fasiti naa.












