Adajọ yì ìgbẹ́jọ rẹ̀ padà lóri àtúndi ìbò Adamawa

Ajọ eléto ìdìbò INEC ti pari ètò láti ṣe àtúndi ìbò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Adamawa lọ́jọ́bọ ti ṣe ọjọkejidínlógbọn osùn yìí.
Ikéde yìí wáye lónìí ọjọ ìṣẹ́gun lẹ́yìn ti ilé ẹjo pàṣẹ pe àjọ INEC ní àṣẹ lati ṣe àtúndi ibo nibẹ̀.
Alága àjọ náà n;í ìpínlẹ̀ Adamawa, Kassim Gaidam sàlàyé pé àjọ náà ti ṣe gbogbo ètò tó yẹ láti mú èto náà lọ ni ìrọwọrọsẹ̀ lọ́jọ́ méjì si àsìkò yìí.
Ile ẹjọ kan ní ìpínlẹ Yola ní ìpínlẹ̀ Adamawa ti yí ìgbéjọ to ṣ tẹ́lẹ̀ pada pé àjọ elétò ìdìbò kò lẹtọ láti ṣe àtúndi ìbò gómìnà ní ìpínlẹ̀ náà.
Adájọ Abdul'Aziz Waziri tun dájọ pe ilé ẹjọ náà kò le gbọ ẹjọ ti ẹgbẹ́ òṣèlú Movement for the Restoration and Defence of Democracy (MRDD) pè.










