Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ó ṣeṣe kó jẹ́ pé ará ló sán pa ènìyàn mẹ́ta

Ara san ni oju ofurufu

Oríṣun àwòrán, Dan (catching up) Flikr

Ara ti san pa eniyan mẹta ni ijọba ibilẹ Guusu Ughelli ni Ipinlẹ Delta.

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa, Adeyinka Adeleke sọ fun awọn oniroyin wipe awọn ṣi n fi oju sunukun wo ọrọ naa nitori wipe ko si iwe ayẹwo ile iwosan to fi han wipe ni tootọ ni pe ara san pa awọn oloogbe naa.

Iroyin fi han wipe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni bi aago mẹrin ọjọ Iṣẹgun nigba ti ojo arọọrọda kan rọ ni ilu Otu-Jeremi. Awọn ti ọrọ ṣe oju wọn ni awọn oloogbe naa wa ninu ile kan ti wọn n duro de ojo naa ko da ni ara ba wọ inu ile naa.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àkọlé fídíò, Kloe: Èmi kìí mu òògùn olóró, àmọ́ mo fẹ́ràn láti máa wà lẹ́bà omi

Igba ti awọn aladugbo maa de ibẹ, oku awọn mẹta naa ni wọn ba nilẹ. Ori ko ọkan lara awọn ti àrá naa ba yọ, ṣugbọn wọn ti gbe oku awọn to ku lọ ile iwosan ijọba to wa nilu naa.