DSS: Àwọn ọ̀gá àgbà wo ló ti lo sáà rí lájọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, dss
Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ awuyewuye ló ti n jẹyọ lorí bí Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe yan Yusuf Magaji Bichi sí ipò gẹ́gẹ́ bí Olùdarí àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS.
Àwọn kan fi ẹ̀sùn kan Buhari pé óun ṣe ẹlẹ́yàmẹ̀yà nínú àwọn ìyànsípò rẹ̀, èyí tí kò yọ Bichi sílẹ̀.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ṣùgbọ́n àwọn mì í gbóríyìn fún ìyànsípò nàá.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Àkọsílẹ̀ àwọn tó ti jẹ Olùdarí àjọ SSS láti ìgbà tí wan ti da a sílẹ̀.
Ọ̀gágun Abdullahi Mohammed ni Olùdarí àkọ́kọ́ fún àjọ ẹ̀sọ́ aláàbò Nigeria Security Organisation tó ti di State Security Service (SSS) bàyíì. Ó ṣiṣẹ́ láàrin ọdún 1976 sí 1979.
Alhaji Umaru Shinkafi ni Olùdarí kejì. Òun nàá ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi Olùdarí fún àjọ NSO láàrin oṣù Kẹwàá, ọdún 1979 sí oṣù Kọkànlá, ọdún 1983. Ọmọ ìpínlẹ̀ Sokoto ni.
Mohammed Lawal Rafindadi ni Olùdarí kẹta, òun nàá ló sì kẹ́hìn lásìkò tí àjọ nàá n jẹ́ National Security Organisation, kó tó di pé wọ́n pa orúkọ rẹ̀ dà sí State Security Service. Ọmọ ìpínlẹ̀ Katsina ni.
Alhaji Ismaila Gwarzo : Ọmọ ìpínlẹ̀ Kano Aliyu Ismaila Gwarzo. Nínú oṣù Kẹfà, ọdún 1986 ni Ọ̀gágun Ibrahim Babangida yàn án sípò gẹ́gẹ́ bi Olùdarí àgbà fún àjọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ State Security Service tuntun. Ó sì ṣiṣẹ́ láàrin ọdún 1986 sí oṣù Kẹ́sàn án, ọdún 1990.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Albert Korubo ni Olùdarí àjọ State Security Service (SSS) karùn ún. Ọmọ ìpínlẹ̀ Rivers ni. Ó ṣiṣẹ́ láàrin oṣù Kẹsàn án, ọdún 1990 sí oṣù Kẹwà, ọdún 1992.
Chief Peter Nwaoduah: Abẹ́ ètò ìṣàkóso Ọ̀gágun Sani Abacha ló ti jẹ ọ̀gá àgbà SSS láàrin ọdún 1992 sí 1998.
Lateef Kayọde Arẹ ni Olùdarí àjọ SSS láàrin ọdún 1999 sí 2007. Ààrẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ ló yàn án sipò. Ó wà ní ipò nàá láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ètò ìṣàkóso Ọbasanjọ.
Afakriya Gadzamaló gba ipò lọ́wọ́ Kayọde Arẹ. Nínú oṣù Kẹjọ, ọdún 2007 ni olóògbé Umaru Yar'Adua yàn án sípò. Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Borno ni. Ọjọ keje, oṣù Kẹsàn án ni,Alhaji Umaru Shinkafi ọdún 2010 ni Ààrẹ àná, Goodluck Jonathan gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
Ita Ekpeyong: Oṣù Kẹsàn án, ọdún 2010. Níkété tí wọ́n gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ni Goodluck Jonathan yàn án sípò lẹ́yìn tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Afakriya Gadzama. Ó ṣiṣẹ́ láàrin ọdún 2010 sí 2015. Ọmọ ìpínlẹ̀ Cross River ni. Níkété tí Ààrẹ Muhammadu Buhari dé ipò ló yọ ọ́ nípò.
Lawal Musa Daura: Òun ló rọ́pò Ekpeyong nínú oṣù Kẹsàn án, ọdún 2015. Ó di ipò nàá mú títí di ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Keje, ọdún 2018, tí Adelé Ààrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Ọṣinbajo dáà dúró lẹ́yìn wàhálà tó wáyé nílé aṣòfin. Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Katsina ni.
Matthew Seiyefa: Lẹ́yìn ìyọnípò Daura ní Ọṣinbajo yàn án gẹ́gẹ́ bi adelé Olúdarí Àgbà fún àjọ SSS. Ó ṣiṣẹ́ títí di ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Kẹsàn án, ọdún 2018 tí Ààrẹ Buhari yan Yusuf Magaji Bichi sípò nàá. Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Bayelsa níì ṣe.
Yusuf Magaji Bichi: Ààrẹ Muhammadu Buhari yàn án sípò nàá lọ́jọ́ kẹtàlá, oṣù Kẹsàn án, ọdún 2018.














