Ethiopia: Bíi ti Zimbabwe, àdó olóró mìíràn bú ní Ethiopia
Àwọn alaṣẹ orilẹede Ethiopia ni eniyan meji ni o ku ti awọn ogunlọgọ si f'ara pa lẹyin ti ado oloro kan bu gbamu nibi iwọde fun olori orilẹede naa tuntun, Abiy Ahmed.
Abiy ṣẹṣẹ ba awọn ero sọrọ tan nibi iwọde naa, ni ado oloro ọhun dun. O ṣe apejuwe iṣẹlẹ naa bii iṣe ọwọ awọn ti ko fẹ ki Ethiopa ṣ'ọkan.
Wọn tete gbe e sa lọ lẹyin ti eniyan kan ju ado oloro naa si aarin awọn ẹgbẹgbẹrun awọn oluwọde to wa ni orita Meskel to wa ni olu ilu orilẹede Ethiopa, Addis Ababa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ko ju bii wakati melo kan lọ ti ori ko aarẹ orilẹede Zimbabwe Emmerson Mnangagwa yọ lọwọ ado oloro ti ti Ethiopa naa ṣẹlẹ.
Ni kete ti iṣẹlẹ naa waye ni wọn fi olori ile iṣẹ olopa ti Addis Ababa si atimọle pe ko ṣe iṣẹ rẹ to.
Wọn tilẹ tun fi ọlọpàá mẹjọ si atimọle pẹlu rẹ. Wọn ni wọn o yẹ ki wọn ṣọ ibi iwọde naa daadaa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Minisita fun Eto Ilera ni Ethiopia sọ pe eniya bii mẹrinlelogoji ni o wa ni ile iwosan bayi ti eniyan marun si wa ni ẹsẹ-kan-aye-ẹsẹ-kan-orun.
Abiy di olori orilẹede naa lẹyin ti olori ti tẹlẹ Hailemariam Desalegn, kọ'we f'iṣe silẹ ni oṣu keji ọdun yii.














