UN: Nàíjíríà, ẹ sọ ìlò igbó fún ìwòsàn di òfin

Igbo gbigbẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, UN sọ̀ fún Nàíjíríà, pé kí ó sọ lìlò igbó fún ìwòsàn di òfin

Ní ọjọ́ ajé ni àjọ ìsọ̀kan orílẹ̀èdè àgbáyé (United Nations) ní, òun ti fòǹtẹ̀ lu ìlò èròjà igbó fún ìwòsàn, tó sì rọ orílẹ̀èdè Nàíjíríà láti dẹ ọwọ́ lóríi òfin tó de fífi ọwọ́ sí ìlò igbó bíi òògùn fún ìwòsàn àwọn èèyàn.

Bákannáà ló ní dípò ká máa fi òfin ìwà ọ̀daràn de lílò òògùn olóró, ńse ló yẹ kí orílẹ̀èdè Nàíjíríà máa fojú aláìsàn wo àwọn èèyàn tó bá kúndùn igbó mímu, ká sì sètọ́jú wọn bọ ti yẹ.

Níbi ìjókòó ìta gbangba kan tí ìgbìmọ̀ tó wà fọ́rọ̀ òògùn olóró nílé asòfin àgbà ilẹ̀ wa gbé kalẹ̀ ni asojú kan fún àjọ ìsọ̀kan àgbáyé, Harsheth Kaur Virk, ti gbé ìmọ̀ràn yìí kalẹ̀.

Ìdí rèé tí BBC Yorùbá se fẹ́ mọ èrò àwọn aráàlú nípa ìmọ̀ràn yìí àti ipa tí yóò ní lóríi ìlera àwọn ọmọ̀ orílẹ̀èdè Nàíjíríà lápapọ̀.

Amin iyasọtọ kan

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Amin iyasọtọ kan

Lérò Dókítà Kúnlé Òbílàdé, tíí se onísègùn òyìnbó, ó ní àmúsẹ òfin yìí yóò lẹ́yìn tó burú fún ìlera àwọn ọmọ Nàíjíríà.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Dókítà: Kò dára ká sọ ìlò igbó fún ìwòsàn di òfin

Sùgbọ́n onímọ̀ kan nípa ìdènà àwọn òògùn olóró ní orílẹ̀èdè Nàíjíríà, tó fẹ́ ka fi orúkọ bo òun ní àsírí sàlàyé pé kò sí ohun tó burú nínú àbá náà, orílẹ̀èdè Nàíjíríà ni yóò dènà irúfẹ́ àwọn èèyàn tí yóò ní ànfààní sí èròjà igbó.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Onímọ̀ kan ńfẹ́ kí Nàíjíríà lo igbó fún ìwòsàn

Àmọ́ èyí tó wù kó jẹ́, ó yẹ kí á se ohun gbogbo ní ìwọ̀n tunwọ̀nsì.