Ẹsa ninu aworan Afrika: 9-15, ose kẹta ọdun 2018

Ẹsa ninu awọn aworan to rẹwa ju l'Afrika ati aworan awọn ara Afrika nibomiran lagbaye ninu ọse yii.

Wọn gbe ọkọ kan si waju ile alarabara kan ni adugbo itan Bo Kaap to wa ni igboro Cape Town, lorilẹede South Africa, lọjọ kẹdogun 15 osu kẹta ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ọkọ yii yatọ ni adugbo itan Bo Kaap nigboro Cape Town. Adugbo naa jẹ ibudo itan aṣa Malay nigboro Cape Town, osi jẹ ibudo mọṣalasi akọkọ ni orilẹede South Africa eleyi ti awọn ajeji kọ lọdun 1884 , gẹgẹ bi ileese iroyin EPA ṣe sọ.
Wọn ran ọkunrin kan lati sọkalẹ lati ori ọkọ nla kan ti agba gbe danu ni ilu Isinya to to ogoji mẹli si gusuu ila-oorun Nairobi lọjọ kẹdogun osu kẹta, ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọkọ-akẹru yii da bii ẹni pe ọkan rẹ balẹ lẹyin igba ti agba gbe danu nilu Isinya, to to ogoji mẹli si olu ilu Kenya, Nairobi...
Awọn eeyan n wo agba bo ti n sare lọ lapa kan ọna marose ilu Isinya to sunmo ẹnu ala Kenya pẹlu orilẹede Tanzania lọjọ kẹdogun osu kẹta, ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Omi sọ ọna marose ilu naa di odo..
Awọn ọmọ ile-iwe Kenyan kan pejọ ni waju ita yara ẹkọ wọn ni ile iwe girama Isinya, to jẹ kilomita mẹjindinlọgota si gusuu ila-oorun Nairobi lọjọ kẹẹdogun osu kẹta, ọdun 2018

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Sugbọn awọn ọmọde wọn yii saasala kuro nibi ojo naa.
Ọmọkunrin kan ba awọn eye kan ṣere ladugbo Yoff, to wa ni Dakar,lorilẹede Senegal lọjọ kẹrinla osu kẹta, ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọmọkunrin kan ni orilẹede olu ilu orilẹede Senegal, Dakar, da bi ẹni to n ṣọra fun awọn eye kan ti wọn kọja lọ l'Ọjọru (Wednesday).
Ọkunrin kan kopa ninu iwọde kan ti wọn ṣe lati tako eleyamẹya at lati satilẹyin fun Idy Diene, ontaja ilẹ Senegal kan ti ọmọ ilẹ Italy kan pa nigboro Florence, lorilẹede Italy lọjọ kẹwa osu kẹta , ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, l'ọjọ Abamẹta, awọn eeyan ṣe iwọde l'awọn oju opoponaa igboro Floreence ni orilẹede Italy lati fi ẹhonu han lori pipa ọmọ orilẹede Senegal kan to n taja, Idy Diene.
Awọn ajafẹtọ kegbajare nigba iwọde kan nibi ti wọn ti n ja f'ẹtọ ij'ogun kan naa pẹlu ọkunrin f'awọn obirin ni Tunis, orilẹede Tunisia lọjọ kẹwa osu kẹta, ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, L'ọjọ kan naa, awọ eeyan ni orilẹede Tunisia ṣe iwọde lati ja fun ẹtọ awọn obirin nibi didọgba ninu ogun pinpin.
Awọn ọdọ Fulani tẹtibẹlẹjẹ nigba ifẹhonuhan kan ni Bamako l'ọjọ kẹẹdogun osu kẹta, ọdun 2018 ẹgbẹ Jeunesse Tabital Pulaaku-Mali, to n ja f'ẹtọ awọn Fulani ilẹ Mali, ṣeto lori ikọlu to ṣẹlẹ ni ipinlẹ Plateau ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, L'orilẹede Mali, awọn Fulani yii n ṣe iwọde ni olu ilu orilẹede naa, Bamako, l'Ọjọbọ (Thursday) lori ikọlu laarin awọn daran-daran Fulani ati awọn agbẹ oloko ni aringungun Naijiria.
Salem,ọkunrin ilẹ Tunisia kan to jẹ ẹni ọdun marundinlaadọta (45), n dari awọn ẹran rẹ nilu Mdhila, to wa ni gusuu Gafsa, ọkan lara awọn ibuwa nnkan alumọni ni aarin gungun Tunisia. Wọn ti bẹrẹẹ iṣẹ lẹyin igba ti wọn da iṣẹ silẹ fun oṣu kan, lọjọ kẹsan oṣu kẹta, ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Darandaran yii n dari awọn ẹran rẹ lode ilu Mdhila, ọkan lara awọn ibuwa nnkan alumọni ni orilẹede naa , nibi tawọn oṣiṣẹ ti pada s'ẹnu iṣẹ lẹyin igba ti wọn da'ṣẹlẹ fun oṣu kan.
Rebecca Palai n ba dokita kna sọrọ nigba to na gba ogun lori ẹrọ afunnilogon kan maa n fun awọn alaisan ti aisan wọn kii gb'ogun bọrọ ni anfani ati gba ogun laarin isẹju mẹta-mẹta, nigboro Alexandra, lorilẹede South Africa., lọjọ kẹẹdogun osu kẹta, ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, L'ọjọ kannaa , Rebecca Palai n ba dokita kan sọrọ lori fonu nigba to n gba ogun lati ẹrọ ifunnilogun kan. Ẹrọ afunnilogun naa maa n fun awọn alaisan ti aisan wọn kii gb'ogun bọrọ ni anfani ati gba ogun laarin isẹju mẹta-mẹta, nigboro Alexandra, lorilẹede South Africa.
Agbegilere Kenya, sculptor Edward Njenga (lapa ọtun), ti wọn bi lọdun 1922, o n tun ere okuta rẹ ("Women"s Guild Member (2008)") ṣe pẹlu atilẹyin ọmọ rẹ Edward Njenga, to n jẹ orukọ kannaa pẹlu rẹ nileese rẹ to wa ni Nairobi l'ọjọ kejila osu kẹta, ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, L'ọjọ Aje (Monday), gbajugbaja agbegi-lere Kenya, Edward Njenga (lapa ọtun), ti wọn bi l'ọdun 1922, o n tun ere okuta rẹ ti wọn pe ni Women's Guild Member ṣe pẹlu atilẹyin ọmọ-ọmọ rẹ, ti orukọ rẹ naa n jẹ Edward Njenga, ni ileese rẹ ni Nairobi.
Ọkunrin kan n wo awọn iwe kan ninu awọn apoti ti wọn n lo lati ko awọn ohun ija pamọ nigba ogun, ni Misrata, Libya, lọjọ kẹtala osu kẹta , lọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọkunrin kan n wo awọn iwe tita ninu awọn apoti ti wọn lo lati ko ohun ija pamọ tẹlẹ nigba ogun abẹle Libya ni igboro Misrata to wa ni Libya l'ọjọ Iṣẹgun (Tuesday).
Awọn ọmọ Libya wọ aṣọ ibilẹ wọn nibi ayajọ ọjọ aṣọ aṣa Libya nibudo Martyrs Square to wa ni, olu ilu Libya Tripoli, lọjọ kẹtala osu kẹta, ọdun 2018

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, L'ọjọ kan naa , awọn ọmọ orilẹede Libya yii n s'afihan aṣọ aṣa wọn lọjọ ayajọ aṣọ ibilẹ Libya ni olu ilu wọn, Tripoli.

Awọn aworan yii wa lat'ọdọ AFP, Reuters, EPA ati Getty Images