Lagos Airport: Ó yẹ́ ká gbóríyìn fún àwọn akọni méji tó dá bààgi padà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìrèti ṣì ń bẹ fún orílẹ̀èdè Nàìjíríà, nítorí kìí ṣe gbogbo ènìyàn náà ní ìwà àjẹbánu ń dà láàmú.
Ní pápákọ̀ òfurufu ìlú Eko ní àwọn òṣìsẹ́ alámojútó ààbò méjì nínú ọgbà náà ti fakọyọ tí wọn si gbé ounjẹ fẹ́gbẹ́ gbàwo bó lọ́dọ̀ ààrẹ Muhammadu Buhari bi ó ṣe gbóríyìn fún wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn òṣìṣẹ́ ààbo náà rí báàgi ẹnìkan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti òkè okun tí wọn si wá ẹni náà kan láti dáa padà
Francis Emepueaku àti Achi Daniel, tó rí báàgi ọ̀hún ríi dáju pé wọ́n dáa pada fún olóhun, láì yọ ohunkohun nínú rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kò tíì ju wákàtí kan àti ààbọ lọ tí ọmọ orílẹ̀èdè yìí kan dé tó si gbàgbé bààgì rẹ̀ sí pápákọ̀ ofurufú lọ́jọ́ satidé ọjọ kejidinlogun osù yìí nígbà ti àwọn aláṣẹ ibẹ̀ pè é pé kó wá gbé báàgì rẹ̀.
Nígbà to gba báàgì ọhun tó sì yẹ̀ẹ́ wò ní o ríi pé gbogbo ǹkan òun pátá ló pe síbẹ̀ tó fi mọ owo dọ́là tabua, fóònù àti ààgo ọwọ́.
Ọkọ àti ìyàwó náà fun Francis àti Daniel ní ẹ̀bun sùgbọn wọn ò gbàá, wọn ni iṣẹ́ àwọn ní àwọn ń ṣe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìgbésẹ̀ àwọn ènìyàn yìí ló wú ààrẹ Muhammadu Buhari lórí tó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. O ní òtítọ́ ló ṣe pàtàkì jùlọ nínú ohun gbogbo, o fi kún un pé àwọn òṣìṣẹ́ méjèèjì huwa ọmọluabi.
Nínú àtẹjáde kan tí ààrẹ fi síta lati ọwọ́ olùrànlọwọ pataki rẹ̀ Femi Adeshina, o ní ó ṣe pàtàkì kí àwọn ọmọ Nàìjíríà wọ àwòkóṣe Francis àti Daniel.













