Pinnick: Danny Jordaan láti South Africa ló rọ́pò rẹ̀

Amaju Pinnick

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n mojuto bọọlu afẹsẹgba nilẹ Afrika, CAF, ti gba iṣẹ lọwọ Amaju Pinnick, ọmọ orilẹede Naijiria, gẹgẹ bi igbakeji aarẹ wọn, ti wọn si fi Danny Jordaan lati orilẹede South Africa rọpo rẹ.

Pinnick jẹ igbakeji aarẹ ajọ CAF akọkọ lati oṣu Keje ọdun 2018.

Aarẹ CAf, Ahmad ko sọ idi kankan ti wọn fi gba iṣẹ lọwọ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lori iṣẹlẹ yii, Pinnick ti fesi. O ni 'Lati ṣiṣẹ isin gẹgẹ bi igbakeji aarẹ ninu idari ere bọọlu gbigba ni Afrika jẹ anfaani nla fun mi."

"Ẹmi ifọkansin ti mo si ni fun ere bọọlu ṣi wa sibẹ, atilẹyin fun awọn akẹẹgbẹ mi ninu igbimọ oludari ko ni i dinku."

Bi Pinnick ṣe kuro yii tumọ si pe Ahmad yoo ṣe atunto awọn igbakeji rẹ. Eyi tumọ si pe Constant Omari lati orilẹede DR Congo ati Faouzi Lekjaa lati Morocco yoo kuro ni ipo keji ati ikẹta bọ si oke.

Jordaan ti wọn ṣẹṣẹ yan yoo wa ni ipo kẹta.