Mikel Obi: Orílẹ̀èdè Egypt ni mo ti bẹ̀rẹ̀ ayò, ibẹ̀ náà ló parí sí

Oríṣun àwòrán, Instagram/John Obi Mikel
Eyi ti mo ṣe to! Ọrọ yi ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu ọkunrin Naijiria, John Mikel Obi sọ l'Ọjọbọ.
Balogun Super Eagles, Mikel to fọrọ naa lede loju opo Instagram rẹ, sọ pe, asiko ti to fun oun lati fi ikọ agbabọọlu Naijiria silẹ.
Mikel fi fọto ara rẹ soju opo Instagram, o sọ pe orilẹede Egypt loun ti bẹrẹ si soju Naijiria, nibẹ naa si ni oun pari rẹ si.
O sọ pe ni Egypt lọdun 2006 loun ti ṣoju Naijiria ninu idije AFCON fun igba akọkọ, bakan naa ninu idije AFCON 2019 loun ti fi adagba rọ bọọlu gbigba fun Naijiria si.
Mikel dupẹ lọwọ Naijiria fun anfani lati ṣoju orilẹede rẹ ninu oniruuru idije ere bọọlu.

Oríṣun àwòrán, Instagram/John Obi Mikel
Mikel ni oun gbe igbesẹ lati fi ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria silẹ lati fun awọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu laaye.
O ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles gbiyanju ninu idije AFCON 2019, lẹyin ti wọn gba ami ẹyẹ baba(Bronze) tii ṣe ipo kẹta.
Naijiria na Tunisia pẹlu ami ayo kan sodo l'Ọjọru lati gba ipo kẹta.












