FaceApp: Ǹjẹ́ ẹwu wà nínú lílò ẹ̀rọ yìí?

Oríṣun àwòrán, Laide Bakare
Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti n lọ lori lilo ẹrọ to n pa ọjọ ori ẹni da FaceApp, ti o le mu ki aworan eniyan kere sii ni ọjọ ori, abi ki o dabi arugbo.
Oju opo Instagram ti kun pitimu bayii fun fọto awọn oṣere tiata, ti wọn parada di arugbo, amọ ṣe ewu kankan wa ninu lilo ẹrọ yii?
Iwadii fihan wi pe ile isẹ to gbe ẹro naa jade ko sọ fun awọn eniyan lẹkunrẹrẹ wi pe awọn fọto wọn ti wọn ba fi sori ẹrọ FaceApp yoo wa lọwọ wọn fun igba pipẹ.
Imọ ẹrọ artificial intelligence (AI) ni wọn n lo lati fi ma a se atunse oju, enu ati ẹrẹkẹ awọn fọtọ ti wọn ba lo.
Ṣáájú, wọn ti fẹsun kan wọn wi pe wọn n lo awọn fọto ti awọn eniyan ba fi sori erọ FaceApp lati fi da oju awọn eniyan mọ, tabi se iwadii wọn.

Oríṣun àwòrán, Odunlade Adekola
Bakan naa ni olori ẹgbẹ oselu to kereju ni Ile Igbimọ Asofin Agba ni orilẹede Amerika, Chuck Schumer ti ke si ẹka to n sewadi lorilẹede naa, FBI lati se iwadii ile isẹ FaceApp to jẹ ti orilẹede Russia.
Amọ adari ile isẹ naa, Yaroslav Goncharov sọ fun BBC pe awọn ko lo fọto awọn eniyan lati ori ẹrọ ibanisọrọ wọn, wọn ni awọn n lo eyi ti wọn ba fi si ori ẹrọ wọn lati fi pamọ.
Ẹrọ FaceApp le mu ẹni ti o ba le oju koko, ki o dabi ẹni to ba n rẹrin, bakan naa ni o le mu ẹni ti o ba darugbo, jọ ọdọ.
Bakan naa ni ohun sọ awọn ọdọ pada si arugbo, ti wọn ba ti fi aworan wọn si ori ẹrọ naa.













