Iree Osogbo Bank Robbery: Ara olóògbé Dauda Jelili Kayode ti wọ káà ilẹ̀ lọ ní Iree

Lẹyin ti ileewosan ti fidiẹ mulẹ pe sajẹnti ọlọpaa ti awọn adigunjale pa sileeṣẹ ọlọpaa ni ilu Iree lọjọ ru naa ni wọn sin in.Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Osun bínú yabo iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ìdigunjalẹ̀ tó gba ẹ̀mí eèyàn ní Iree

Ana, ọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ, ọdun 2021 ni wọn gbe oloogbe Dauda Jelili Kayode wọ kaa ilẹ lọ.

Ilu Iree nibi to ti n ṣiṣẹ ti o ti ku iru iku yii naa ni wọn sin Dauda Jelili Kayode si.

Tẹbi tara ati iyekan lo peju sibẹ pẹlu omije kikoro loju wọn.

Awọn alaba ṣiṣẹ rẹ naa royin iwa akọni to ni pe o ṣeni laanu pe nibi ti yoo ba lọ ni ẹnu iṣẹọba to n ṣe.

Awọn olugbẹ ilu Ire ni ipinlẹ̀ Osun ti yabo ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni ilu na pẹlu ibinu.

Wọn ṣe iwọde de ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Iree lẹyin ti awọn adigunjale yabo banki UBA ati Access Bank nibẹ ti wọn si ṣọṣẹ.

Ninu idigunjale naa ni ẹmi agbofinro kan ti ba iṣẹlẹ naa lọ ni irọle ana, ọjọbọ, ọjọ karun un, oṣu kẹjọ, ọdun 2021.

Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Osun bínú yabo iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ìdigunjalẹ̀ tó gba ẹ̀mí eèyàn ní Iree

Awọn adigunjale naa lo fi ibọn pa ọkunrin naa ni agọ ọlọpaa to wa nitosi ibẹ lati fi le awọn agbofinro kuro ni agbegbe naa ki wọn to ṣoṣẹ.

Awọn olugbe Iree binu nitori lati nkan bii aago mẹrin ni wọn ni awọn oniṣẹ ibi naa ti bẹrẹ iṣẹ nibẹ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nibẹ, Yemisi Opalola fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lẹyin to ni awọn akọṣẹmọṣẹ agbopfinro ti bẹrẹ iṣẹ nibẹ bayii.

O ni awọn ọlọpaa n fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹgbẹ Olọdẹ ibilẹ ati awọn ẹgbẹ alaabo mii nibẹ bayii.

Awọn ti iṣẹlẹ ibinu awọn ara ilu ṣoju wọn sọ pe awọn ara ilu kan n ṣe iwọde alaafia ni.

Ati pe wọn ko ba nkan ini ilu kankan jẹ.

Bẹẹ naa ni wọn ko ṣe ọlọpaa kankan ni ijamba.

Wọn ni wọn ti gbe oku Sajẹnti ọlọpaa ti awọn adigunjale pa naa lọ si aagọ ọlọpaa miran ni Ikirun.

Kọstabu ọlọ́pàá ni awọn adigunjale pa ní ìlú Ire ti wọ́n ti fọ BankiAkọroyin BBC ti fidi ọrọ mulẹ fun BBC pe kọstabu ọlọpaa ni awọn adigunjale to ṣọṣẹ ni Banki meji kan ni ilu Ire.

Bakan naa lo fi kun pe ibọn ba asọna banki ti Access naa sugbọn o ti n gba itoju nile iwosan.Nibayii eniyan kan lo ku nibi iṣẹ̀lẹ̀ naa ti eniyan kan si wa ni ile iwosan.

Àwọn adigunjalè ṣọṣẹ ni Banki méjì nípìnlẹ̀ Osun.

Àwọn adigunjale kan ti lọ kọlu ile ifowopamọ meji ni ilu Iree ni ipinlẹ Osun.

Gẹgẹ bi akọroyin BBC to debi iṣẹlẹ naa ṣe sọ ibọn ba okunrin kan ti wọn si ri oku rẹ nilẹ, bi o tilẹ jẹ pe ko si ẹni ti o ti le sọ iye eniyan ti o ti ba iṣẹlẹ naa rin.

Awọn ti isẹlẹ naa ṣẹ loju wọn salaye pe akẹkọọ ni ọmọkunrin ti ibọn ba naa sugbọn ko si ẹni to tii mọ eni to jẹ.

Wọn fi kun pe awọn adigunjale naa dede yabo ile ifowopamọ UBA ati banki miiran ni agbegbe ijoba ibile Boripe.

Bakan naa ni wọn fi kun pe ilu Ada ni wọn gba salọ.

Ninu awọn ti ọrọ soju wọn ohun, bi awọn kan se n fidi rẹ mulẹ fun akọroyin wa pe awọn ri pe ọkọ meji ni wọn gbe wa ni awọn miiran sọ pe ọkọ mẹta ni wọn gbe wa titi di asiko yii ko si ẹni to mọ iye wọn.

Agbesnusọ ọlọpaa ipinlẹ Osun SP Yemisi Opalola fidi ọrọ naa, o si fi kun pe awọn ikọ ọlọpaa ti le awọn adigunjale naa lati se awari wọn.