You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá paná ìpayà ìdúnkokò mọ́ ààbò nílé ẹ̀kọ́ kan l'Eko
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ṣalaye bi wọn se pana ibẹru to gbinlẹ lẹyin ti awọn afurasi agbebọn fi atẹjisẹ Whatsapp ransẹ si pe wọn yoo kọlu ile ẹkọ meji ni agbegbe Ikeji nipinlẹ Eko.
Ni atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Abimbola Adebisi fi lede ni deede ago mẹrin ni awọn alasẹ ile ẹkọ aladani meji naa kesi ileeṣẹ ọlọpaa ni Ikeja pe awọn gba atẹjisẹ kan loju opo Whatsapp lati ọdọ nọmba kan naa.
Iṣẹlẹ yii waye ni ọjọ kọkanlelogun oṣu kinni ọdun 2026, ti ileeṣẹ ọlọpaa si suure lọ si ile ẹkọ mejeeji pẹlu awọn irinsẹ ati awọn onimọ lati ẹka Command's Explosive Ordnance Disposal, Chemical Biological Radiological and Nuclear (EOD-CBRN), the Rapid Response Squad (RRS), ati awọn ikọ mii to n ṣe iwadii lori ado oloro.
Abimbola ni lẹyin ọpọ iwadii ati ọfintoto ileeṣẹ ọlọpaa, wọn ko ri ado oloro kankan ni agbala ilẹ ẹkọ aladani mejeeji, ti wọn si ni ki awọn ilẹ ẹkọ pada si yara ẹkọ wọn, ki wọn si tẹsiwaju ninu gbigba ẹkọ.
"Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ ni kiakia lati ṣawari ibi ti atẹjisẹ naa ti wa, ki wọn si foju wina ofin."
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa tun fi da awọn ob, awọn alaṣẹ ileẹkọ ati awọn alagbatọ loju pe wọn yoo ri daju pe wọn pese aabo to peye lati da aabo bo ẹmi ati dukia.
Kọmisana tun rọ wọn ki ri daju wọn pe n kesi ileeṣẹ ọlọpaa lẹsẹkẹsẹ ti wọn ba kẹfin ohun kohun to ba sokunkun si wọn ni agbegbe wọn.