You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Olubadan Rashidi Ladoja sọ̀rọ̀ lórí ìpèníjà àbò ní Nàìjíríà, Ó ní ó ti ń pẹ́ nílẹ̀ jù
Olubadan ti ilẹ Ibadan, Oba Rasidi Adewolu Ladoja ti bu ẹnu atẹ lu bi iṣoro eto aabo ṣe ti n ba orilẹede Naijiria finra fun igba pipẹ.
Oba Ladoja sọ eyi nigba to n sọrọ nibi eto ayẹyẹ ọdun kẹtalelogun idasilẹ ileeṣẹ iroyin Daily Trust Dialogue to waye niluu Abuja, lọjọbọ.
Olubadan ni alejo pataki nibi ayẹyẹ naa.
Nigba to n fesi si ọrọ minisita fun ọrọ oke okun pe iṣoro eto aabo ni Naijiria fi si ibi kan ju ibi kan lọ, Oba Ladoja ni iṣoro yii ti wa fun igba pipẹ.
Bi ẹ ko ba gbagbe, minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Naijiria, Tuggar ti kọkọ ṣalaye ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin ilẹ okeere kan pe iṣoro eto aabo to n ba Naijiria finra jẹ eyipe awọn apa ibi kan lo ti wọpọ ju, ti awọn eeyan lati ita si n fi oju ti ko da wo orilẹede Naijiria.
"Mo gba ọrọ to sọ, ṣugbọn o ti n pẹ ju. Ko si ẹnikẹni to n gbe pẹlu ifọkanbalẹ. O ko mọ ibi ti ikọlu yoo ti waye," Olubadan ṣalaye.
Olubadan fikun pe ko yẹ ki ijọba fi oju ọrọ ẹṣin wo iṣoro eto aabo to n ba Naijiria fin.
"N ko gba pe ọrọ ẹṣin ni. Ko ki n ṣe. Ṣugbọn awọn eeyan kan fẹ ko da bi pe ọrọ ẹṣin ni fun ere ti wọn.
Awọn eekan mi to wa nibi ayẹyẹ nii aarẹ ile igbimọ aṣofin nigba kan ri, Bukola Saraki, Gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Malam Nasir El-Rufai, ati ọmọ ile igbimọ aṣofin nigba kan ri, Hon. Nnenna Elendu Ukeje.