Mà á dupò gómìnà Oyo ní 2027 – Oriyomi Hamzat

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajumọ sọrọsọrọ ori Redio, Oriyomi Hamzat, ti kede erongba rẹ lati dupo gomina ipinlẹ Oyo ninu idibo apapọ ọdun 2027.

Ana ode yii ti i ṣe Satide, ọjọ Kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni Oriyomi kede erongba rẹ naa, pẹlu alaye pe ẹgbẹ Accord ni oun yoo ti dije.

'Mo n kede erongba mi lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Accord lonii, ati lati kede fun gbogbo eeyan pe Oriyomi Hamzat yoo wa ninu iwe idibo ni ọdun 2027"

Bẹẹ ni Oriyomi Hamzat sọ nibi eto naa ti ọpọ eeyan ti wọn jọ wọ aṣọ ẹgbẹ Accord wa.

Aṣọ ti wọn ya aworan Oriyomi Hamzat si, ti wọn si kọ ''Oyo n pe ọ" si lara ni awọn eeyan naa wọ nibi ikede ọhun.

Ninu fidio kan to ṣafihan ikede naa ni olorin kan ti n ki sọrọsọrọ ori redio naa, to n pe, 'to ba di gomina lọla ẹ ma ba wi, iṣẹ Oluwa a wa ma ridii ni.''

Tẹ o ba gbagbe, ọdun to kọja ni Hamzat ti n sọ pe oun yoo dupo gomina ipinlẹ Oyo, nitori awọn eeyan kan n polongo rẹ pe ipo naa tọ si i pupọ.

Ṣugbọn ero awọn ẹlomiran ṣọtọ lori erongba Oriyomi yii. Wọn ni ipo gomina ki i ṣe nnkan awada, o si yatọ gedegbe si ẹ gbẹnu si maiki ti Oriyomi n ṣe lori redio rẹ n'Ibadan.

Amọ sorọsọrọ naa ti ni oun ko polongo ibo fun oloṣelu kankan mọ, oun gan-an fẹ dije bayii, ipo gomina Oyo si ni oun n lọ.

Ta a ni Oriyomi Hamzat?

Oriyomi Abdulrahman Hamzat jẹ ilumọka sọrọsọrọ ati ajafẹtọọ ọmọniyan to ni ileeṣẹ redio ti wọn n pe Agidigbo Fm, niluu Ibadan.

Hamzat ni wọn bi niluu Ibadan nipinlẹ Oyo, baba rẹ, Asimiyu Adekunle Hamzat, naa jẹ akọroyin pẹlu ileeṣẹ Nigerian Television Authority (NTA).

Hamzat lo si ile ẹkọ girama Iroko Community Grammar School ko to morile ile ẹkọ giga Oyo State School of Sciences.

Bakan naa lo ti gba oye Diploma ninu Geology lati ile ẹkọ Gbogbonise to wa niluu Ibadan.

O tun tẹsiwaju lati gba oye ninu eto ẹkọ Mass Communication lati ile ẹkọ Adeseun Ogundoyin niluu Eruwa.

Ni oṣu kọkanla ọdun 2023, Hamzat tun gba iwe ẹri lati ile ẹkọ giga fasiti ilu Ibadan fun imọ ninu ẹkọ Linguistics and Language Arts.

Oṣu Kejila ọdun 2024 ni oun ati Olori Ọọni Ile ifẹ tẹlẹ, Naomi Ogunwusi, jọ di ẹni to foju bale ẹjọ lori ẹsun awọn ọmọ to di oloogbe, nibi eto ifunni lẹbun ọdun ti Naomi fẹ ṣẹ niluu Ibadan nigba naa.

Ile ẹjọ pada fi wọn silẹ lẹyin awọn akoko igbẹjọ to yẹ.