You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Àwọn ajínigbé dúnkokò láti gbẹ̀mí Kàbíyèsí tàbí ọmọ rẹ̀ tí wọn kò bá san N100m owó ìtúsílẹ̀'
Oluṣọ aguntan ijọ ECWA ti ilu Idọfihan to jẹ ijọ ti kabiesi ti wọn ji gbe Ọba Simeon Ọlanipẹkun Aniwo ti ilu Aafin-Ilere ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara n lọ, Ẹniọwọ Samuel Ajayi ti pariwo si ta nípa ìlera kabiyesi naa.
Ẹniọwọ Ajayi, ẹni to ba BBC News Yorùbá sọrọ nipa iṣẹlẹ naa laarọ lọjọru salaye pe, irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kẹfa, oṣu Kiini ọdun 2026 ni Kabiesi pe oun lori ẹrọ ibanisọrọ pẹlu ọmọ rẹ ọkunrin ti wọn ji gbe pe ki oun jọ ọ bawọn wa owo ọgọ́rùn-ún kan mílíọ̀nù naira tawọn ajinigbe naa n beere fun.
O sọ pe ohùn kabiyesi naa ko ṣe dáadáa lasiko ti wọn sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ.
O ṣalaye pe kabiesi ni kawọn lọ wa ọgọ́rùn-ún kan mílíọ̀nù naira ti awọn ajinigbe naa n beere fun ni gbogbo ọna tawọn ba ti leri owo ni kawọn wa owo lọ nitori ẹmi awọn ti fẹ ẹ bọ.
Ajayi tẹsiwaju pe oun tun ba ọmọ kabiyesi naa, Ọlaolu sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ to si n sunkun bo ṣe jẹ pe bawọn ṣe n sọrọ ni awọn ajinigbe naa n na an.
O fi kun pe kabiesi ni awọn ajinigbe naa ti n dunkoko mọ awọn pe bi awọn ko ba ri owo lọjọru, awọn maa pa ọkan ninu kabiyesi tabi ọmọ rẹ.
Ojiṣẹ Ọlọrun yii ni kii ṣe oun nikan lawọn ajinigbe yii pe, wọn tun pe ẹlomii to n jẹ iya Bose to jẹ ẹgbọn si kabiyesi.
O wa rọ ijọba ipinlẹ Kwara ati ijọba ibilẹ Ifẹlodun lati seranwọ lori iṣẹlẹ naa pẹlu afikun pe, gbogbo igbiyanju awọn lati ri owo ti wọn beere fun lo jasi pabo.
O fikun ọrọ rẹ pe, oun ti pe alaga ijọba ibilẹ Ifẹlodun, Alaga ni ijọba o le san owo idoola sugbọn awọn ti ko awọn ọmọ Ogun lọ si inu igbo lagbegbe naa.
A o ranti pe, Ọba Simeon Ọlanipẹkun Aniwọ ti ilu Ààfin iléèrè lẹkun ileere lagbegbe Babanla ijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara lawọn ajinigbe jigbe lalẹ ọjọru ọjọ Kọkanlelọgbọn oṣu Kejila ọdun to kọja oun ati ọmọ rẹ ọkunrin Ọlaolu to jẹ agunbanirọ to n sinru lu lọwọ ti wọn si yinbọn mọ Olori to n gba itọju lọwọ ni ile iwosan.
Lati igba naa lawọn eeyan ilu naa o ti loju oorun mọ pẹlu mọlebi kabiesi ati ijọ ti kabiesi n lọ.
Awọn ajinigbe naa n beere fun owo ọgọ́rùn-ún kan mílíọ̀nù naira ki wọn to le yọnda Ọba Simeon Ọlanipẹkun ati ọmọ rẹ Olaolu.
Àwọn ajínigbé tún ti jí Kábíyèsí míì gbé lọ ní ìpínlẹ̀ Kwara
Ṣaaju ni a ti mu iroyin wa pe lalẹ aisun ọdun ọjọ kọkanlelọgbọ̀n osu kejila ọdun 2025 lawọn ajinigbe tun sọsẹ nipinlẹ Kwara, nibi ti wọn tun ti kabiyesi mii lọ niluu Aafin-Ilere nijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ naa.
Gẹ́gẹ́ bí Ọgbẹni Jimoh ọkan lara awọn araalu ilu naa ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ ṣe sọ, nnkan bi ago mẹjọ ni iṣẹlẹ naa waye.
O salaye pe wọn ji Kabiyesi ilu naa, Ọba Simone Ibiyinka Ọlanipẹkun ati ọmọkunrin rẹ to n sinrulu lọwọ Ọlaoti gbe, wọn sì yinbọn fun Olori ọba.
Ọgbẹni Jide, ẹlomiran ti oun naa tun ba BBC Yorùbá sọrọ sọ pe, ṣe ni awọn ajinigbe naa da ibọn bolẹ nigba ti wọn wọ ilu.
O fikun pe ọpọlọpọ awọn ara ilu naa ni wọn sun inu igbo mọju pẹlu ibẹru-bojo to gbalẹ.
O salaye siwaju si pe igba akọkọ kọ niyi tawọn ajinigbe yoo sọsẹ niluu naa.
Ọgbẹni Jide wa rọ ijọba lati doola kabiyesi Ọba Ọlanipẹkun ati Arẹmọ rẹ.
O fidi rẹ mulẹ pe wọn ti gbe Olori tawọn ajinigbe naa yinbọn fun lọ si ile iwosan fun itọju.
Lasiko ti oun naa n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ojiṣẹ Ọlọrun Samuel Ajayi to jẹ alufaa ijọ ti kabiesi naa n lọ ni ilu Idofian sọ pe Kabiesi lọ sọdun ni ilu rẹ ni tori Idọfina ni kabiesi n gbe.
Ojiṣẹ ọlọrun naa ni oun ni oniwaasu ijọ Frist ECWA ti Kabiesi n lọ.
Ajínigbé kọlu ìlú Adanla ní Kwara, jí èèyàn mẹ́sàn-án gbé lọ, yìnbọn pa ẹnìkan
Laipẹ yii ni lawọn ajinigbe sọsẹ ni ipinlẹ Kwara lẹyìn tí wọn sekọlu si ilu Adanla to wa ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ naa.
Iṣẹlẹ naa to waye lalẹ ọjọ keji ọdun keresimesi ni nnkan bi ago meje alẹ ti ko ipaya ba awọn eeyan ilu naa bayii.
Ọgbẹni Yusuf to jẹ oṣiṣẹ atunase ni ilu Adanla fidi rẹ múlẹ pe eeyan mẹsan-an ni wọn ji gbe ni ilu naa.
O fikun ọrọ rẹ pe ọmọ ile kan naa lawọn ti wọn ji gbe lọ naa.
Yusuf salaye pe awọn to wa sọdun keresimesi ni ilu Adanla lawọn eeyan ọhun.
Araalu Adanla náà tún sọ pe mọlẹbi oun wa lara awọn ti wọn ji gbe naa.
Ohun tí a gbọ́ ni pe awọn ọlọpaa ati awọn eleto aabo miran ti de si ilu naa bayii.
Ọgbẹni Yusuf salaye pe se ni ọrọ di bo o lọ ya n mi lasiko ti awon ajinigbe ọhun ya wọ inu ilu naa.
Ninu ọrọ tiẹ, Ọgbẹni Ajayi ti oun naa jẹ ọmọbibi ilu Adanla, sọ pe inu igbo ni oun salọ lalẹ ọjọ naa lasiko ti awọn agbebọn náà sadeede da ibọn bo ilẹ.
Ajayi salaye pe ẹni ti ibọn ba, wọn ti gbe e lọ ile iwosan fún itọju, amọ, o tun fidi rẹ múlẹ pe awon ajinigbe ọhun yinbọn pa ẹnikan.