You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Mò ń wá ọkọ, mo ti ṣetán láti fàyè gba ìfẹ́ nínu ọkàn mi – Princess Damilola
Princess lo sọ ọrọ naa ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ nibi to ti rawọ ẹbẹ si awọn gbajumọ pasitọ ni Naijiria pe ki wọn ran oun lọwọ lati mu afojusun ọhun ṣẹ.
Àlàyé lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Edo tó sọ akẹ́kọ̀ọ́ àti èèyàn 52 dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n
Ẹgbẹ awọ akẹkọọ, NANS sọ pe iwa ti ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo n wu si awọn akẹkọọ naa ko tọ o si jẹ titẹ etọ araalu loju mọlẹ.
Kà nípa Yoweri Museveni, ààrẹ Uganda tọ fẹ́ lọ fún sáà kéje
Yoweri Museveni fipa gba ipo to ga ju lọ naa lọ ni ọdun 1986, nisinyi to si ti pe ẹni ọdun mọkanlelọgọrin (81) o fẹ maa tẹsiwaju nipo agbara.
Tinubu, Obasanjo, Sanwo-Olu àtàwọn mí-ìn ń ṣèdárò Ọba Akran tó wàjà ní Badagry
Ana ode yii ti i ṣe ọjọ Aje ni iroyin ipapoda àgbà ọba fun gbogbo Badagry naa gbode. Ẹni ọdun mọkandinlaadọrun-un (89) ni Kabiyesi naa ki ọlọjọ too de.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 1,01
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọkùnrin tó 'gún ìyàwó rẹ̀ pa' tóun náà sì pa ara rẹ̀ l'Ogun
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fesi lori iṣẹlẹ naa tẹlẹ, iyalẹnu lo ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to n gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun.
Fídíò, Orúkọ ọkọ mi ló wà níbi gbogbo dúkìá tí a ní, àmọ́ mi ò ri rò-Kemi Fajana,ìyàwó tó bá ọkọ rẹ̀ da òwò pọ̀, Duration 3,49
Abilekọ Fajana fi kun un pe ọkọ oun jẹ akinkanju nigba ti oun fẹ ẹ, yara kan ṣoṣo lo n gbe, o si n ta simẹnti ti ko ju aadọta apo lọ.
''Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti wà lójúfò fáwọn agbébọn tó ṣèlérí láti ṣèkọlù sí Ikoyi-Ile l'Ogbomoso''
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, CSP Benjamin HUndeyin, lo fọrọ yii lede loju opo X rẹ.
Kókó nǹkan méje tí Chimamanda ń béèrè lọ́wọ́ ilé ìwòsan Euracare lórí ikú ọmọ rẹ̀
Ọmọdekunrin naa, Nkanu Nnamdi ku sile iwosan niluu Eko lẹyin aisan ranpẹ, eyii to da omi tutu sọkan awọn mọlẹbi rẹ.
Fídíò, Ṣíṣe bíi Quadri kò ki í ṣe ohun tí mo ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀, ìdí rèé- Taooma, Duration 3,51
O ni oun ko ni lọkan pe oun yoo ṣe ẹda itan Quadri ṣugbọn oun to fẹ wa, to si jẹ ohun ti awọn eeyan
Ìpínlẹ́ Katsina ṣàlàyé ìdí tó fi fẹ́ẹ́ tú agbésùnmọ̀mí 70 sílẹ̀
Ijọba ṣapejuwe igbesẹ gẹgẹ eyi ti yoo fayegba jiroro alaafia laarin ijọba ati awọn agbesunami.
Gbas-gbos ní ìpínlẹ̀ Rivers àti àtunbọ̀tán òṣèlú bàbá ìsàlẹ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà
Wo awọn ipinlẹ ti ija ti waye laarin gomina ati baba isalẹ rẹ, eyii to da rogbodiyan silẹ laarin ilu.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
₦9.3bn ni Tinubu yà sọ́tọ̀ fún Iléeṣẹ́ Ààrẹ, oúnjẹ ati ìrìnàjò ní 2026
Tinubu ni ọjọ kọkandinlogun ọdun 2025 gbe eto isuna lọ siwaju ile igbimọ aṣofin orilẹede Naijiria, ti apapọ owo naa si jẹ N58.18tn.
Kà nípa Li, ọkùnrin aláàbò ara tó tọrọ báárà àmọ́ tó padà di dókítà
Ọmọ oṣu mẹfa pere n i Li wa ko to lugbadi arun polio.
Afonja: Ọ̀rẹ́ àjèjì ló kó bá Afọnja, tí Ilọrin fi bọ́ lọ́wọ́ Yorùbá
Afọnja gba ilu Ilọrin labẹ akoso ilu Ọyọ, to si kede pe ilu naa ti di ilu olominira.
Iná jó èèyàn kan pa àti ilé 300 ní Australia
Iroyin ni fun ọpọ ọjọ ni ina ọhun fi jo kaakiri ilẹ naa, paapaa lagbe Victoria ati New South Wales.
Tí Trump bá ṣèkọlù sí Iran, a ṣetán láti gbẹ̀san lára Amẹrika - Ìjọba Iran
Adari ile aṣofin Iran sọ fawọn akẹgbẹ rẹ nile wi pe Iran ṣetan lati ṣe ikọlu si ibudo ologun Amẹrika to wa lẹkun Middle East ati si Israel, ti Amẹrika ba le ṣekọlu si Iran.
Wo bí Amala, moimoi, àtàwọn ọ̀rọ̀ míì ṣe wọ ìwé atúmọ̀ èdè Oxford àti ìtumọ̀ tí wọ́n fún wọn
Nínú àtẹ̀jáde ti oṣù Kejìlá, ọdún 2025 tí wọ́n fi léde lójú òpó ìtàkùn ayélujára wọn ṣàfihàn àwọn ọ̀rọ̀ tuntun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta sínú ìwé atúmọ̀ èdè náà tó fi mọ́ DM, amala, moimoi, brainfart àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìbànújẹ́ ni ikú Oluwafunlola Laisi jẹ́ sí àwa ẹbí ọkọ̀ rẹ̀ - Ẹ̀gbọ́n ọkọ̀ rẹ̀
Ọdun to kọja ni iroyin gbode lori iku arabinrin naa ati ọmọ rẹ eyi ti wọn ni ko sẹyìn bi ọrẹ rẹ kan ṣe tan-an lọ si ipinlẹ Osun lati ipinlẹ Ogun to ti n ṣiṣẹ, to si tan an lọ si ọdọ babalawo lati fi ṣe etutu ọla rẹ.
Kí nídìí táwọn olùwọ́de fi gba gbogbo ìgboro orílẹ̀ èdè Iran?
Ọjọ́bọ̀ ló pé ọjọ́ kejìlá tí ìwọ́de ti ń wáyé ní orílẹ̀ èdè náà látàrí bí owó ìlú náà ṣe ti já wálẹ̀ lọ́jà àgbáyé, tí ìwọ́de náà sì ti tàn káàkiri àwọn ìlú tó lé ní ọgọ́rùn-ún káàkiri ẹkùn mọ́kànlélọ́gbọ̀n tó wà ní orílẹ̀ èdè náà gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ṣe sọ.
Ìjọba ilẹ̀ òkèrè dá $9.5m tí àwọn kan jí kó lọ sílẹ̀ wọn padà fún Naijiria
Owo ọhun ni iroyin sọ pe awọn kọlọrọsi ẹda ji ko lọ silẹ naa lọpọ ọdun sẹyin.
Ẹnikẹ́ni tí Allwell bá sẹ̀, ẹ dákun, ẹ forí jì í - Rotimi Salami dọ̀bálẹ̀ bẹ àwọn èèyàn
Ana ode yii ti i ṣe Ọjọbọ, ọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni eto isinku Oloogbe Allwell bẹrẹ ninu ọgba Tẹlifiṣan ipinlẹ Eko, nibẹ ni Rotimi Salami si ti ṣe ohun to jọ gbogbo eeyan loju nitori Allwell.
NCC fẹ máa da owó padà fáwọn oníbàárà tí kò bá rí káàdí ìpé lẹ́yín ìṣẹ́jú àáyá ọgbọ̀n tí wọ́n yọ owó wọn
Itumọ eyi ni pe nigba ti wọn ba ti yọ owo ẹni to fẹẹ ra kaadi, ṣugbọn ti ko ri kaadi, ko ni i ju iṣẹju aaya ọgbọ̀n (30 seconds) lọ ti wọn yoo fi da owo naa pada si akanti rẹ.
Àjọ NERC kéde pé Togo, Niger àti Benin ń jẹ Naijiria ní 25bn owó iná mọ̀nàmọ́ná
NERC sọ pe awọn orilẹeede naa jẹ Naijiria lowo yii nipasẹ ipese ina fun wọn, eyi to ni adehun ati ajọsọ ninu.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìjọba mi yóò rí i dájú pé irú ìkọlù yíì kò ṣẹlẹ̀ mọ́- Gómìnà Seyi Makinde
Gomina Makinde ṣalaye pe iwadii awọn ẹṣọ alaabo fi han, pe awọn agbesunmọmi to ti ẹnu ibode ibomiran wa lo ṣe iṣẹ ibi naa.
Kí làwọn àtúntò tí ìjọba Nàìjíríà mú bá ètò ìdánwò WAEC àti NECO láti dènà àwọn aṣemáṣe?
Ètò ìdánwò WAEC àti NECO ló wà fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama tí wọ́n wà ní ipele àṣekágbá, tí wọ́n sì ń múra láti lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga.
Àlàyé lórí òfin tuntun tí UK gbé kalẹ̀ lórí àwọn tó ń fi ọkọ̀ ojú omi káwọn àjèjì wọlé
Awọn ẹṣọ aṣọbode yoo maa gba foonu awọn to n lo ọkọ oju omi lati japa lọ si UK ni toootọ, amọ, eyi ko tumọ si pe wọn maa fọwọ ofin mawọn eeyan naa.
Ta ni Ọ̀mọ̀wé Olugbemisola Odusote, Adarí Obìnrin àkọ́kọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga àwọn Amòfin tí Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò?
Atẹjade kan ti Oludamọran fun Aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, fi sita lọjọ Iṣẹgun ana, fidi iyansipo naa mulẹ.
Àwọn orílẹ̀ èdè wo ni Trump tún ń fojúsùn lẹ́yìn Venezuela?
Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè ni Trump ti ń fojúsùn láti ṣe ìkọlù sí.
Kí nídìí tí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers fi bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ Gómìnà Fubara nípò?
Nígbà tó ń fìdí ìgbésẹ̀ náà múlẹ̀ pẹ̀lú ìwé òfin Nàìjíríà, Olórí ọmọ ilé tó pọ̀ jùlọ, Major Jack ka àwọn ìwà aṣemáṣe mẹ́sàn-án tó ní ó lòdì sí òfin.
Kí ni òfin tí Amẹ́ríkà ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀ fáwọn tó bá fẹ́ ṣe ìrìnàjò afẹ́ tàbí lọ ra ọjà níbẹ̀ láti Nàìjíríà?
Òfin yìí ló de àwọn tó bá fẹ́ gba físà B1 tàbí B2, tí wọ́n yóò sì máa san owó tí iye rẹ̀ fẹ́ẹ̀ tó mílíọ̀nù méje sí mílíọ̀nù méjìlélógún náírà ($5,000 - $15,000) kí wọ́n tó le rí físà gbà.
Ìdìtẹ̀gbàjọba ní Burkina Faso forí sánpọ́n, Traoré móríbọ́ lọ́wọ́ ikú
Mínísítà fún ètò ààbò Burkina Faso, Mahamadou Sana nínú ìkéde tó ṣe sọ pé ológun kan Paul Henri Damiba ló gbìyànjú ìdìtẹ̀gbàjọba tí kò kẹ́sẹ járí náà.
'Àwọn ajínigbé dúnkokò láti gbẹ̀mí Kàbíyèsí tàbí ọmọ rẹ̀ tí wọn kò bá san N100m owó ìtúsílẹ̀'
Ẹniọwọ Ajayi ṣalaye pe kabiesi ni kawọn lọ wa ọgọ́rùn-ún kan mílíọ̀nù naira ti awọn ajinigbe naa n beere fun ni gbogbo ọna tawọn ba ti leri owo ni kawọn wa owo lọ nitori ẹmi awọn ti fẹ ẹ bọ.