Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn, èsì, iye góòlù àti ipò tí ikọ̀ agbábọ́ọ́lù kọ̀ọ̀kan wà nínú ìdíje Afcon 2025

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ní báyìí, idije ife ẹyẹ láàrin àwọn orílẹ̀èdè nílẹ̀ Áfíríkà, tí a mọ̀ sí Afcon 2025 tí bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.

Afcon 2025 náà sì ni yóò máa wáyé laarin ọjọ́ kokanlelogun oṣù Kejìlá ọdún 2025 si ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kinni odun 2025.

Orílẹ̀èdè Morocco sì ni idije náà yóò ti máa wáyé.

Orílẹ̀ èdè Morocco náà sì ni yóò side ifesewonse níbi idije Afcon 2025 náà nítorí òun ló ń gbalejo idije ọhun.

Gbajúmọ̀ agbábọ́ọ́lù láti Morocco, Achraf Hakimi yóò sì wà lára àwọn agbábọ́ọ́lù tí yóò kopa ninu ifesewonse àkọ́kọ́.

Orílẹ̀ èdè Senegal, Ivory Coast, Egypt áti Nàìjíríà tí Victor Osimhen ń léwájú rẹ náà wà lára àwọn alátakò fún ikọ̀ agbábọ́ọ́lù orílẹ̀èdè Morocco nínú ìdíje Afcon 2025.