You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ètò ìdìbò láàárín Museveni àti Boby wine láti yan ààrẹ Uganda
Oni Ọjọbọ, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni idibo n waye ni Uganda, titi kan ti ipo aarẹ.
Koda, idibo ọhun ti bẹrẹ, bo tilẹ jẹ pe ọpọ nnkan eelo ti wọn nilo ni ko si nikalẹ lasiko ti a n kọ iroyin yii, eyi to n fa ọwọ aago idibo naa sẹyin.
Wọn ni ẹrọ ti wọn nilo lati fi ṣe idanimọ (Biometric identification kits)lo n fa, awọn kan si sọ pe oju opo ayelujara ti ko ṣiṣẹ ni.
Oludije mẹjọ lo n dupo aarẹ, bo tilẹ jẹ pe meji gboogi lo foju han ju, awọn naa ni Aarẹ Yoweri Museveni to ti wa nipo aarẹ Uganda lati 1986, to si fẹẹ lọ fun saa keje, ati Boby Wine, olorin to pada waa di oloṣelu.
Ẹni ọdun mọkanlelọgọrin (81) ni Aarẹ Museveni, nigba ti Boby Wine jẹ ẹni ọdun mẹtalelogoji (43).
Bi Museveni ṣe n sọ pe oun ko dagba lati ma dije, bẹẹ ni Boby Wine naa n leri pe oun yoo yi ijọba atijọ pada, oun yoo ṣe nnkan tuntun bii ọdọ, bi awọn eeyan Uganda ba fi ibo gbe oun wọle sipo aarẹ.
Ko si aaye pupọ fun awọn alatako ijọba ni Uganda, lara ohun ti wọn n koju ni atimọle, ati ki ọlọpaa maa da ipejọ wọn ru.
Bakan naa ni airiṣẹ ṣe pọ laaarin awọn ọdọ lorilẹede naa, bẹẹ si ni ọdọ lo pọ ju nibẹ, awọn ti ọjọ ori wọn ko ti i pe ọgbọn (30).
Lonii ọjọ idibo, aago meje aarọ ni wọn kede pe idibo yoo bẹrẹ, yoo si pari ni aago mẹrin.
Ìbò wo gan-an ni wọn n di ni Uganda?
Eeyan to to 21.6 million lo fi orukọ silẹ lati dibo lonii ni Uganda, gẹgẹ bi akọsilẹ wọn ṣe wi.
Ipele mẹta ni idibo naa:
*Ibo aarẹ - Oludije mẹjọ lo wa fun ipo yii.
*Ibo ile igbimọ (1) - ẹkun idibo 353 lo wa lati ṣoju ninu idibo ile igbimọ aṣofin akọkọ.
*Ibo ile igbimọ (2) – obinrin 146 lo wa fun ipo aṣoju, ẹnikan fun ẹkun kan ni wọn yoo dibo yan.
Ta lo ṣee ṣe ko di aarẹ?
Yoweri Museveni(NRM)
Gẹgẹ bi a ṣe wi, Aarẹ Museveni ati Bobi Wine ni oludije gboogi ti ipo aarẹ naa foju han pe yoo ja mọ lọwọ ninu awọn ọkunrin mẹjọ to n du ipo naa.
Eyi ni igba keji ti Museveni ati Boby Wine yoo jọ dije, Museveni lo pada di aarẹ ni 2021, eyi ti ọpọ araalu sọ pe magomago pọ ninu ibo naa.
Ibo ida 58% ni wọn ni Aarẹ Museveni ni nigba naa, nigba ti Bobi Wine ni 35%.
Ẹgbẹ National Resistance Movement (NRM) ni Aarẹ Yoweri Museveni n ṣe. Bo si tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo fẹran rẹ nigba to kọkọ fipa gbajọba logoji ọdun sẹyin, kaluku lo ti n sọ bayii pe agidi ati ipa ni aarẹ agbalagba naa fi n ṣejọba Uganda.
Awọn awoye sọ pe Museveni ko fẹ kuro nipo naa mọ, wọn lo ti fẹẹ sọ ọ di ogun ibi rẹ, pẹlu bo ṣe jẹ pe oun yii naa ni aarẹ ti ọpọ ọmọ Uganda gbọnju ba .
Lọwọlọwọ yii, Aarẹ Museveni ni aarẹ kẹta to pẹ ju lori ipo ni Africa.
O ti ṣe atunṣe ofin orilẹeed naa, o yọ gbedeke ọjọ ori kuro fun oludupo aarẹ, eyi to fun un ni anfaani lati maa dije funpo naa lọ.
Awijare rẹ ni pe oun nikan loun le fi ọwọ ilọsiwaju ati alaafia ilu sọya.
Bobi Wine - National Unity Platform (NUP)
Oludije keji to n tan kan-n-gbọn ju pẹlu Museveni ni Bobi Wine, ẹni ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Robert Kyagulanyi.
Lasiko kan, awọn eeyan Uganda fun un ni inagije ''Ghetto president", iyẹn Aarẹ agbegbe awọn eeyan ti ko ni nnkan kan.
Wọn ri I bii ọdọ to ni afojusun awọn nnkan to le mu ayipada rere ba Uganda.
Nnkan bii ọdun marun-un sẹyin ni Bobi Wine di gbajumọ to mu oṣelu lọkunkundun, ipo keji lo ṣe nigba to dije nigba naa .
Nigba naa si ni ẹgbẹ rẹ ti i ṣe NUP di ẹgbẹ alatako to pọju nile igbimọ.
Bi awọn eeyan Uganda ba tẹle ifẹ ọkan wọn lori ayipada, awọn awoye sọ pe o ṣee ṣe ko fi sọdọ Boby Wine.
Awọn oludije yooku ni: Frank Bulira, Robert Kasibante, Joseph Mabirizi, Nandala Mafabi, Mugisha Muntu and Mubarak Munyagwa.
Njẹ ibo yii ko ni I kun fun èrú?
Lọpọ igba ni ọpọ eeyan ti maa n bu ẹnu atẹ lu ilana idibo ni Uganda.
Ṣugbọn lọtẹ yii, awọn alabojuto sọ pe ibo naa yoo lọ ni irọwọrọsẹ, amọ awọn akọṣẹmṣẹ lati ajọ UN kilọ pe o ṣee ṣe ko jẹ bakan naa ni ọmọ yoo tun ṣe ori ninu ibo oni.
Lasiko ipolongo ibo, awọn alatako koju oriṣiriṣi idaamu, gẹgẹ bi awọn awoye ṣe tọka.
Awọn agbofinro da ipolongo Bobi Wine ru, wọn ko si fọwọ kan awọn ti Museveni.
Bakan naa ni ajọ alaanu, Amnesty International, ṣapejuwe bi wọn ṣe lo ẹrọ tajutaju, ata ati bi wọn ṣe fẹrẹ lu awọn kan pa lasiko ipolongo ibo bii iwa ọdaju ati ika.
Amọ ijọba Museveni sọ pe o yẹ ko ri bẹẹ lati ri I pe ibo alaafia ni awọn eeyan di.
Wọn ni ki awọn le dena rogbodiyan kankan to ba fẹ waye lọjọ ibo ni.
Bobi Wine ni tiẹ rọ awọn oludibo lati duro ti ibo wọn bi wọn ba di I tan, lati da aabo bo o, ko ma baa si magomago kankan.
Ṣugbọn awọn ajọ eleto idibo sọ pe ki kaluku gba ile rẹ lọ jẹẹ to ba ti dibo tan ni.
Wọn ni akoyawọ ni awọn yoo fi ka ibo naa, awọn olootu idibo ati awọn akọroyin yoo si boju to o bawọn ba n ka a.
Awọn awoye kan ti ni awọn ko gbagbọ ninu ajọ eleto Uganda ṣaa.
Bẹẹ ni awọn NUP naa sọ pe awọn ni ẹrọ kan to le mojuto ibo naa, ti ko ni i si ogun magomago, wọn ni oju opo Bluetooth ni ẹka imọ ẹrọ naa n lo.
Nipa igba ti esi idibo yoo de, ọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni won kede pe esi idibo naa yoo jade fun araalu lati mọ.
Eyi ri bẹẹ nitori wakati mejidinlaadọta (ọjọ meji) lẹyin idibo ni ofin sọ pe awọn ajọ eleto idibo gbọdọ kede esi idibo ti wọn ba di ni Uganda.
Iṣoro Uganda
Ọrọ nipa ọrọ aje jẹ ọkan lara idaamu to n koju orilẹede Uganda, paapaa julọ, airiṣẹ ṣe.
Owo to n wọle fun araalu kere, bo tilẹ jẹ pe o ti n gbera sọ lẹyin ajakalẹ arun Corona to waye lọdun mẹfa sẹyin, ṣugbọn iṣẹ ko ti I pọ to fun awọn ọdọ lati ṣe.
Ai si nnkan amayedẹrun tun kun iṣoro ilu naa, bẹẹ ni eto ẹkọ ati ti ilera mẹhe.
Ajẹbanu ni iṣoro miran ti Uganda tun n koju, ipo ogoje (140) ni wọn wa ninu aadọsan (180) ninu awọn orilẹede ti ajẹbanu wọ lẹwu, gẹgẹ bi akọsilẹ 'Transparency International annual Corruption Perceptions Index.
Gbigba owo ẹ̀yìn ati pinpin ẹtọ araalu yooku fun awọn to wa nipo ijọba tun kun iṣoro ti akọsilẹ wa fun ni Uganda.
BBC News Yoruba yoo maa fi to yin leti bo ba ṣe n lọ ninu idibo Uganda.