You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kà nípa Yoweri Museveni, ààrẹ Uganda tọ fẹ́ lọ fún sáà kéje
- Author, Wedaeli Chibelushi
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8
Fun awọn ọmọ orilẹede Uganda ti ọjọ ori wọn ko to ogoji ọdun, wọn si pọ, wọn ju ida mẹta ilu naa lọ, wọn ko gbọnju mọ aarẹ miran ri, bi ko ṣe Aarẹ Yoweri Museveni to ti n dari ilu wọn fun ọdun gbọọrọ.
Yoweri Museveni fipa gba ipo to ga ju lọ naa lọ ni ọdun 1986, nisinyi to si ti pe ẹni ọdun mọkanlelọgọrin (81) o fẹ maa tẹsiwaju nipo agbara.
Ni ti ododo, saa iṣakoso rẹ mu alaafia ati idagbasoke wa, eyi ti ọpọ eeyan n dupẹ si. Ṣugbọn awọn awoye sọ pe agidi ni baba naa fi n ṣejọba, nipa lile awọn alatako danu, to si tun n dọgbọn alumọkọrọyi fun awọn ajọ aladaani to yẹ ko ṣe otitọ.
"A ko nigbagbọ ninu ki gbedeke wa fun ipo aarẹ". Yoweri lo sọ bẹẹ fun BBC nigba kan, iyẹn nigba to wọle ibo fun igba karun-un.
Ọdun kan lẹyin eyi, wọn yọ gbedeke kuro ninu iye ọdun ẹnikẹni to ba fẹ dupo aarẹ - eyi ti ọpọ gbagbọ pe yoo fun Museveni ni anfaani lati maa ṣe aarẹ lọ titi aye.
Ọdun 1944 ni wọn bi Museveni si idile awọn ọlọsin agbo kan, ni Ankole, ẹkun Iwọ-Oorun Uganda.
Lasiko ti Uganda n ja fun ominira kuro lọwọ UK loun bẹrẹ si i dagba, ifiyajẹni ati idaamu lo tẹle asiko naa, labẹ awọn alagbara bii Milton Obote ati Idi Amin.
Fun ọpọ ọdun, Museveni ko mọ ọjọọbi rẹ, o kọ ọ sinu akọsilẹ rẹ pe : "A koju ipaniyan lai nidii ati ajẹbanu... ko tiẹ si aaye fun wa lati ronu ọjọọbi."
Ni 1967, Museveni kuro ni Uganda lọ si University of Dar es Salaam, eyi to wa ni Tanzania ti i ṣe alamuleti wọn. Nibẹ lo ti kẹkọọ nipa ọrọ aje ati oṣelu, o si bẹrẹ ajọṣe pẹlu awọn akẹkọọ ibẹ.
Ọdun 1970 sisalẹ lo di gbajugbaja, lẹyin iditẹgbajọba kan lati ọwọ ẹrujẹjẹ Idi Amin.
Aṣaaju ogun ni Museveni nigba naa fun ẹgbẹ akọya kan, pẹlu iranlọwọ Tanzania, wọn ṣẹgun Idi Amin.
Tẹ o ba gbagbe, Idi Amin ki i fẹ gbọ ọrọ alatako seti, oun lo le awọn eeyan Asia to wa nitosi wọn lọ, ko si din ni eeyan 400, 000 to ku lasiko iṣakoso ọdun mẹjọ rẹ.
Bi Museveni ṣe di aarẹ
Lẹyin iṣubu Amin,aarẹ tẹlẹ,Milton Obote, gba ipo agbara pada nipasẹ idibo apapọ. Ṣugbọn Museveni kọ lati gba pe Obote lo wọle ibo, o ni wọn ṣe èrú ibo naa ni.
Nigba naa lo gbe ijijagbara kan kalẹ ni 1981, nigba to si di ọdun marun-un lẹyin igba naa, ẹgbẹ alatako rẹ, National Resistance Movement (NRM), fipa gba agbara naa, Museveni si di olori ilu.
Bẹẹ ni ọrọ aje Uganda bẹrẹ si i dagba, nigba ti ọdun mẹwaa yoo si fi kọja, orilẹede naa ti ri idagbasoke to le ni ida mẹfa.
Awọn eeyan to n wọ ile ẹkọ alakọọbẹrẹ n pọ si i, bẹẹ ni onka awọn to ni arun HIV bẹrẹ si i dinku, latari ikede to n tako arun ko gboogun, eyi ti Aarẹ funr rẹ gbe kari.
Bayii ni Museveni ṣe di aayo fun awọn eeyan ẹkun Iwọ-Oorun, sugbon nigba to di 1988, okiki rẹ to n kan ja walẹ, nigba ti Uganda ati Rwanda kọlu Democratic Republic of Congo to jẹ alamuleti wọn, ti wọn n ti awọn ọlọtẹ lẹyin lati da oju ijọba bolẹ.
Lasiko naa, awọn alatako ti n sọ pe Museveni ki i fẹ ohun to ba ti yatọ si ifẹ inu rẹ. O si tun foju han pe ko ṣetan lati gbe ijọba silẹ rara.
Ni 1986, o sọ ninu akọsilẹ rẹ kan pe "Iṣoro Africa lapapọ, paapaa Uganda, ki i ṣe awọn eeyan, bi ko ṣe awọn olori wọn ti ki i fẹ fipo agbara silẹ. "
Ṣugbọn nigba to ya, o jọ pe ero rẹ lori ọrọ yii ti yipada, wọn si tun ofin Uganda ṣe, wọn yọ apa iye saa ti aarẹ le ṣe .
Ni 2017, wọn tun ṣagbeyẹwo iye ọjọ ori aarẹ - eyi ti ẹgbẹ MP lodi si lasiko kan ti wọn si bẹrẹ si i ju ṣia nipade igbimọ.
Agbára àjùlọ
Ẹsun kan ti wọn tun fi n kan Museveni ni pe o ti sọ awọn ẹka to yẹ ko ni aṣẹ lọwọ ara wọn di ọlẹ.
Paapaa julọ, ẹka idajọ Uganda, wọn ni awọn adajọ to n gbe lẹyin ijọba ni wọn n gba sibi eto idajọ..
Awọn asiko ti awọn adajọ kan tako ijọba, ibi ti wọn ti ba ara wọn pẹlu awọn alagbara ko rọgbọ.
Fun apẹẹrẹ, loṣu Kejila ọdun 2005, awọn agbofinro to dihamọra ogun ya bo ile ẹjọ giga to wa ni olu ilu ti i ṣe Kampala, wọn tun awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ti wọn ti mu nigba kan mu, awọn ti ile ẹjọ ṣẹṣẹ tu silẹ pe wọn ko jẹbi iditẹ mọ ijọba.
Bakan naa ni oju awon akoroyin naa n ri, loju aye, Uganda ni ẹka iroyin to wuyi, ṣugbọn ọpọ ile iroyin ni wọn ti kọlu, wọn si ti awọn akọroyin kan mọ ahamọ.
O fẹrẹ jẹ pe ohun to foju han ju ninu ijọba ọlọdun pipẹ Museveni ni pe ko fẹ ri imi awọn ọta ijọba rẹ laatan.
Nigba to foju han pe Museveni ko ṣetan lati gbe ijọba silẹ, awọn kan lara awọn to n tẹle e tẹlẹ bẹrẹ si i pada lẹyin rẹ. Bi wọn ṣe n ṣe bẹẹ, awọn agbofinro ko foju ire wo wọn mọ.
Fun apẹẹrẹ, Kizza Besigye, ọmọ ẹgbẹ alatako Forum for Democratic Change, to figba kan jẹ dokita fun Museveni's doctor, lo kọkọ dije ta ko o ni 2001.
Lati igba naa ni wọn ti fi ofin mu un ti wọn si fẹsun kan an lọpọ igba. Ni 2024, bi ere bi ere ni wọn ko deede ri i mọ ni Nairobi, ki wọn too tun ri i lẹyin ọjọ kerin ni kooru ologun ilẹ Uganda.
Ẹwọn lo wa lori ẹsun iditẹmọ ijọba, eyi to ni oun ko jẹbi rẹ.
Ẹru o bodo, ẹgbẹ NRM ti i ṣe ti Museveni ni ko si giri
Gbajumọ olorin to di oloṣelu lorilẹede naa, Bobi Wine, ni ẹni to n foju wina atako Museveni lọwọ.
Ẹni ọdun mẹtalelogoji naa ti ọpọ ọdọ fẹran ni wọn ti mu, ju si ẹwọn ti wọn si fẹsun ọlọkan-o-jọkan kan an, debi iditẹmọ ijọba. Wọn pada sọ pe ko ri bẹẹ.
Ni 2021, awọn ọlọpaa yin tajutaju ati ibọn mọ Bobi Wine ati awọn ọmọ ẹyin rẹ, wọn ni wọn tapa si ofin Korona to gbode nigba naa pẹlu kiko ọpọ eeyan jọ.
"Lasiko ipolongo to n lọ lọwọ,awọn agbofinro lo banga ati ibọn lati le awọn eeyan to jokoo alaafia ka" wọn si ji awọn ọmọ ẹgbẹ alatako gbe lọ ninu ọkọ ti ko ni nọmba. Bẹẹ ni iroyin UN kan wi.
Museveni paapaa sọ pe ọta ibọn 120 lo wa lapo ṣọja kan ṣoṣo. O si tun ni ki ọlọpaa ma ṣe na ọmọ ẹgbẹ alatako, ki wọn lo tajutaju fun wọn ni.
Awijare awọn alatilẹyin rẹ ni pe alaafia wa Uganda latigba ti Museveni ti n ṣejọba.
Emmanuel Lumala Dombo, agbẹnusọ NRM, sọ pe o le ni eeyan 1.7m to ti ko wa si Uganda, lẹyim ti wọn sa kuro niluu wọn nitori ikọlu.
"Ogoji ọdun sẹyin, a wa lara awọn to n fi atipo ranṣẹ julọ laaarin awọn ilu to sunmọ wa, , nisinyi, Uganda ni ilu to n gba atipo julọ ni Africa."
Dombo lo sọ bẹẹ fun BBC.
Ijọba Museveni ti bẹrẹ si i pe awọn ilẹ okeere lati waa ba wọn dowo pọ, wọn n ni ajọsọ pẹlu China, United Kingdom ati United Arab Emirates. Museveni ni oun fẹ ki Uganda di orilẹede to rọwọ họri gidi nigba ti yoo ba fi di 2040.
Museveni n ri ara rẹ bii alakikanju to ni ọjọ ọla. O maa n pe awọn ọdọ ni Bazukulu to tumọ si ọmọ-ọmọ, awọn naa si maa n pe e ni M7 tabi Sevo.
Koda, o maa n sọ pe ilera oun pe gan-an ni. "Ṣe ẹ gbọ ọ ri pe mo wa nile iwosan, ogoji ọdun ree ti mo ti wa pẹlu yin.Afi nigba ti mo ni arun Korona fun ọjọ mọkanlelogun."
Ṣugbọn awọn awoye sọ pe baba naa ti sọ ipo aarẹ di ogun idile rẹ.
Wọn ni iyawo rẹ, Janet, ni minisita eto ẹkọ, ọmọ rẹ ọkunrin, Gen Muhoozi Kainerugaba, ni olori ologun. Ọmọ-ọmọ ọkunrin paapaa darapọ mọ ileeṣẹ ologun loṣu Keje to kọja, wọn ni ọgbọn ati sọ ọ di ogun ibi ni.
Awọn ẹgbẹ NRM ko ti i sọrọ pupọ nipa bi wọn yoo ṣe ṣẹgun Museveni, ṣugbọn awọn eeyan n sọ pe Ọgagun Kainerugaba, ẹni ọdun 51 yoo ba a dije.
Ṣugbọn lọwọ yii, ẹru ko ba Museveni, leyin iriri to fẹre to ologoji ọdun nipo agbara, ero rẹ ni pe oun yoo tun lọ fun saa keje.
"Ko si wahala ni Uganda. Ẹ jade, ẹ dibo." Bẹẹ lo wi fun awọn araalu lọjọ aisun ọdun tuntun nigba to n ba wọn sọrọ. O ni ẹru kan ko si fun ẹgbẹ NRM ti i ṣe ẹgbẹ oun.
Afikun iroyin lati ọwọọ Sammy Awami