You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gbas-gbos ní ìpínlẹ̀ Rivers àti àtunbọ̀tán òṣèlú bàbá ìsàlẹ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà
Gbas-gbos laarin awọn oloṣelu atawọn baba isalẹ wọn ko jẹ tuntun mọ ni Naijiria, eyii ko ṣẹyin bi awọn gomina kan ṣe maa n fa ọwọ awọn ti wọn ba n fẹ ko gori alefa lẹyin wọn soke, amọ ti ede aiyede maa n paa waye laarin awọn mejeji.
Lootọ lawọn araalu maa n reti irufẹ ija bẹẹ laarin awọn oloṣelu atawọn ọga wọn amọ ọpọ ni ko lero pe ija ti gomina ipinlẹ Rivers, Siminalayi Fubara ati ọga rẹ, Nyesom Wike lo le le to bo ṣe ri lonii.
Ko pẹ ti Fubara gori alefa, koda, ko tii lo oṣu marun un lori oye ti ija bẹrẹ laarin oun ati Wike amọ Aarẹ Bola Tinubu pari aawọ naa.
Ija ọhun gbona girigi lẹyin ti iroyin ni awọn kan lọ dana sun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ọhun lalẹ ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023.
Bii baba ati ọmọ ni Nyesom Wike ati Siminalayi Fubara ri tẹlẹ, ko too di pe ọrọ oṣelu da wahala silẹ laaarin wọn.
Lara awọn ohun to fa rogbodiyan naa ni igbẹsẹ awọn aṣofin lati yọ gomina Fubara nipo, eyi to waye loṣu Kẹwaa ọdun 2023.
Awọn kan wa lẹyin Fubara, ṣugbọn ọpọ lo tẹlẹ Wike to wa lẹyin iyọnipo naa.
Iwọyii ni akọjọpọ ija to ti waye sẹyin laarin awọn oloṣelu ati baba isalẹ wọn
Ladoja ati Adedibu – Ipinlẹ Oyo
Rashidi ladoja ni gomina ipinlẹ Oyo lati ọdun 2003 si ọdun 2007, gbogbo ilu lo si mọ oloye Lamidi Adedibu gẹgẹ bii baba isalẹ rẹ.
Amọ wahala bẹ silẹ laarin awọn mejeji lẹyin ti ariyanjiyan kan waye lori ọrọ owo.
Gẹgẹ bii ohun ti Adedibu funra rẹ sọ ninu irọfọwerọ kan, o ni kete ti Ladoja di gomina tan ni iwa rẹ yipada si oun.
Ṣaaju ni Adedibu ti kọ bere fun N15m gẹgẹ bii owo ajẹmọnu oun ninu N65m ti ijọba apapọ n fi ṣọwọ si Ladoja loṣoṣu gẹhgẹ bii owo eto abo ṣugbọn Ladoja kọ jalẹ.
Adedibu lo ipo rẹ lati jẹ ki awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lọdun naa lọhun yọ Ladoja nipo bii jiga, ti ọrọ naa si da igboro ru.
Adekunle Ajasin ati Akin Omoboriowo – Ipinlẹ Ondo
Ni nnkan bii ogoji ọdun sẹyin ni oloye Adekunle Ajasin ati igbakeji rẹ Akin Omoboriowo dije du ipo gomina lọtọtọ ninu ẹgbẹ oṣelu UPN and NPN.
Ajasin ni gomina tẹlẹ, ti Omoboriowo si jẹ igbakeji rẹ, amọ awọn alatilẹyin Ajasin ri Omoboriowo bii ọdalẹ lẹyin ti oun naa gbe apoti ibo lati dije tako ọga rẹ ana.
Igbesẹ Omoboriowo naa lo waye latari ija kan to ṣẹlẹ laarin awọn mejeji lasiko ti wọn n ṣejọba ṣaaju.
Ẹwẹ, kii ṣe pe wọn yọ Omoboriowo nipo, bẹẹni ko kọwe fi ipo silẹ, niṣe lo kuro ninu ẹgbẹ oṣelu to gbe de ipo igabkeji gomina, UPN, to si lọ si NPN lati lọ dije tako ọga rẹ.
Amọ ṣa, ija wọn naa fa rogbodiyan ti ko ṣe fẹnusọ, ọpọ ẹmi sun, bẹẹ ni wọn dana sun ọpọ ile ati dukia.
Bola Tinubu ati Akinwumi Ambode - Ipinlẹ Eko
Ni ọdun 2014, Akinwunmi Ambode gbe apoti ibo gomina ipinlẹ Eko ni ọdun 2015, ti Aarẹ orilẹede Naijiria bayii, Bola Tinubu si fun ni iwuri.
Fun bi ọdun mẹta lẹyin eto idibo, gbogbo nnkan lọ pẹlu alaafia laaarin Tinubu ati Ambode. O ku ọsẹ diẹ si eto idibo abẹle ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, ni itan yii pada fun Ambode.
Gbogbo agbara rẹ lati ja pada lo ja si pabo.
Ambode da lori ọrọ naa, to si padanu eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko sọwọ Babajide Sanwo-Olu.
Rabiu Kwankwaso ati Abdullahi Ganduje – Ipinlẹ Kano
Rabiu Kwankwaso ni gomina ipinlẹ Kano ṣaaju Abdullahi Ganduje amọ ija nla waye laarin wọn bo tilẹ jẹ pe wọn n ba ra wọn ṣe tẹlẹ gẹgẹ bii ọrẹ ati oloṣelu.
Ija naa tubọ buru si lẹyin ti Abba Yusuf di gomina lẹyin Ganduje, to bẹrẹ si bẹrẹ si n pa awọn nnkan ti Ganduje ti ṣe ṣaaju rẹ.
Lẹyinorẹyin, ija awọn oloṣelu mejeji naa fa iwọde nla niluu Kano.
Nyesom Wike ati Rotimi Amaechi – Rivers
Agbegbe Ikwere ni awọn oloṣẹlu memeji ti wa, wọn si ti jọ ṣiṣẹ pọ ki ija to waye laarin wọn.
Nigba ti Amaechi wa nipo gomina ipinlẹ Rivers, Wike ba ṣiṣẹ gẹgẹ bii olori awọn oṣiṣẹ rẹ ki wọn to fa Amechi kalẹ fun ipo minisita ninu ijọba Goodluck Jonathan.
Amọ ija bẹrẹ laarin awọn mejeji lẹyin ti Amaechi lọ sinu ẹgbẹ oṣelu APC lati ṣatilẹfin fun Muhammadu Buhari fun ipo Aarẹ lọdun 2015 ṣugbọn ti Wike, to n du ipo gomina lọdun naa lọhun ṣatilẹyin fun Goodluck Jonathan fun ipo Aarẹ kan naa.
Ninu idibo ọdun naa Wike ni jawe ti jawe olubori gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Rivers lẹyin to fidi aayo Amaechi, iyẹn Dakuku Pertersisde janlẹ.
Peter Obi ati Willie Obiano - Ipinlẹ Anambra
Peter Obi ati ẹni to gba ipo gomina lọwọ rẹ, WIllie Obiano ni ajọsepọ nla ṣaaju eto idibo ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ lẹyin eto idibo.
Obi ati Obiano jẹ akẹgbẹ ni ile ẹkọ Christ the King College, CKC, Onitsha.
Ajọsepọ yii laaarin awọn mejeeji pada di ọta meji lẹyin ti Obi kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APGA lọ sinu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Lasiko eto idibo ọdun 2017 , Obi leri pe oun yoo fidi ọmọ Obiano janlẹ.
"Mo ma ja fun eto idibo yii, am si gbogbo ara mi ja fun eto idibo yii, ti ma si ri pe ẹgbẹ oṣelu PDP bori eto idibi" o sọ lasiko naa.
Ẹwẹ, lẹyin-ọ-rẹyin, Obi fidi janlẹ pẹlu oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Oseloka Obaze.
Adams Oshiomhole ati Godwin Obaseki - Ipinlẹ Edo
Adams Oshiomhole ko ipa nla lati ri pe Godwin Obaseki di gomina ipinlẹ Edo lẹyin to kuro ni ipo Gomina lẹyin ọdun.
Obaseki ṣiṣẹ labẹ Oshiomhole gẹgẹ bii alaga to n risi eto iṣuna ipinlẹ Edo, Edo State Economic Team.
Pẹlu bii wọn ti ṣe ni ajọsepọ to lerinrin ṣugbọn ija to waye laaarin wọn kọja nnkan ti a fi ẹnu wi.
Oshiomole lo agbara rẹ gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu APC lasiko naa lati ma fun Obaseki ni tikẹẹti lati gbe apoti ibo fun saa keji ṣugbọn Obaseki morile ẹgbẹ oṣelu PDP, to si tun bori eto idibo naa.