You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Seyi Makinde ṣèlérí mílíọ́nù márùn-ún náìrá fún ẹbí aṣọ́gbó kọ̀ọ̀kan tí agbébọn pa l'Oyo
Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọẹrọ Seyi Makinde, ti ṣeleri lati fun ẹbi kọọkan awọn aṣogbo marun-un ti awọn agbebọn pa nipinlẹ Oyo lọsẹ meji sẹyin ni miliọnu marun-un naira.
Yatọ si owo naa, Makinde tun ṣeleri lati ran awọn ọmọ oku ọrun naa nile ẹkọ lati ipele alakọọbẹrẹ de Yunifasiti.
Ana ode yii ni Gomina Makinde ṣeleri naa, lasiko to ṣabẹwo si igbo ọba ipinlẹ Oyo to wa lagbegbe Oloka, nibi ti awọn agbebọn ti mu ẹmi aṣogbo marun-un lọ lọjọ keje, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.
Ọwọ́ ti ba afurasí mẹ́ta nínú àwọn tó ṣèkọlù náà
Nigba to n tẹsiwaju ninu alaye rẹ, Gomina Makinde sọ pe afurasi mẹta ni ọwọ ti ba lori ikọlu ati ipaniyan naa.
"Lanaa ni a ṣabẹwo si Igbo ọba atijọ ipinlẹ Oyo, lati ba awọn eeyan agbegbe ibẹ sọrọ lẹyin ikọlu ọdaran to mu mu ẹmi aṣogbo marun-un lọ.
"Mo ba ẹbi awon aṣogbo to di oloogbe naa kẹdun, ki Oluwa tẹ wọn si afẹfẹ rere.
"Awọn agbofinro ti mu eeyan mẹta ti wọn jẹ afurasi ninu ikọlu naa, ti igbagbọ wa pe wọn lọwọ ninu rẹ, wọn yoo si foju wina ofin bo ṣe yẹ."
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye fun awọn eeyan Oloka, Makinde sọ pe oun yoo kọwe si Olori ologun lati gbe ibudo ologun kan wa sibẹ, lati mu aabo agbegbe naa nipọn si i.
"A maa ṣiṣẹ tọ atunṣe awọn nnkan amayedẹrun bii ọna to dara, ipese omi nilana ẹrọ igbalode (borelhole) ati ipese ina to n lo oorun (solar)''
Gomina Makinde lo ṣeleri bẹẹ.
O fi kun un pe ijọba oun yoo ri sanwo fun awọn ẹka ẹlẹrọ ibara ẹni sọrọ lati waa ri opo mọbẹ, ki ikansira ẹni le rọrun ju bo ṣe wa lọ.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ keje, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn kan ya wọ igbo ọba naa ti wọn si ṣina ibọn bolẹ.
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, pẹlu alaye pe awọn agbebọ naa to mejila .
Wọn ni bi wọn ṣe pitu aburu naa tan ni wọn sa lọ.
Ninu awọn fidio to ṣafihan iṣẹlẹ naa, ẹjẹ awọn aṣogbo to padanu ẹmi wọn naa wa nilẹ kiri.
Bẹẹ ni awọn apa ibi ti ikọlu naa kan fara han pẹlu.