You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gbajúgbajà olórin ẹ̀mí, Bunmi Akinnaanu 'Omije Oju Mi' jáde láyé
Gbajumọ olorin ẹmi, Bunmi Akinnaanu Adeoye, ti jade laye.
Ọkan lara awọn to sunmọ oloogbe ọhun tipẹtipẹ, Gbenga Samuel, lo fidi iroyin iku rẹ mulẹ fun BBC Yoruba.
Gẹgẹ bi Samuel ṣe sọ, nnkan biii aago mẹwaa alẹ ọjọ Iṣẹgun lo dake sile iwosan kan niluu Eko.
Ṣaaju ni obinrin naa ti kọkọ dubulẹ aisan fun ọjọ pipẹ ti awọn akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ orin ẹmi si n fi adura ran an lọwọ.
Ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ, ololufẹ ati ọrẹ rẹ lo ti bẹrẹ si n ṣedaro lori ayelujara.
Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan naa n ṣedaro ko si ẹni to sọ ni pato boya o ti papoda ni tabi o ṣi wa laaye.
Ki ni awọn eeyan n sọ?
Mega Testimony
Lara awọn to sunmọ Omije Oju Mi ni Mega Testimony ti oun naa jẹ olorin, ninu atẹjade to fi lede loju opo Facebook rẹ, niṣe lo n daro.
O fidi rẹ mulẹ pe ọkan oun n fa si olorin ẹmi naa ti oun si pe e lana ọjọ Iṣẹgun amọ awọn ko lanfani lati sọrọ.
O ni Omije Oju Mipe pe oun pada ni nnkan bii aago mẹrin ku iṣẹju mẹri irọlẹ, o si dabii pe igab ikẹyin ti awọn yoo sọrọ niyẹn.
Senwele Jesu
Akinade Olubukola Racheal ti ọpọ mọ si Senwele Jesu naa sọrọ loju opo rẹ, o ni "irora adura ti ko gba."
Awọn ololufẹ rẹ ti n ba kẹdun Omije Oju Mi loju opo rẹ, bẹẹ lawọn mii n sọ pe iroyin ẹlẹjẹ ni iroyi naa.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Ṣaaju ni Omije Oju Mi ti kọkọ n ṣaisan to si n lọ si awọn ile ijọsin fun iṣẹ adura lati bori aisan naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Lọdun to kọja ni fidio kan jade, nibi ti olorin ẹmi ọhun ti joko sori aga kan ti ẹsẹ rẹ mejeji si wu ti wolii kan si n gbadura fun iwosan rẹ.
Lẹyin naa ni awọn ololufẹ rẹ ko gbọ nnkankan mọ titi di asiko ti iroyin iku rẹ gba igboro kan yii.