You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Aarẹ Tinubu, Obasanjo, Sanwo-Olu atawọn eekan ilu mi-in ti ranṣẹ ibanikẹdun si Badagry.
Nitori Ọba Babatunde Akran, Wheno Aholu Menu-Toyi I to waja lọjọ Aje ana.
Wọn ni adanu nla ni iku olórí ọba Badagry naa fun ipinlẹ Eko ati Naijiria lapapọ.
Ẹkunrẹrẹ wa ni BBC.COM/YORUBA.
;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;;
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti ṣetan lati koju awọn agbébọn tó lawọn n bọ waa kọlù Ikoyi-Ile l'Ogbomoso.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, CSP Benjamin Hundeyin, lo sọ bẹẹ loju opo X rẹ.
Hundeyin ni iwadii ti jinna ni niluu naa latigba tawọn agbebọn ti kọ lẹta wa.
Ogunjọ oṣu yii ni awọn agbebọn tun ni awọn n bọ, lẹyin ti wọn pa ọdẹ aṣogbo marun-un l'Oyo lọsẹ to kọja.
Ka a loju opo wa
hhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhhh
BBC Yoruba de ile Ganiyat Ayanwale ti ọkọ gun pa ni River Valley Estate, ipinlẹ Ogun.
Ọkan lara awọn araale wọn ṣalaye pe Ayoola, ọkọ to gun un pa ko ṣẹṣẹ maa lu u.
O fẹ mọ ohun to sọ nipa ọkọ naa ati ohun to ṣẹlẹ gan-bi?
Fun ẹkunrẹrẹ