Ṣíṣe bíi Quadri kò ki í ṣe ohun tí mo ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀, ìdí rèé- Taooma

Ṣíṣe bíi Quadri kò ki í ṣe ohun tí mo ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀, ìdí rèé- Taooma

Gbajugbaja adẹrinposonu, Mariam Apaokagi-Greene, ẹni ti ọpọ mọ si Taaoma ni bi oun ṣe n ṣe bi ọdọmọkunrin, Quadri jẹ ohun ti oun ko ni lero tẹlẹ ṣugbọn to fẹ wa, ti ọpọ eeyan si tẹwọ gba.

Apaokagi Greene ba BBC Yoruba sọrọ lori irinajo aye rẹ paapa bi o ṣe n mu iṣe papọ pẹlu ọmọ bibi.

O ni oun ko ni lọkan pe oun yoo ṣe ẹda itan Quadri ṣugbọn oun to fẹ wa, to si jẹ ohun ti awọn eeyan

"Bi Quadri ṣe jẹ- mo ma n sọ pe Quadri ki n se ẹda itan ti mo gbero tẹlẹ.

"O ni ọjọ kan ti mo n ṣe, boya ipolowo abi nnkan mi, mo nilo eeyan lati ṣe nnkan fun mi, mow a ni o daa, jẹ ki n lọ soju opo Snapchat, bi mo ṣe ri ẹda aworan Quadri niyẹn, nitori mo ni ẹda eeyan lori mi bi awọn ọmọ ibadan ati Ilorin ṣe ma n ṣe, ti ẹnu wọn mu pupọ."

Ninu alaye rẹ, o ni gbogbo ere ti oun n gbe sita lo jẹ ida aadọrin ohun ti oun kọ lọwọ iya oun, ti ida ọgbọn yooku si jẹ ohun ti ohun ti oun fikun nitori pe oun ri pe awọn eeyan nifẹ oun ati ohun ti oun n gbe sita.

"Gbogbo awada yẹn, ka ni aadọrin, bi iya mi ṣe ma n ṣe niyẹn, ida ọgbọn yooku, mo fi kun ni, nitori pe mo ṣakiyesi pe awọn fẹran rẹ."