Iná jó èèyàn kan pa àti ilé 300 ní Australia

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Eeyan kan ti ku, nigba ti ọọdunrun ile jona gurugu lẹyin ina to ṣẹyọ ni Australia.

Iroyin ni fun ọpọ ọjọ ni ina ọhun fi jo kaakiri ilẹ naa, paapaa lagbe Victoria ati New South Wales.

Ijọba Victoria ti kede ilu o fararọ, ẹgbẹgbẹrun awọn oṣiṣẹ panapana ati ọkọ ofurufu bii ọgọrin si ti n koju ina ọhun.

Awọn alaṣẹ ni ibẹru awọn ni pe o ṣeeṣe ki ina naa jo fun ọpọlọpọ ọsẹ si asiko yii latari ọgbẹlẹ to wa lode ati ọwọ afẹfẹ lile.

Alakoso agbegbe Victoria, Jacinta Allan ni lọwọ yii, agbegbe bii ọgbọn ni ina ti n jo lọtọtọ, ti ewu nla si wa ninu mẹwaa ninu awọn agbegbe ti ina naa ti n jo.

Obinrin naa sọ pe nnkan bii 350,000 eeka ilẹ ni ina ti kan nipinlẹ ọhun.

O sọ fun ileeṣẹ iroyin Australia pe "ina ọhun yoo tẹsiwaju lati maa jo kaakiri awọn agbegbe kan nipinlẹ wa, a ko tii bọ ninu rẹ.

"Awọn ina kan ṣi n bọ bayii to lewu fun ile ati dukia awọn araalu."

Wọn ti ri oku ẹnikan ti ina jo pa labule Gobur, to jẹ bii 110km si ilu Melbourne to jẹ olu ilu orilẹede naa. Ọlọpaa ni awọn ko tii mọ ẹni ti oloogbe ọhun n ṣe.

Allan gboriyin fun awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi to ri oku ẹni naa, o tun ba awọn eeyan Gobur kẹdun.

Ọkan lara awọn to padanu ile wọn ni ọkunrin panapana kan, Tyrone Rice.

Rice ni ẹnu iṣẹ loun wa ti oun ti n pa ina to ran ile awọn eeyan ki oun to gbọ pe ina ti mu ile oun naa.

Akọroyin ileeṣẹ iroyin 9 News, Jack Ward, sọ fun BBC pe oun ti oun foju ri jẹ ohun to ba eeyan lọkan jẹ gidi.

Ward ni awọn agbeggbe to rẹwa tẹlẹ ti awọn eeyan n gbe ni ina ti sọ dahoro bayii.

Awọn alaṣẹ sọ pe ina ọhun ni eyii to buru julọ lagbegbe naa lẹyin ina to ṣẹyọ lọdun 2019 si 2020.

Ina ọhun pa eeyan mẹtalelọgbọn lọdun naa lọhun, agbegbe to jo si to gbogbo orilẹede Turkey.