Pásítọ̀ tó ní ayé yóò parẹ́ lọ́jọ́ Kérésì, kan ọkọ̀ ńlá, dèrò àhámọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ipari ọdun 2025 ni okiki ọkunrin ọmọ Ghana kan, Evans Eshun tawọn eeyan mọ si Ebo Noah, bu jade, nigba to kede pe aye yoo wa sopin lọjọ ọdun Keresimesi to kọja.

Ebo Noah ko sọ bẹẹ lasan, o tun kan ọkọ nla bii ti igba aye Noah inu Bibeli, o si ni kawọn ti ko ba fẹ ṣegbe tete wa wọ ọkọ ọla naa ki wọn too parẹ maye.

O ni oun gba iran kan lati oke wa, pe arọọda ojo yoo rọ fun ọdun mẹta gbako, eyi ti yoo bẹrẹ lọjọ ọdun Keresi to kọja.

Idi eyi naa lo ni oun fi kan ọkọ igbala, bi Oluwa ṣe pa oun laṣẹ, lati dena ijiya ọdun mẹta naa.

Bi ọjọ Keresi ṣe n sunmọle, awọn Kristẹni kan tu yaaya lọ sibi ọkọ Ebo Noah, wọn fẹ wọle ki ẹkun omi ma baa pa wọn.

Lọjọ ti Keresi ku ọla, Ebo Noah sọ fun wọn pe oun ko ti i pari ọkọ naa, o ni o ku diẹ ko pari.

Ṣugbọn iran ti pasitọ naa ri ko pada wa si imuṣẹ, aye ko parẹ lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2025, bẹẹ ni òjò ko kan debi ti yoo rọ rẹpẹtẹ.

Nigba naa lo si sọ fun wọn pe oun ti gba iran miran lati oke wa, to ni ojo naa ko ni i rọ mọ.

Ebo Noah ni sibẹ, Oluwa ni koun tun kan ọkọ pupọ si i.

.

Bawo ni pasitọ ṣe dero ahamọ?

Lẹyin iriran to pada ja si iran eke naa, awọn alaṣẹ ilẹ Ghana fa ọrọ naa le awọn agbofinro lọwọ.

Ẹka to n ri si ohun to n lọ lori ayelujara lo nawọ gan Ebo Noah lọjọ ti 2025 pari gan-an.

Agbegbe Weija-Gbawe, ni Accra ni wọn ti mu un lasiko to n sọrọ lọwọ lori ayelujara.

Ibẹ lo gba de kootu ilẹ Ghana kan, Adentan Circuit Court , lọjọ Keji, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.

Nibi igbẹjọ naa ti Adajọ Angela Attachie gbọ, ni wọn ti fi ẹsun gbigbe iroyin eke jade kan pasitọ naa, pẹlu alaye pe o ko ibẹru bojo ba awọn eeyan.

Laaarin oṣu Kẹjọ si Ikejila ọdun 2025 ni ile ẹjọ sọ pe Ebo Noah fi gbe awọn iran eke rẹ jade lori Facebook, Tiktok, Instagram, You Tube ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Adari iwadii ọtẹlẹmuyẹ, Seth Sewornu, ṣalaye pe ẹnikan digba-di agbọn rẹ lati Liberia, o wa si Ghana lati wọ ọkọ Ebo Noah, ti gbogbo rẹ si pada ja si irọ.

"Iwadii wa fidi ẹ mulẹ, pe Ebo Noah ki I ṣe Ojiṣẹ Oluwa, ile ẹkọ aladaani kan lo n ba wọn ṣọ. O si ni iwe ẹri HND lati ile ẹkọ Gbogboniṣe Accra."

Adajọ ni ki wọn fi pasitọ si ahamọ ọsẹ méjì na

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Adajọ Angela Attachie, paṣẹ pe ki Ebo Noah wa ni ahamọ fun oṣu meji na.

Yatọ si eyi, o ni ki wọn lọ ṣe ayẹwo ọpọlọ fun ọkunrin naa, lati mọ boya ilera rẹ pe lapa ibẹ yẹn.

Ile iwosan itọju ọpọlọ Pantang Psychiatric Hospital, ni adajọ ni ki wọn gbe e lọ ṣaaju igbẹjọ miran ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.

Ayẹwo yii ni ireti wa pe yoo ran igbẹjọ lọwọ.