Male Fertility: Wo àwọn oúnjẹ márùn ún tó ń mú kí àtọ̀ ọkùnrin dára sí i

Ọmọ bibi jẹ ohun to ṣe pataki ni igbe aye awọn ẹda paapaa ọkunrin ati obinrin.

Ohun pato to wọpọ laarin ọkunrin ati obinrin ni ore ọfẹ ti wọn ni lati sọ eso nipa bibi ọmọ ọkunrin ati obinrin.

Ọpọlọpọ nkan lo n fa airọmọbi lara ọkunrin ati obinrin, amọ awọn ounjẹ asaraloore kan wa lati mu atọ okunrin dara si.

Dokita Ugo Ezentirioha sọrọ lori awọn ounjẹ bii ẹja, ẹran, ẹyin ati awọn nkan miran

Ẹja

Jijẹ ẹja loorẹ koore paapaa eleyii to ni eroja ''Omega 3 fatty acids'' n ṣe atọ ọkunrin loore nipa ṣiṣẹ iranwọ fun bi ẹjẹ ṣe n lọ si ibi atọ ọkunrin.

Eso

Jijẹ eso ṣe pataki fun ọkunrin ki atọ rẹ le dara si.

Awọn eso bii ọgẹdẹ, carrot, ọsan, berries naa n ṣiṣẹ takuntakun lati jẹ ki atọ ọkunrin dara si.

Fun apẹrẹ, ọgẹdẹ ni eroja bi vitamin B1,C magnesium ati bromelain ti wọn n ṣiṣẹ takuntakun ni ara ọkunrin.

Bakan naa ni Carrot ni awọn eroja ara bii beta-carotene ti kii jẹ awọn sẹẹli ara ti ko dara ṣe aṣemaṣe.

Ọsan naa ni eroja Vitamin C ni ara.

Ẹfọ

Awọn ẹfọ to ba jẹ alawọ ewe ni awọn eroja ara bii folate, eleyii to n ran obinrin lọwọ ni ati tete loyun, ti o si ma n jẹ ki atọ ọkunrin duro ni ara obinrin.

Bakan naa ni ẹpa naa dara ni ara lati mu ki atọ ọkunrin dara si ni ara.

Ẹyin

Ẹyin jẹ ọkan lara awọn eroja to ṣe koko ni ara eniyan.

O ni awọn eroja ara bii vitamin E, zinc ati protein eleyii ti o fun awọn agọ ara awọn eniyan lati ṣiṣẹ.

Ẹyin le jẹ ki eroja ara ji pepe, ki atọ ara ọkunrin le ṣiṣẹ dara dara.

Tomato

Tomato naa n ko ipa ribiribi ninu awọn eroja ara paapaa ki atọ ọkunrin le dara si.

Wọn ni eroja ara ti orukọ rẹ n jẹ lycopene, eleyii to n mu ki ara ji pepe.

O dara ki ọkunrin ma a jẹ tomato daradara, ki atọ rẹ le dara.

Ẹran

Jijẹ ẹran dara ni ara bakan naa lo si ni awọn abawọn.

Ọkan lara awọn eroja to ni ni zinc, folic acid ati selenium to n mu ki ato okunrin dara si.

Amọ ko dara ki eniyan jẹ ẹ ni ajẹju nitori o le mu ki suga ara pọsi, to si le e fa ijamba si ara.

Ẹpa / Imumu

Orisirisi ẹpa to wa lo dara ni ara to si n mu ki atọ ọkunrin dara si ju tẹlẹ lọ ti wọn ba n jẹ loore-koore.

Awọn apẹẹrẹ ẹpa ni ''Tiger Nuts'' ti awọn kan n pe ni ofio tabi imumu, agbọn, asala ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Garlic, iyẹn ayuu ati awọn eso miran naa ni bii Vitamins C, E, B12, D ati zinc naa.