You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Igboho Ultimatum to Fulani: Ẹni bá mọ Sunday Igboho kó bá wa bẹ̀ẹ́ o, a ò mọ ibi tí a lè kó lọ, Seriki Fulani pariwo síta
Kini yoo ṣẹlẹ?
Ibeere ti ọpọ n beere lasiko yii ni yi.
Nitori pe o ku bii wakati diẹ si asiko ti gbendeke ọjọ meje ti eekan ọmọ Yoruba ni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho fun awọn Fulani lagbegbe Ibarapa yoo pe.
- ''Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo kò bẹ̀rù idúnkokò mọ́ni iléeṣẹ́ ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ àwọn Fulani darandaran''
- Igboho vs Fulani: Makinde ní ẹnikẹ́ni tó bá dúnkokò mọ́ Fulani láti kúró lórí ilẹ̀ Oyo yóò fojú winá òfin
- Alààfíà ló kú tí àwa Fulani ń wá ní Oyo báyìí- Miyetti Allah
- Iléẹjọ́ ní kí ìyà akẹ́kọ̀ọ́ Iléẹ̀kọ́ Deeper Life tó ní wọ́n fipá bóun lòpọ̀ yé sọ̀rọ̀ mọ́ lórí ayélujára
- Ooni Ile ife ṣàlàyé ohun tí Tinubu níló fún ilépa ipò ààrẹ lọ́dún 2023
Sẹriki Fulani ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Abdulkadir ti ke gbajare sita pe ẹnikẹni to ba mọ Oloye Sunday Igboho ko ba awọn rawọ ẹbẹ sii ni nitori pe ko si ibi ti awọn lee ko lọ bayii mọ lẹyin aadọta ọdun.
Alhaji Abdulkadir to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye pe gbogbo ibi to yẹ lawọn n sa kaakiri lọ bayii lati wa ọna abayọ si ọrọ naa.
O ni lootọ ijọba n fi awọn lọkan balẹ pe Sunday Igboho ko ni lee ṣe ohun to wi sibẹ gbogbo awọn eeyan to ba mọọ lawọn n bẹ bayii ki wọn ba awọn pẹtu sii ninu ki wọn si le joko sọrọ naa ni itubi inubi.
Alhaji Abdulkadir to ni bi awọn aletilapa darandaran to sọ ara wọn di darandaran naa ṣe n ṣọṣẹ fun awọn ọmọ onilẹ lagbegbe naa ni wọn n ṣọṣẹ fun awọn gan an pẹlu to jẹ Fulani to tẹdo si agbegbe naa.
Seriki ni awọn ti kan sawọn agbofinro, awọn si ti kan sawọn ọbalaye lagbegbe Ibarapa lati lee wojutu si ọrọ naa to si jẹ pe wọn n fi awọn lọkan balẹ ni pe yoo lojutu laipẹ.
O ni awọn ko palẹ ẹru kankan mọ nibẹ nitori awọn ko tilẹ mọ ibi ti awọn lee dorikọ nitori pe agbegbe naa ni gbogbo awọn mọ ni ile lẹyin ti ọpọ wọn ti gbe nibẹ fun ọpọlọpọ ọdun.
Igboho, Ará ìlú ni ẹ, òó kí ń ṣe ìjọba, lọ ní sùúrù- Afenifere
Ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Afenifere ti sọrọ lori aṣẹ ọlọjọ meje ti Oloye Sunday Adeyẹmọ fun awọn Fulani ni Oke Ogun nipinlẹ Oyo.
Ogbeni Yinka Odumakin ti o jẹ Akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, salaye ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba pe nitootọ ni ohun to n ṣẹlẹ ni Oyo n banilọkan jẹ.
O ni sibẹ Sunday Igboho kii ṣe gomina, bẹẹ ko si ninu ijọba bikoṣe ogidi ara ilu.
- Ìgbìmọ̀ aláàṣẹ Nàìjíríà ti buwọ́lu ọjọ́ orí ìfẹ̀yìntì tuntun fún àwọn olùkọ́
- Ẹgbẹ́ Afenifere bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu Aárẹ Buhari lórí gbèńdéke tí Akeredolu fún àwọn darandaran Fulani
- Wo ọnà tí olè gbà jàǹfàní ọkọ́ lọ́wọ́ ìjọba Eko kí ilẹ̀ ò í tó ṣú
- Wo ohun mẹ́fà tí yòó ṣẹlẹ̀ níbi ìbúra ìjọba tuntun Biden àti Harris
Ati pe gẹgẹ bii ara ilu, iwe ofin Naijiria ko faaye gba a lati paṣẹ kuro nilu fun ẹlomiran.
Odumakin ni gomina Makinde nikan lo lagbara lati paṣẹ bẹẹ gẹgẹ bi gomina Akeredolu ṣe se ni ipinlẹ Ondo.
Odumakin ni ẹgbẹ Afenifẹre ti parọwa fun Sunday Igboho lati ni suuru ki iran Yoruba fi le pa amukuru pẹlẹ ọrọ awọn Fulani ajinigbe yii.
O ṣalaye pe Gomina Makinde lo ni agbara lori eto aabo ipinlẹ rẹ.
O ni: " Ati pe iran Yoruba maa n bọwọ fun ofin " Federalism" ti a n practice ni eyi to fun Makinde lagbara lati daabo bo ara ipinlẹ rẹ"
- Seyi Makinde pàṣẹ fún àwọn ọlọ́pàá láti wádìí Sunday Igboho lórí gbèǹdéke tó fún àwọn Fulani
- Bí ẹ bá tó bẹ́ẹ̀ ẹ pàdé mi l'Òjé- Makinde; Wọ́n ń tàn Ẹ́ bí àbẹ́là- APC
- Ẹ wo ohun tí Seriki Fulani sọ fún gómìnà Makinde nípa Sunday Igboho
- Joe Biden Innauguration, Jill Biden: Tani ìyàwó Joe Biden tí yóò jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ nílẹ̀ Amẹrika?
- America Inauguration Joe: Wo àwọn eré orí ìtàgé tí Donald Trump ṣe kó tó fi ipò aàrẹ sílẹ̀
Ǹkankan kò gbọdọ̀ ṣe Sunday Igboho - Àwọn ọ̀dọ́ Ibarapa sí Makinde, Buhari:
Àwọn ọ̀dọ́ Ibarapa kìlọ̀ fún Makinde, Buhari lórí gbèndéke tí Igboho fún àwọn Fulani
Ẹgbẹ awọn ọdọ agbegbe Ibarapa labẹ asia Ibarapa youths consultative Forum ( IYCF ) ti kilọ fun aarẹ Muhammadu Buhari ati ijọba ipinlẹ Oyo lati sọra ṣe lori ọrọ Oloye Sunday Igboho.
Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ti sọ fun Gomina Makinde wi pe nkankan ko gbọdọ ṣe Igboho, lẹyin to fun awọn Fulani to wa ni agbegbe Ibarapa ni ọjọ meje lati kuro ni agbegbe naa.
Igboho ni tori ijinigbe ojoojumọ to n waye ni agbegbe naa ni o mu ki oun gbe iru igbesẹ bẹẹ.
Ati wi pe awọn Fulani bẹrẹ si ni jo ile ni agbegbe Igangan ni ipinlẹ Oyo, lẹyin ti Igboho ṣe ibẹwo si Sheriki awọn Fulani ni agbegbe naa, ti ọpọlọpọ ọdọ to jẹ Yoruba si farapa.
Ẹgbẹ Ibarapa Youth ninu ọrọ wọn sọ wi pe awọn wa lẹyin ọrọ ti Igbohọ sọ.
Ati wi pe ko si ọmọ Yoruba ododo ti yoo ri bi awọn Fulani ṣe dana sun ile, ti yoo si gboju kuro nibẹ.
Wọn fẹsun kan awọn Fulani darandaran lagbegbe naa wi pe awọn ni wọn n pa eniyan, ti wọn ji awọn eniyan gbe, ti wọn si n hu iwa ọdaran lagbegbe naa.
Gbendeke ti Igboho fun awọn Fulani naa ti da ọpọlọpọ rogbodiyan silẹ ni ipinlẹ Oyo, ti awọn Fulani ni agbegbe Ibarapa si ni awọn ko ni ibi kankan n lọ.
- Kíní Kọmíṣọ́nnà Ọlọ́pàá, mẹ̀kòó ṣe tí wọ́n fi rí ẹ̀wọ̀n gbére he ní Ekiti?
- Fulani kìí ṣe ajínigbé! Akeredolu kò ní ká pòórá nínú igbó ìjọba l'Ondo, ohun tí Gómìnà sọ rèé...- Miyetti Allah
- Ta ni Mohammad Buba Marwa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀gá àgbà àjọ NDLEA?
- Ìjọba àpapọ̀ gbé ₦10b kalẹ̀ fún ìpèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 alábẹ́lé
- Báwo ni èròjà Fáítámì D ṣe ń dáàbò bo àgọ́ ara wa?
Ni ọjọ Satide, ọjọ Kẹrindinlogun, oṣu kinni, ọdun 2021 ni iroyin jade lori ayelujara pe eekan ajafẹtọ Yoruba kan, Oloye Sunday Adeniyi ti ọpọ mọ si Sunday Igboho fun awọn Fulani ni gbendeke ọjọ meje lati fi ilẹ Yoruba silẹ.
Amọ,Gómìnà ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ní ìjọba kò sí lẹ́yìn Sunday Igboho lórí gbèǹdéke tó fún àwọn Fulani, to si paṣẹ fun àwọn ọlọ́pàá lati ṣe iwádìí rẹ̀.
Sunday Igboho fún Fulani Oyo ní gbèǹdéke, Seriki fulani yarí, ọlọ́pàá dá síi...
Wo ohun tí a mọ̀ nípa gbèdéke ti Sunday Igboho fún àwọn Fulani ní Ibarapa àti èsì tí wọ́n fún un
Ni ọjọ Satide, ọjọ Kẹrindinlogun, oṣu kinni, ọdun 2021 ni iroyin jade lori ayelujara pe eekan ajafẹtọ Yoruba kan, Oloye Sunday Adeniyi ti ọpọ mọ si Sunday Igboho fun awọn Fulani ni gbendeke ọjọ meje lati fi ilẹ Yoruba silẹ.
- Àbámọ̀ ni yóò gbẹ̀yin ẹgbẹ́ ''Association of Stingy Men'' tí kò fẹ́ náwó f'óbìnrin- Akeugbagold
- Wo ìdí tí Oluwo fi ń wọ ìbòmú lẹ́yìn tó ní covid-19 ò lè wọ ìlú Iwo láéláé
- Covid-19: Ilé aṣojú-ṣòfin l'Abuja dábàá kí ìjọba sún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ síwájú pẹ̀lú oṣù mẹ́ta
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlà lọ́sẹ̀ tó kọjá tó fi mọ́ bí Covid-19 ṣe gbẹ̀mí èèyàn 23 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
Gẹgẹ bi fidio to gba ori ayelujara kan naa ṣe fihan, Sunday Igboho wọ inu awọn Gaa Fulani kan lọ lagbegbe Ibarapa nibi ti o ti fun awọn Fulani to wa nibẹ ni gbendeke ọjọ meje eleyi ti yoo pari ni ọjọ kejilelogun, oṣu kini, ọdun 2021 lati fi ilẹ naa silẹ.
O ni eyi ko ṣẹyin bi "awọn eeyan ilẹ Yoruba ṣe ni awọn ko fẹ wọn"
Ọrọ yii ti da oniruuru ọrọ silẹ laarin awọn olugbe ipinlẹ Ọyọ ati ilẹ Yoruba lapapọ.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe awọn ti ohun to sọ lẹyin, ni awọn miran n sọ wi pe ta ni Igboho lati maa pa iru aṣẹ bẹẹ?
Ki ni Sunday Igboho sọ lori gbedeke ọlọjọ meje naa?
Ohun ti Sunday Igboho gbe igbesẹ ati ọrọ to sọ le lori ni gulegule ijinigbe to n waye lẹkun Ibarapa lẹnu lọwọlọwọ yii.
O ni laarin oṣu diẹ sẹyin awọn eekan ipinlẹ Ọyọ ati agbegbe Ibarapa ti awọn ajinigbe ti wọn fura si pe wọn jẹ Fulani darandaran ji gbe.
O ni yala ti wọn pa tabi fi gbowo gọbọi kii ṣe kekere eyi ti iwadii awọn si ti fihan pe awọn to n ṣe iṣẹ yii lọpọ igba maa n fara sinko si Gaa awọn Fulani kaakiri ti wọn kii sii foju wọn han sita.
Kinni Igboho tun sọ?
Nigba to ba ileeṣẹ iroyin BBC News Yoruba sọrọ, Oloye Sunday Igboho sọrọ ilẹ kun.
O ṣalaye iṣẹlẹ arakunrin kan to ti oke okun wale wa si ilu Igangan wa dako ṣugbọn tawọn Fulani kan da ẹran lọ jẹ oko rẹ.
O ni igba to lọ fi ẹjọ sun awọn aṣiwaju awọn Fulani naa ni wọn de e mọlẹ wọn si tẹẹ pa.
O ni eyi atawọn iṣẹlẹ miran lo faa ti oun fi woo pe ko yẹ ko ri bẹ ti oun fi ni asiko to lati kọrin O to gẹẹ.
Ki ni awọn Fulani n sọ bayii?
Amọṣa awọn alaṣẹ awọn Fulani ni ipinlẹ Ọyọ ti ṣalaye pe ko sohun to jọọ rara ati pe awọn eeyan wọn ko ni ibi kankan ti wọn n ṣi lọ gẹgẹ bi Igboho ti ṣe pa a laṣẹ.
Wọn ni ijọba lo laṣẹ ati ẹtọ lati gbe irufẹ gbedeke bẹẹ kalẹ, bẹẹ nigba ti ijọba tabi awọn agbofinro ko sọ ohun to jọ bẹẹ, ko si idi fun awọn lati gbe igbesẹ lori rẹ.
Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Seriki Fulani ni ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Yakubu Bello ṣalaye pe Oloye Igboho "mu madaru" wa saarin awọn olugbe agbegbe naa.
O ni Igboho n fa madaru laarin Yoruba atawọn Fulani nibẹ ni nitori ibagbepọ alaafia lo wa laarin awọn ẹya gbogbo lagbegbe naa.
- Miyetti Allah ní kí wọn wọ́gilé Amotekun, Sunday Igboho yarí
- Sunday Igboho yarí, ó fohùn ránsẹ́ sáwọn èèyàn tó ń pẹ̀gàn rẹ̀
- Opral Benson, ẹni ti oge ṣíṣe sọ di gbajúmọ̀ àti Yeye Oge ìlú Eko
- Ọjọ́ orí wo ló yẹ kí ikùn ẹ̀dá bẹ̀rẹ̀ sí tóbi?
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlà lọ́sẹ̀ tó kọjá tó fi mọ́ bí Covid-19 ṣe gbẹ̀mí èèyàn 23 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
Ninu ọrọ rẹ, Alhaji Bello ni lootọ Oloye Sunday Igboho mu ibẹru ba awọn eeyan nibẹ.
Sugbọn wọn ko ni faaye silẹ fun ohun to lee fa ipinya laarin awọn Fulani ati Yoruba nibẹ.
" Awọn ijọba ti gbe igbesẹ lori ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe naa. Ni ipinlẹ Ọyọ, alaafia wa fun wa, Yoruba ati Fulani, ọmọ iya kan naa ni wa.
Inu oko kan naa lawọn Fulani ati agbẹ n gbe. Bi ibajẹ kankan ba si waye laarin wọn, wọn yoo yanju rẹ laarin ara wọn laisi wahala kankan."
Seriki Fulani ni ipinlẹ Ọyọ ni awọn Fulani ko lee kuro lagbegbe naa gẹgẹ bi Igboho ṣe sọ, awọn fa ọrọ naa le ijọba lọwọ nitori pe ijọba lo ni ilu, awọn lo si lẹtọ lati gbe igbesẹ lori ọrọ naa.
Ki ni awọn ọlọpaa sọ sii?
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi ṣalaye fun BBC News Yoruba pe ọrọ naa ko ṣe ajeji si awọn ọlọpaa.
O ni yatọ si pe wọn ti da awọn ọlọpaa ati ikọ agboguntiwa ibajẹ si agbagbe naa, awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ti n forikori lori ohun ti wọn yoo ṣe si ọrọ naa.
O fi kun un pe pipana rogbodiyan tabi wahala to lee fẹ ṣuyọ lawọn ọlọpaa wa fun, wọn si ti n gbe igbesẹ gbogbo lati rii pe ko si ohunkohun tabi ẹnikẹni to da omi alaafia ilu ru.