Igboho Ultimatum to Fulani: Sunday Igboho wà lọ́nà Ibarapa, Seriki Fulani ní àwọn kó níbiì lọ, àrọ̀wà ló kù

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkan awọn eeyan ni ipinlẹ Ọyọ, paapaa awọn eeyan agbegbe Ibarapa ṣe n fo lori gbendeke ti Oloye Sunday Igboho fun awọn Fulani to n gbe lagbegbe naa ṣe lonii ọjọ Ẹti.

Sẹriki Fulani, Alhaji Abdulkadir ṣalaye fun BBC News Yoruba pe inu Gaa awọn lawọn ṣi wa ni ireti pe aawọ ati aigbọraẹniye naa yoo pari ni tubi inubi.

Bi a ṣe n sọrọ yii, ikọ Oloye Sunday Igboho ti gbera kuro ni ilu Ibadan ti wọn si ti morile agbegbe Ibarapa lati lọ ree fi idi ileri ti wọn ṣe ni ọjọ Ẹti.

to kọja pe awọn yoo wa le awọn Fulani kuro lagbegbe naa mulẹ.

Gẹgẹ bi ọrọ ti a gbọ lati ẹnu ikọ Oloye Sunday Igboho, gbogbo wọn ati olori wọn ni wọn ti mu irinajo pọn bayii.

Ninu ifọrọwerọ rẹ, Alhaji Abdulkadir, Seriki Fulani ṣalaye pe awọn ọlọpaa ti wa ni Gaa wọn nibẹ lati fi idi ofin ati alaafia mulẹ.

Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin nile Igboho laarọ yii?

Ikọ iroyin BBC News Yoruba wa ni ile Oloye Igboho lowurọ oni lati mojuto gbogbo igbera rẹ.

Sugbọn lasiko ti eekan ọmọ Yoruba naa yoo fi gbera kuro nile rẹ, ko si akọroyin to lee sọ nitori gbogbo awọn oniroyin ni wọn ni ko ṣe gaya fun un naa nitori ati jade rẹ ko pẹ mọ.

Amọṣa ni asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, ohun ti a kojọ pọ lati ọdọ awọn ikọ rẹ ti wọn jumọ rinrinajo naa ni pe awọn ti wa lọna.

Ati pe, laipẹ ni wọn yoo si gunlẹ si Ibarapa ti wọn yoo si morile Gaa awọn Fulani naa.

Alààfíà ló kú tí àwa Fulani ń wá ní Oyo báyìí- Miyetti Allah

Lọwọlọwọ ni awọn eeyan ipinlẹ Oyo n gbe ni inu fu, aya fu latari gbendeke ọjọ meje ti Sunday Igboho fun awọn Fulani.

Gbendeke yii ko ṣẹyin bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe ti wọn tun n pa awọn ọmọ ilu ni ẹkun Oke Ogun ni ipinlẹ Oyo.

Eyi si ti mu oriṣiriṣi jade pẹlu Igboho, Makinde ati awọn eekan ilẹ Yoruba.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ni pe ẹgbẹ awọn Onimaalu, Miyetti Allah ti n pe fun alaafia ki ọla to jẹ gbendeke Oloye Sunday Adeyemo to pe.

Alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Oyo, Alhaji Saliu Ibrahim Dede lo fi atẹjade sita pe alaafia ati iṣọkan lo ku lasiko yii ti Miyetti Allah n wa ni ẹkun Oyo.

Dende ni o ṣe pataki ki awọn Yoruba gba awọn Fulani tọwọtẹsẹ ki awọn ẹya mejeeji jọ mojuto aabo ati alaafia awọn olugbe ẹkun naa lasiko yii.

O ni lootọ ni awọn iṣẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan ẹkun Igangan ati Ibarapa kọnilominu ati pe iran kọọkna lo ni awọn ọmọ buruku laarin awọn eeyan rẹ ṣugbọn eyi ko sọ pe gbogbo iran naa ni ko dara.

Adari Miyetti Allah naa ni iṣoro eto aabo naa ko dun mọ awọn Fulani ninu ṣugbọn o parọwa fun Oloye Igboho lati yọwọ ninu gbendeke ọjọ meje naa.

O ni ki Igboho fi ayọ tẹwọgba awọn Fulani ni wọn n fẹ.

O ni awọn ṣetan lati jọwọ awọn ti ade iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori silẹ fun ofin.

A ti pe ki ipade maa wa loorekoore laarin awọn agbẹ ati darandaran.

Ẹ wo ohun tí Seriki Fulani sọ fún gómìnà Makinde nípa Sunday Igboho

Seriki Fulani fi ẹjọ́ Sunday Igboho sun gómìnà Makinde nípa gbèǹdéke tó fún wọn

Lẹyin ti iroyin ti n ja ranyinranyin nilẹ pe Oloye Sunday Igboho ti fun awọn Fulani lagbegbe Ibarapa ni ipinlẹ Ọyọ ni gbendeke ọjọ meje lati fi agbegbe naa silẹ, awọn Fulani lagbegbe naa ti ke gbajare tọ Gomina Makinde lọ.

Seriki Fulani nipinlẹ Ọyọ, Alhaji Saliu Abubakar ṣalaye fun amugbalẹgbẹ gomina ipinlẹ Ọyọ lori ọrọ aabo, Sunday Odukọya ohun to ṣẹlẹ.

O ni pe ọpọlọpọ awọn fulani to n gbe ni Gaa naa ni wọn farapa lasiko ti Oloye Sunday Igboho atawọn ọmọlẹyin rẹ wa si agbegbe naa.

O ni ahere meje lawọn to ba oloye Sunday Igboho kọwọrin wa dana sun.

O ni bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ṣi jẹ iyalẹnu fun awọn ti o si n ke si ijọba lati gba awọn silẹ.

Aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ naa, Ọgbẹni Odukọya rọ awọn Fulani naa lati fọwọ wọnu o si ṣeleri fun wọn pe ijọba yoo ṣe iwadii to ba tọ lori rẹ.