You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ondo Fulani ultimatum: Ìjọba Ondo ní òun kò bẹ̀rù idúnkokò mọ́ni iléeṣẹ́ ààrẹ lórí gbèdéke tó fáwọn darandaran
Ẹru o bodo, ẹni ti yoo wọ odo lominu n kọ.
Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe oun ko bẹru idunkoko mọni lati ileeṣẹ aarẹ lori ọrọ awọn Fulani darandaran nipinlẹ naa.
Ṣaaju akoko yii lọjọ Iṣẹgun ọjọ kọkandinlogun, oṣu kinni, ọdun 2021 yii ni ijọba ipinlẹ Ondo sọ fawọn darandaran to wa ninu igbo ijọba pe ki wọn forukọ silẹ pẹlu ijọba, bii bẹẹ kọ, wọn gbọdọ fi igbo ọba silẹ.
Lẹyin naa ni agbẹnusọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu sọ pe ijọba Ondo ko laṣẹ lati le ẹnikankan kuro lori ilẹ ti wọn ba n gbe nibi kibi ni Naijiria.
- Igboho vs Fulani: Makinde ní ẹnikẹ́ni tó bá dúnkokò mọ́ Fulani láti kúró lórí ilẹ̀ Oyo yóò fojú winá òfin
- Àwọn Ọba ló rànṣẹ́ pè mi pé ìyá ìjínigbé àti ìpànìyàn yì tó gẹ́- Sunday Igboho
- Ìsọkúsọ ni Garba Shehu ń sọ, Akeredolu láṣẹ láti lé darandaran kúró nínú igbò l'Ondo- Ogunye
- Àwọn agbébọn ti jí àwọn arìnrìnàjò gbé ní ìpínlẹ̀ Osun!
- Gbogbo ẹ̀yin Fulani darandaran tó wà ní ìgbó ìjọba ní Ondo, ọjọ méje lẹní láti pòórá - Gomina Akeredolu
- Àwọn agbébọn ti yìnbọn pa igbákejì akọ̀wé FUTA
Ẹwẹ, ajọ Northern Elders' Forum (NEF) naa sọ fawọn Fulani darandaran to wa l'Ondo lati kọ eti ikun si gbedeke ti gomina fun wọn.
Ṣugbọn akọwe iroyin fun Gomina Rotimi Akeredolu, Segun Ajiboye sọ fun BBC Yoruba pe idunkoko lati ileeṣẹ aarẹ ko le dẹru ba ijọba ipinlẹ Ondo.
Ọgbẹni Ajiboye sọ pe amofin agba to mọ tifun-tẹdọ ofin ni Gomina Akeredolu, nitori naa ko si ẹnikan to le ṣe ohun to lodi si ofin.
Akọwe iroyin fun Gomina Ondo ni ofin lo gbe orilẹede Naijiria ro.
O ni aabo eeyan ipinlẹ Ondo lo jẹ ijọba Gomina Akeredolu logun bayii, kii ṣe ipo tabi agbara.
O fikun ọrọ rẹ pe akeregbe lo maa juwe ibi a fokun si lọrọ naa maa jẹ lori gbedeke ọjọ meje ti ijọba fawọn darandaran nipinlẹ Ondo.
- Lere Paimo ṣàlàyé bí fíìmù "Ogbori Elémosho" ṣe sọ ọ̀ di Olóyè MFR pẹ̀lú Dangote àti Adenuga
- "Adájọ́, ẹ má tú wa ká, mo sì nífẹ̀ẹ́ ọkọ mi bó tilẹ̀ jẹ́ pé alágbèrè pásítọ̀ ni"
- Wo ọnà tí olè gbà jàǹfàní ọkọ́ lọ́wọ́ ìjọba Eko kí ilẹ̀ ò í tó ṣú
- Iléẹjọ́ ní kí ìyà akẹ́kọ̀ọ́ Iléẹ̀kọ́ Deeper Life tó ní wọ́n fipá bóun lòpọ̀ yé sọ̀rọ̀ mọ́ lórí ayélujára
- Wo orílẹ̀-èdè tí ọ̀kọ̀ọ́kan àwọn aṣojú Naijiria yóò ti ṣiṣẹ́ jákèjádò àgbáyé
Ẹgbẹ́ Afenifere bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu Aárẹ Buhari lórí gbèńdéke tí Akeredolu fún àwọn darandaran Fulani
Ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Afenifere ti bu ẹnu ẹtẹ lu bi ileesẹ aarẹ Naijiria ṣe koro oju si gbedeke ọjọ meje ti ijọba ipinlẹ Ondo fun awọn darandaran Fulani, lati kuro ni gbogbo igbó nlanla nipinlẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Yinka Odumakin fi sita l'Ọjọru lo ti sọ pe ohun ti ileesẹ aarẹ sọ yii ko jẹ iyalẹnu, o ni sugbọn àṣẹ Gomina Rotimi Akeredolu ni ẹgbẹ naa faramọ.
"Bo ṣe jẹ pe lasiko ti Gomina Akeredolu fun awọn darandaran naa ni gbedeke láti fi ipinlẹ Ondo silẹ, ni ileesẹ aarẹ to o gbọ ohun àwọn ará ipinlẹ Ondo fihan pe ọrọ to ba kan ẹ̀yà Fulani nìkan lo ma n ka ijọba to wa l'ode lára."
O ṣalaye pe ipalara to pọ ni awọn ọdaran Fulani ti mu ba ipinlẹ Ondo, ati awọn ìlú ati abule mii nilẹ Yoruba lasiko yii.
O ni " ijọba to fẹ ẹ fi ojuṣe rẹ silẹ lai ṣe bi ti ijọba apapọ, ni yoo kawọ gbera lori ọrọ naa".
O fikun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ Afenifere faramọ erongba ijọba ipinlẹ Ondo lori bo ṣe sọ pe ìhà kò kan mi ni itumọ ọrọ ti agbenusọ Ààrẹ Buhari, Garba Shehu sọ.
O kesi gbogbo ọmọ Yoruba tootọ lati ti Gomina Akeredolu lẹyin lori ipinnu rẹ.
"Gomina gbọdọ lo gbogbo agbara to wa ninu ofin lati le gbogbo awọn ọdaran kuro ninu awọn igbó to wa nipinlẹ Ondo.
" Gbogbo awọn gomina yooku naa si gbọdọ fi alaga wọn ṣe awokọse. "
Ìsọkúsọ ni Garba Shehu ń sọ, Akeredolu láṣẹ láti lé darandaran kúró nínú igbò l'Ondo- Ogunye
Isọkusọ ni oludamọran fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu n sọ lori ọrọ awọn darandaran ti ijọba ipinlẹ Ondo sọ pe ki wọn kuro ninu igbo ijọba ti wọn ko ba ti forukọ silẹ.
Shehu to jẹ oludamọran fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ royin sọ pe aṣẹ ti Gomina Rotimi Akeredolu pa lodi si iwe ofin orilẹede Naijiria.
Shehu ni o kuna fun Gomina Akeredolu lati le awọn darandan to ti n gbe ipinlẹ Ondo ni gbogbo aye wọn kuro ninu igbo ijọba nitori awọn aṣawọ kan to n ṣiṣẹ ibi.
- Ǹkankan kò gbọdọ̀ ṣe Sunday Igboho - Àwọn ọ̀dọ́ Ibarapa sí Makinde, Buhari
- Àwọn Ọba ló rànṣẹ́ pè mi pé ìyá ìjínigbé àti ìpànìyàn yì tó gẹ́- Sunday Igboho
- Gbogbo ẹ̀yin Fulani darandaran tó wà ní ìgbó ìjọba ní Ondo, ọjọ méje lẹní láti pòórá - Gomina Akeredolu
- Darandaran tí kò bá forúkọ sílẹ̀ gbọdọ̀ fi ìgbó ìjọba sílẹ̀ l'Ondo, Akeredolu fèsì sọ́rọ̀ Garba Shehu
- Seyi Makinde pàṣẹ fún àwọn ọlọ́pàá láti wádìí Sunday Igboho lórí gbèǹdéke tó fún àwọn Fulani
- Ẹ wo ohun tí Seriki Fulani sọ fún gómìnà Makinde nípa Sunday Igboho
Ṣugbọn agbẹjọro ati ajafẹtọ, Jiti Ogunye ni ko si ohun to kan Shehu ninu ọrọ naa.
Ati wi pe, ta lo sọ pe Shehu ni agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn darandaran, Miyetti Allah?
Agbẹjọro Ogunye ni ohun ti Akeredolu sọ wa ni ibamu pẹlu iwe ofin orilẹede Naijiria.
''Ojuṣe gomina ni lati pese eto abo to peye fawọn araalu, nitorinaa, ohun to dara ni Akeredolu n ṣe,'' Jiti Ogunye ṣalaye.
- Wo ọnà tí olè gbà jàǹfàní ọkọ́ lọ́wọ́ ìjọba Eko kí ilẹ̀ ò í tó ṣú
- Wo ohun mẹ́fà tí yòó ṣẹlẹ̀ níbi ìbúra ìjọba tuntun Biden àti Harris
- "Adájọ́, ẹ má tú wa ká, mo sì nífẹ̀ẹ́ ọkọ mi bó tilẹ̀ jẹ́ pé alágbèrè pásítọ̀ ni"
- Lere Paimo ṣàlàyé bí fíìmù "Ogbori Elémosho" ṣe sọ ọ̀ di Olóyè MFR pẹ̀lú Dangote àti Adenuga
Ogunye ni ijọba apapọ ko laṣẹ lori ilẹ awọn ipinlẹ ni Naijiria, o ni ilẹ ti ijọba apapọ laṣẹ lori rẹ ko ju ilẹ ilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria lọ.
Ogunye ni ko tiẹ boju mu ki awọn eeyan maa da ẹran ninu igbo ijọba, o ni oun ti igbo ijọba wa fun kọ niyẹn.
O ni ọpọ awọn eeyan lawọn daran daran ti da ẹmi wọn legbodo, koda o ni ti ṣẹlẹ si mọlẹbi oun kan ri.
Agbẹjọro Ogunye ni ọrọ orilẹede Naijiria nilo asọyepọ lori bawọn eeyan kan ṣe maa n gbe ọrọ ti ko kan wọn sori ju ọlọrọ gan an lọ.
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Joe Biden, aàrẹ tuntun ilẹ̀ America
- Fulani kìí ṣe ajínigbé! Akeredolu kò ní ká pòórá nínú igbó ìjọba l'Ondo, ohun tí Gómìnà sọ rèé...- Miyetti Allah
- Ta ni Mohammad Buba Marwa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀gá àgbà àjọ NDLEA?
- Kíní Kọmíṣọ́nnà Ọlọ́pàá, mẹ̀kòó ṣe tí wọ́n fi rí ẹ̀wọ̀n gbére he ní Ekiti?
Darandaran tí kò bá forúkọ sílẹ̀ gbọdọ̀ fi ìgbó ìjọba sílẹ̀ l'Ondo, Akeredolu fèsì sọ́rọ̀ Garba Shehu
Ijọba ipinlẹ Ondo ti da ijọba apapọ lohun lẹyin to sọ pe Gomina Rotimi Akeredolu ko laṣẹ lati le awọn darandaran kuro ninu igbo ijọba l'Ondo.
Ninu atẹjade ti oludamọran fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu fi sita lọjọ Iṣẹgun, o ṣalaye pe igbesẹ naa tapa si ofin orilẹ-ede Naijiria.
Shehu ni o kuna fun Gomina Akeredolu lati le awọn darandan to ti n gbe ipinlẹ Ondo ni gbogbo aye wọn kuro ninu igbo ijọba nitori awọn aṣawọ kan to n ṣiṣẹ ibi.
Oludamọran si aarẹ ni o kuna fawọn ọmọ Naijiria lati maa sọ pe ẹya kan tabi awọn eeyan ipinlẹ kan lo wa nibi iṣẹlẹ ijinigbe ati awọn iwa ọdaran mii.
O ni ijọba aarẹ Buhari ṣetan lati rii pe awọn eeyan n tẹle ofin iwe orilẹede Naijiria, eleyi to jẹ ki ijọba sọ fawọn ẹgbẹ awọn musulumi kan to ni ki Biṣọọbu ilu Sokoto Matthew Hassan Kukah wọn ko laṣẹ lati sọ fun un pe ko fi ilu naa silẹ.
- Seyi Makinde pàṣẹ fún àwọn ọlọ́pàá láti wádìí Sunday Igboho lórí gbèǹdéke tó fún àwọn Fulani
- Ìjọba àpapọ̀ gbé ₦10b kalẹ̀ fún ìpèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 alábẹ́lé
- Báwo ni èròjà Fáítámì D ṣe ń dáàbò bo àgọ́ ara wa?
- Ọkọ̀ agbépo bẹ́ntiról kankan kò gbọdọ̀ gun afárá nípínlẹ Ogun mọ́ - Gomina Dapo Abiodun
Ṣugbọn kọmisọnna eto iroyin ipinlẹ Ondo, Donald Ojogo ṣalaye pe ijọba ko ni ki awọn Fulani fi ipinlẹ naa silẹ.
''Ohun ti Gomina sọ ni pe awọn darandan to ko ba forukọ silẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Ondo gbọdọ fi igbo ijọba silẹ,'' Ojogo ṣalaye.
O ni ọrọ ti Shehu sọ dabi ki eeyan maa dakun iṣoro to wa nilẹ tẹlẹ ni eleyi to si ṣakoba fun iṣokan orilẹede Naijiria.
Ojogo ni ijọba ipinlẹ Ondo si wa lori ẹsẹ rẹ pe awọn darandran ti ko ba forukọ silẹ gbọdọ kuro ninu igbo ijọba laarin ọjọ meje.
- Ẹ wo ohun tí Seriki Fulani sọ fún gómìnà Makinde nípa Sunday Igboho
- Gbogbo ẹ̀yin Fulani darandaran tó wà ní ìgbó ìjọba ní Ondo, ọjọ méje lẹní láti pòórá - Gomina Akeredolu
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Joe Biden, aàrẹ tuntun ilẹ̀ America
- Bí ẹ bá tó bẹ́ẹ̀ ẹ pàdé mi l'Òjé- Makinde; Wọ́n ń tàn Ẹ́ bí àbẹ́là- APC
Fulani kìí ṣe ajínigbé! Akeredolu kò ní ká pòórá nínú igbó ìjọba l'Ondo, ohun tí Gómìnà sọ rèé...- Miyetti Allah
Alaga ẹgbẹ awọn Fulani darandaran, Miyetti Allah Cattle Breeders Association (MACBAN) nipinlẹ Ondo, Alhaji Bello Garba ti sọrọ soke lori aṣẹ Gomina akeredolu.
O ni pe irọ funfun balau ni iroyin to sọ pe Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti awọn Fulani darandaran ni ọjọ meje lati kuro ni igbo ijọba to wa ni ipinlẹ naa.
Alhaji Bello to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe Gomina Akeredolu nifẹ araalu ati alejo ju ko paṣẹ pe ki awọn Fulani kuro l'Ondo.
Alaga Miyetti Allah l'Ondo sọ pe oun atawọn ọmọ ẹgbẹ awọn ṣe ipade pọ pẹlu Gomina Akeredolu lọjọ Aje lati bi ago mẹkanla to fi di ago kan ọsan.
Ki wa ni Miyetti allah sọ pe Gomina Akeredolu sọ fun awọn?
Alhaji Garba ni ''oun ti Gomina sọ ni pe oun ko fẹ ki awọn ọmọ kekeke maa da maalu mọ nipinlẹ Ondo.
Gomina tun sọ pe Fulani kankan ko gbọdọ da ẹran ninu igboro mọ.
Gomina Akeredolu tun sọ fun wa pe a ko gbọdọ da ẹran ninu igbo ijọba loru mọ.
Akeredolu tun sọ fun wa atawọn agbẹ pe ki a wa lojufo nitori awọn to n fi orukọ Fulani ṣe iṣẹ ibi nipinlẹ Ondo.
Gomina tun fun awa Fulani darandaran to ba fẹ ma a ṣiṣẹ ni ipinlẹ Ondo lati fi orukọ wọn silẹ pẹlu awọn alaṣẹ,'' Alaga Miyetti Allah ṣalaye.
Alhaji Garba fikun ọrọ rẹ pe awọn eeyan ti maa n ṣaaba sọ pe Fulani lawọn ajinigbe nigba kuu gba ti iṣẹlẹ ijinigbe ba ti ṣẹlẹ.
''Fulani kii ṣe ajnigbe, ẹgbẹ ni awọn ajinigbe, wọn kii ṣe Yoruba, bẹẹ ni wọn kii ṣe Igbo,'' alaga Miyetti Allah lo sọ bẹẹ.
O ṣalaye pe eto aabo to mẹhẹ nipinlẹ Ondo ko ṣẹyin bi ipinlẹ naa ṣe ni ibode pẹlu ipinlẹ Edo, Ekiti. Ogun ati Kogi.
- Ẹ wo ohun tí Seriki Fulani sọ fún gómìnà Makinde nípa Sunday Igboho
- Ìjọba Eko ṣàlàyé ìdí tó fi ṣí iléèwé padà bí covid-19 ṣe ń pọ̀ síi lójoojúmọ́ níbẹ̀
- Ó lé ní ọgọ́rin èèyàn tó kú nínú ìjà ẹlẹ́yàmẹ́yà tó wáyé ní Dafur- Aláṣẹ Sudan
- Gbogbo ẹ̀yin Fulani darandaran tó wà ní ìgbó ìjọba ní Ondo, ọjọ méje lẹní láti pòórá - Gomina Akeredolu
- Àwọn agbébọn ti yìnbọn pa igbákejì akọ̀wé FUTA