Ondo Fulani ultimatum: Gbogbo ẹ̀yin Fulani darandaran tó wà ní ìgbó ìjọba ní Ondo, ọjọ méje lẹní láti pòórá - Gomina Akeredolu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti fun awọn Fulani darandaran ni ọjọ meje lati kuro ni igbo ijọba to wa ni ipinlẹ naa.

Gomina Akeredolu fi aṣẹ yii lede loju opo ikansiraẹni Twitter rẹ.

O ni ọna lati dẹkun gbogbo iwa ọdaran to fi mọ ijinigbe to peleke ni ipinlẹ naa.

Akeredolu ni awọn Fulani darandaran ti sọ igbo ijọba ni ibujoko awọn ọdaran ati awọn ajinigbe, ti wọn si n lọ awọn agbegbe yii lati sapamọ kuro lọwọ ijọba.

''Ọpọlọpọ ijinigbe ni a ti tọ ipasẹ rẹ lọ si ọdọ awọn to n kaakiri gẹgẹbi darandaran, ti wọn si lọ igbo ijọba lati ko awọn eniyan pamọ ati lati gba owo lọwọ awọn ẹni ti wọn ba jigbe.''

''Gẹgẹ bi alasẹ lori eto aabo nipinlẹ Ondo, mo ṣetan lati da abo bo awọn eniyan ati ohun inu wọn ni ipinlẹ Ondo.''

''Nitori naa mọ paṣẹ pe ki gbogbo awọn darandaran to ba wa ni igbo ijọba kuro nibẹ ni aarin ọjọ meje''

''Mo fopin si dida ẹran kaakiri igboro ni alẹ ni kiakia, nitori ọpọlọpọ oko ni wọn n bajẹ ni alẹ.''

''Ko gbọdọ si dida ẹran laarin igboro ati opopona ni ipinlẹ Ondo mọ.''

''Ko gbọdọ si awọn ọmọde ti yoo ma da ẹran kaakiri ipinlẹ Ondo''

Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu wa fikun wi pe ijọba ipinlẹ naa ninu aanu rẹ wa fun wọn ni gbedeke ọjọ meje fun awọn Fulani darandaran to ba fẹ ma a ṣiṣẹ ni ipinlẹ Ondo lati fi orukọ wọn silẹ pẹlu awọn alaṣẹ.