Chief (Mrs.) Opral Benson: Ìdí rèé tí Oba Eko ṣe fi Olóyè Opral Benson jẹ Yeye Oge ìlú Eko

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ eeyan ni ko mọ ohun to mu ki Ọlọlajulọ, Oba Eko nigba kan ri, Oba Adeyinka Oyekan fi Opral Benson jẹ oye Yeye ilu Eko.

Lọdun 1973 ni eto naa waye nibi ti Oba Oyekan to ti waja bayii ti fi Mama Benson jẹ oye.

Mama Benson to ti pe ẹni ọdun marunlelọgọrin bayii di Yeye Oge ilu Eko nitori bi o ṣe maa n mura daadaa nigba naa lasiko ni orilẹ-ede Naijiria ṣẹṣẹ gba ominira.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọ lo tilẹ ro pe inagijẹ lasan ni ni Yeye Oge ti Benson n jẹ.

Rara o, Oba Eko lo fi oye naa da a lọla nitori bi o ṣe gboge lawujọ.

Oloye Rasheed Gbadamosi, onimọ nipa iṣowo to ti di oloogbe bayii sọ nigba aye rẹ nipa bi Benson ti gbajugbaja pẹlu ara mimu ati oge ṣiṣe nigba to fi wa ni sangoode.

Oloye Gbadamosi ni gbogbo eeyan ni Benson maa n da lọrun nigba naa pẹlu imura rẹ ati bi o ṣe gbọ oge,

Koda. Oloye Gbadamosi kọ ọrọ apilẹkọ nipa Mama Benson nigba to pe ọgọrin ọdun loke eepẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Oloye Gbadamosi ṣalaye pe ''lẹyin to ṣe igbeyawo tan pẹlu Oloye T.O.S. Benson, ti o si fi Liberia orilẹede abinibi rẹ silẹ wa si ilu Eko, o di ẹni aji tana wo laarin ọdun mẹrin ni Naijiria.''

''Lakọkọ, imura rẹ ati bi o ṣe gboge lo jẹ ko di ẹni ti gbogbo eeyan fẹran, ati ọkunrin ati obinrin lo nifẹ rẹ,'' Oloye Gbadamosi lo sọ bẹẹ.

Koda. Mama Benson ko ṣe akitiyan kankan lati di ẹni tawọn akọroyin n kọ nipa rẹ ti wọn fi bẹrẹ si ni gbe iroyin nipa orekelẹwa naa.

Bi awọn oniwe iroyin ṣe n kọ nipa Benson lawọn sọrọsọrọ lori ẹrọ amohunmaworan naa n gbe wa sori eto.

Opral Benson pe ọdun marunlelọgọrin laipẹ yii, ṣugbọn ko tiẹ da bi ẹni to ti pe ọdun marunlelọgọrin loke eepẹ.

Opral Benson gboge de bi pe o da ileeṣẹ iṣaraloge, Chic Afrique Beauty Company Ltd. silẹ.

O tun da omiran Opral Benson Beauty Training Institute silẹ lọdun 1985.

Nibo ni Opral Benson ti wa?

Wọn bi Opral Benson si idile Johnson ati Lilly Mason ni Arthington lorilẹede Liberia ni awujọ awọn ọlọrọ lati ilẹ Amẹrika ni Liberia.

Awọn baba nla rẹ wa si Liberia lati ipinlẹ South Carolina lati orilẹede Amẹrika lọdun 1869.

Ẹgbọn baba rẹ kan lobinrin, Aunty Margaret lo kọkọ sọ ọ ni Opal eyi ti itumọ rẹ jẹ goolu iyebiye oloriṣiiriṣii awọ.

Ṣugbọn oun fun ra rẹ yiorukọ naa pada si Opral nigba ti o n dagba.

Benson bẹrẹ ileewe nile iwe alakọbẹrẹ AME to wa ni Arthington ni Liberia ko to lọ si ileewe Arthington Central School ati College of West Africa fun ikleewe girama.

Benson bi ọmọ akọbi rẹ nigba to wa nile iwe girama fun ọkan lara awọn olukọ rẹ, John Bilson nigba naa.

Lẹyin to bimọ tan ni wọn fun un ni eto ẹkọ ọfẹ eyi to mu lọ kawe sii nile ẹkọ Morris Brown College.

Benson ṣiṣẹ gẹgẹ bi oludari eto nipa ọrọ awọn akẹkọọ ni ileewe giga fasiti ilu Eko, UNILAG lọdun 1973 ti Oba Eko fi joye kan naa.

Wọn tun yan an sipo gẹgẹ bi ọkan lara ọmọ igbimọ ajọ agunbanirọ, National Youth Service Corps.

O tun wa ninu igbimọ Nigerian Olympic Committee lọdun 1982.