Ìtàn Mánigbàgbé: Samuel Taiwo Oredein, àgbà òṣèlú tó fi ẹ̀wọ̀n jura lárúgbó ara

Aye n yi, a n tọọ lẹyin, aye ko tọ lọ bii orere, igba ko tọ lọ bii ọpa ibọn, bẹẹ si ni arugbo ti soge ri, akisa si ti lo igba ri.

Baba oloselu kan wa, to gbajumọ lorilẹ-ede Naijiria, oun si la ba maa pe ni afọbajẹ, oun gan ni baba isalẹ oselu.

Bi o ṣe jẹ ọga patapata nidi ọrọ oselu Naijiria, bẹẹ lo tun jẹ ọwọ ọtun Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ nigba naa.

Orukọ agba oloselu naa ni Samuel Taiwo Ọrẹdẹin, o si wa lara awọn eekan oloselu to da ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ, Action Group silẹ pẹlu Awolọwọ, ẹgbẹ yii si lo fa olootu ijọba akọkọ silẹ lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria lọdun 1955.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn sawawu baba naa ti wọn jọ jẹ eegun sonso tii pari ike lagbo oselu ninu ẹgbẹ ọlọpẹ nigba naa ni Abiọdun Akerele, Ade Akinsanya, J.O Adigun, S.O Shonibarẹ, Ayọ Akinsanya ati Ọlatunji Dosunmu.

Bi o tilẹ jẹ pe Ọrẹdẹin ko du ipo oselu kankan nigba naa sibẹ, o lagbara ju awọn to wa nipo asẹ lọ.

Ohun to ba si sọ ni abẹ ge nigba naa nitori oun ni akọwe aato ẹgbẹ Ọlọpẹ, to si ni asẹ lati ni ki awọn to wa nipo asẹ wa kawọ pọnyin ro ẹjọ, ti ohun ti wọn se ko ba dara.

Amọ isẹlẹ kan waye lọdun 1971 eyi to milẹ titi, eyi to sọ ile ọla Ọrẹdẹin di ahoro.

Iṣẹlẹ ọhun mu ki ọlọla ati ẹni ẹyẹ di ẹni abuku, o si yẹ kawọn ọdọ ati ewe iwoyi, to fi mọ awọn eeyan to n lo igba lọwọ lagbo oselu wa fi kọgbọn.

Itan igbe aye Samuel Taiwo Oredein:

  • Gẹgẹ baa ti ka loju opo itakun agbaye, ọjọ nla ni ọjọ Kẹtala, osu Kẹrin, ọdun 1971 nigba ti isẹlẹ idigunjale alagbara kan waye lopopona Bacita nipinlẹ Kwara nigba tawọn agbebọn kọlu ọkọ banki Barclays, to ti di Union Bank bayii, eyi to gbe owo rin
  • Ọlọpa meji ati osisẹ banki meji ni wọn wa ninu ọkọ tawọn ole yii kọlu, ti wọn si ṣa wọn lọgbẹ yannayanna. Eyi to mu ẹmi ọkan lọ laarin wọn.
  • Awọn adigunjale naa gbe apoti owo nla kan ninu ọkọ banki yii, eyi to kun fun ẹgbẹrun mẹtala pọun, owo nla si ni laye igba naa, Awolọwọ si ni minisita feto isuna laye igba naa
  • Ọga agba fawọn ọlọpaa nigba ta n wi yii, Kam Salem Kiamssa paṣẹ pe ki wọn se awari awọn adigunjale to huwa laabi yii, ko si pẹ, ko jinna, lọwọ tẹ asaaju ikọ apamọlẹkunjaye ọhun, Felix Dumeh, ti gbogbo eeyan ilẹ Naijiria si n yọ pe akara tu sepo
  • Nigba ti Felix de ahamọ awọn ọlọpaa, se lo n ka boroboro pe ki wọn se oun jẹjẹ nitori pe oun nikan kọ lo gbimọpọ ja ole naa, O ni awọn ni baba nigbẹjọ, ti wọn jẹ baba isalẹ fun oun, iromi oun to si n jo loke odo, onilu rẹ wa nisalẹ odo.
  • Felix Dumeh bẹrẹ si ka orukọ awọn eeyan jankajankan, awọn eekan ilu tawọn eeyan n ka orukọ wọn lawọn oju ewe iwe iroyin lojoojumọ, ọga agba kan lẹka ileesẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ nipa iwa ọdaran CID, to wa nilu Ibadan, Patrick Njovens si lo kọkọ darukọ gẹgẹ bii baba isalẹ fun ikọ adigunjale oun
  • Lẹyin eyi lo wa n ka orukọ awọn igi lẹyin ọgba rẹ yoku, to si tun darukọ igbakeji ọga agba lẹka ileesẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ CID yii kan naa, Yesufu Bello nigba ti baba isalẹ rẹ kẹta jẹ Ọga agba ọlọpa miran nilu Ibadan, Amusa Abidogun
  • Gbogbo orukọ ti ogbontagi adigunjale yii n da lo n se awọn ọlọpaa atọpinpin ni haa-hii, amọ ko pẹ lo tun darukọ Oloye Taiwo Ọrẹdẹin pe oun naa wa lara awọn igi lẹyin ọgba fun oun
  • Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Kwara nigba naa, Sunday Adewusi bẹrẹ si finmufinlẹ nipa awọn eeyan ti Felix ka orukọ wọn yii, to si gbe olori tọọgi oloselu kan nilu Ibadan to n sisẹ fun Ọrẹdẹin, ẹni ti wọn n pe orukọ rẹ ni Mustapha Adigun, ti gbogbo eeyan mọ si Balewa abi Tafa Igiripa
  • Balewa yii si lo jẹwọ pe nirọlẹ ọjọ ti wọn digunjale lọna Bacita naa ni oun tẹle ọga oun, Ọrẹdẹin, lọ sile Felix Dumeh, tawọn ọga ọlọpaa ti wọn n se iwadii wọn naa si wa pẹlu Dumeh lasiko yii
  • Balewa ni Felix gbe ọti ogogoro kan ati ataare jade eyi ti wọn mu lati fi mulẹ pe ohun tawọn se ko ni hun awọn, o ni lẹyin eyi lo gbe apo owo kan jade, ti Ọrẹdẹin kọkọ gba lọwọ oun ki Amusa Abidogun to ja a gba mọ lọwọ, to si gbee fun ọga rẹ lẹnu isẹ ọlọpaa, Njovens, igba to si si apo iwe naa, ni Balewa ss pe oun foju kan owo kọrẹnsi to pọ pupọ
  • O ni Njovens beere pe eelo ni owo naa lọwọ Felix, ti onitọun si dahun pe marun amọ ti ọga ọlọpaa naa mi ori rẹ pe sebi adehun meje lawọn dijọ sọ, amọ Felix ni awọn eeyan pọ lori owo naa, ko ba oun gbaa bẹẹ, ti ọga ọlọpaa naa si ni akọsapo ni a kọ owo, to si gbaa
  • Ni kete ti Adewusi gbọ awọn ọrọ ẹri yii lo si pasẹ pe ki wọn gbe awọn ọga ọlọpaa kan lọ silu Ibadan lati finmu-finlẹ nipa isẹlẹ naa, ki wọn si mu abọ wa fun oun, amọ fun iyalẹnu rẹ, se ni awọn eeyan ti wọn lọ finmu-finlẹ naa bọ si ahamọ awọn eeyan mẹtẹẹta ti wọn lọ se iwadii wọn
  • Lẹyin o rẹyin, wọn tu awọn ọlọpaa Adewusi to wa lahamọ nilu Ibadan silẹ, ti wọn si fewe ọmọ mọ wọn leti pe wọn ko gbọdọ wa silu Ibadan mọ amọ eyi bi Adewusi ninu pupọ, ti oun gangan si wa silu Ibadan funra rẹ, o gbe awọn ọga ọlọpaa mẹtẹẹta naa lọ silu Ilọrin, to si tun kesi Ọrẹdẹin pe oun fẹ fi ọrọ wa lẹnu wo
  • Ẹnu ya Ọrẹdẹin lati foju kan Balewa, Adigun ati Felix ni ahamọ awọn ọlọpaa nilu Ilọrin, ti Adewusi si pasẹ fun wọn pe gbogbo ọrọ ti wọn jẹwọ lẹyin Ọrẹdẹin, ni ki wọn sọ loju rẹ, ti awọn onitọhun naa si se bẹẹ, ni jẹbẹtẹ ba gbe ọmọ le agba oselu naa lọwọ
  • Ariwo sọ, ilu mi titi lori iroyin naa, ti ọpọ si n beere pe ki lo lee sun eeyan nla bayii de idi iwa idigunjale, a se ẹni taa gboju okun le, ko jọ ẹni agba
  • Paapa nigba to jẹ pe Ọrẹdẹin kii ṣe akusẹ, o lowo, o lọla, o ni ọpọ ile, ọkọ ayọkẹlẹ ati dukia loniran nran
  • Lasiko igbẹjọ rẹ nile ẹjọ fun ẹsun ṣiṣe onigbọwọ ati gbigba ere idigunjale, Ọrẹdẹin ati awọn ọga ọlọpaa mẹta yoku kawọ pọnyin rojọ, to si sẹ kanlẹ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun tori ilu abinibi oun, Ogere ni oun wa lọjọ ti isẹlẹ idigunjale naa waye, to si tun sẹ lori awọn ẹsun ti Felix fi kan an
  • Adajọ Moradeyọ Adesiyun lo gbọ ẹjọ naa, ti Oloye Rotimi Williams si jẹ agbẹjọro fun Ọrẹdẹin ati Patrick Njovens, Richard Akinjide si lo duro bii agbẹjọro fun Bello ati Abidogun. Anthony Ẹkundayọ si ni oludari fun ikọ agbefọba
  • Lọjọ Isẹgun, ọjọ Kejidinlogun, osu Kejila, ọdun 1971 ti wọn da ẹjọ naa, gọngọ sọ. Adajọ ni lootọ lawọn afurasi naa ko si nibi isẹlẹ idigunjale gẹgẹ bi awọn ti salaye ayafi Felix nikan, amọ o ni wọn mọ saaju pe isẹlẹ naa yoo waye
  • Ati pe awọn to jẹ ọlọpaa laarin wọn ko si ṣe ohunkohun lati dena rẹ, bẹẹ ni wọn tun pin ninu ere to wa lati idi isẹlẹ idigunjale ọhun
  • Ẹkun iwọ oorun Naijiria nikan lo ni, Kwara kii si Ṣe ara wọn. Eyi si lo mu kawọn afurasi shun gba ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa lọ
  • Amọ pabo ni ẹjọ wọn ja si lọhun tori ile ẹjọ to ga julọ naa fidi idajọ ile ẹjọ akọkọ mulẹ, to si ni ẹwọn gbere ni ki wọn fi awọn ọdaran naa si, ti ewe nla Ọrẹdẹin ati awọn ọga ọlọpa miran si pada wa ru wẹwẹ.

Ẹkọ ti itan igbe aye Ọrẹdẹin kọ wa:

  • Ẹkọ akọkọ ni pe ka maa jẹ ki ohun ti a ni tẹ wa lọrun, a ko gbọdọ ru ẹran erin sori, ka tun maa fi ẹsẹ wa irẹ
  • Itan yii tun kọ wa lati sọra se nitori ilẹ n yọ, bi aye ba n yẹ wa loni, ka maa huwa ibajẹ
  • A tun ri kọ pe ipokipo taa ba wa, paapa awọn ọlspa, ka maa sọra, tori asegbe kankan ko si, asepamọ lo wa
  • A tun ri kọ pe ko si ẹni ti Ọlọrun ọba ko lee mu afi eyi ti ko ba setan lati mu.

Ẹ jẹ ka fi itan igbe aye Samuel Taiwo Ọrẹdẹin kọgbọn, ka maa sọra se.