You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Twin Festival 2019: Ṣé ọbẹ ìlasa àti àmàlà ló ń ṣokùnfà bíbí ìbejì ní ìlú Igboọrà?
Igboọra jẹ ilu kan to kalẹ si agbegbe Ibarapa nipinlẹ Ọyọ, ti igbagbọ si wa pe ko si ile kan ninu ilu naa ti wọn ko ti bi ibeji, ibẹta tabi ibẹrin nibẹ.
Koda, awọn ọmọbibi ilu ati awọn ajeji to ba n gbe ninu ilu, to n jẹ ounjẹ wọn, to si n mu omi wọn, ni okun ibeji abi ibẹta wa ninu rẹ.
Ọdọọdun si ni wọn maa n se ọdun ibeji nilu naa, eyi to tun ko lọdun yii, ti ko si sẹyin ikọ iroyin BBC Yoruba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọkan lara awọn ọba alaye ilu Igboọra, Ọba Adedamọla Badmus, tii se Olu-Aso ti Ibẹrẹkodo sọ fun ikọ BBC Yoruba pe, igbagbọ wa pe ọbẹ ilasa ati amala dudu lo n sokunfa okun ibi pupọ nilu ọhun.
Gẹgẹ bi ọba Badmus ti wi, o ti to aadọta ọdun sẹyin ti ilu Igboọra ti gbajumọ nipa bibi ibeji abi ibẹta, ohun to si tun jẹ pataki ni pe, wọn kii fi ibeji tọrọ owo nilu Igboọra.
Bakan naa ni BBC Yoruba, lasiko ọdun ibeji tọdun yii nilu Igboọra, tun ka bi ayẹyẹ manigbagbe naa se lọ, o ya, ẹ fun oju lounjẹ ninu fidio alarinrin yii.