How to get your National Identification Number: Àwọn ọ̀nà tí o le gbà rí fọ́ọ̀mù ìforúkọsílẹ̀ fún NIN rẹ gbà àti àwọn ibùdó ìforúkọsílẹ̀ lágbáyé nìyí

Ọrọ iforukọsilẹ fun nọmba idanimọ apapọ orilẹede Naijiria ti fi ọpọlọpọ sinu hilahilo, pẹlu bi ijsba apaps ti ṣe kede pe awọn nọmba ibanisọrọ ti ko ba ni asopọ pẹlu nọmba idanimọ ẹni to nii yoo di titi pa.

Hilahilo lori ọgọrọ ero to n wọ lu ileeṣẹ ajọ iforukọsilẹ kaadi idanimọ lorilẹede Naijiria, NIMC ti mu ki ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria to wa loke okun ti ko tii gba nọmba naa o maa ko aya soke.

Amọṣa o, ajọ NIMC ti fi wọn lọkan balẹ pe ko si ewu ati pe awọn ti ṣeto awọn ibudo iforukọsilẹ kan loke okun ti wọn ti lee lọ gba nọmba idanimọ apaps ilẹẹwa , NIN tiwọn lẹyin ti wọn ba forukọsilẹ.

Ọjọ kọkandinlogun oṣu kinni ọdun 2021 ni ijọba apapọ Naijiria ti sun gbedeke ṣiṣeto asopọ nọmba idanimọ apapọ ilẹ Naijiria, NIN ati nọmab ibanisọrọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria kọọkan mọ si bayii.

Amọṣa, fun awọn ti ko ba tii fi orukọ silẹ rara, gbedeke ọjọ kẹsan oṣu keji ọdun 2021 ni wọn fun wọn.

Eyi ni ibi ti awọn ibudo iforukọsilẹ fun NIN wa kaakiri orilẹede agbaye.

Bakan naa, ileeẹ ibaraẹnisọrọ ni ijọba apapọ pẹlu ti gbe ilana bi o ṣe lee yanju fọọmu iforukọsilẹ fun kaadi idanimọ apapọ naa lati gba nọmab idanimọ NIN rẹ.

Loju opo ẹyẹnkọrin Twitter wọn ni wọn ti kọ ọ si pe ẹnikẹni to ba nilo fọọmu naa lee daa latori ikanni wọn.

Loju opo twitter yii ni ẹ ti lee ri fọọmu naa gba:

https://twitter.com/nimc_ng/status/1340677445435973633

Bayii ni fọọmu naa ṣe ri.

Wo àwọn nǹkan to tún nílò NIN fún yàtọ̀ fún ìforúkọsílẹ̀ síìmù

Laipẹ yii ni ajọ to n risi ibaraẹnisọrọ ni Naijiria, NCC fi aṣẹ sita pe, gbogbo ọmọ Naijiria to n lo siimu ẹrọ ibaraẹnisọrọ, gbọdọ fi NIN kun iforukọsilẹ siimu wọn.

Gbedeke ọsẹ meji pere si ni ajọ naa fi silẹ lati sẹ bẹ ẹ.

Amọ yatọ si iforukọsilẹ siimu, awọn nnkan mii wa ti o tun nilo NIN rẹ fun gẹgẹ bii ọmọ Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Apo asunwọn banki: Awọn banki ni Naijiria ma n gba NIN gẹgẹ bi ami idanimọ, ki wọn o to le ṣi apo asunwọn pẹlu wọn, tabi bẹrẹ si ni lo asunwọn ti o ko lo fun igba pipẹ pada.

Iforukọsilẹ fun iwe irinna: Ajọ to n risi iwọle-wọde ni Naijiria ti sọ ọ di dandan fun ẹnikẹni to ba fẹ ẹ gba iwe irinna pasipọọti tuntun, tabi tun ti akọkọ ṣe, gbọdọ ṣe afihan NIN rẹ ko to o di ṣisẹ.

Iwe aṣẹ fun ọkọ wiwa: Ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC, naa ti n beere fun NIN lọwọ ẹnikẹni to ba fẹ ẹ gba laisẹnsi gẹgẹ bi awakọ. Laisi NIN, o ko ni le gba iwe aṣẹ fun ọkọ wiwa.

Ọna to le gba lati ri nọmba idanimọ NIN rẹ gba?Ninu alaye ti ajọ to n ṣakoso eto idanimọ ni Naijiria, NIMC ṣe, wọn ni ki awọn ọmọ Naijiria ṣa ti tẹ nọmba *346# lori foonu wọn lati ri nọmba yii.Gbogbo atotonu to n waye lori nọmba yi ko sẹyin bi ajọ NCC ṣe gbe gbendeke ọlọsẹ meji kale

O ti di dandan bayii ki gbogbo awọn to n lo foonu Alagbeka o pese nọmba yi bi won ko ba fẹ ki wọn wọgile opo ibaraẹnisọrọ wọn.Gbogbo ẹni to ba n lo opo MTN, Airtel, 9mobile ati Glo lo le lo nọmba yiNCC salaye pe o di dandan ki gbogbo ẹni to ba ni siimu lati je ki iroyin wọn pe perepere.

Fun awọn ẹlẹrọ Alagbeka ti ko ba ti forukọsilẹ tẹlẹ ilana ti wọn le tele ree:

1) Igbesẹ akọkọ:Ko iroyin nipa re sí inú fọọmu NIMC loju opo wọn tii ṣe: https://penrol.nimc.gov.ng/loginForm.tpl.html.phpRi i pe ohun to ba yẹ lọ kọ sí gbogbo aaye ti wọn lò ṣe pataki to wa ninu fọọmu naa.Ṣe ẹda fọọmu naa ko si tẹ iwe pelebe to jẹri sí pe o kan sí ojú òpó naa.

2) Igbesẹ Kejì:

Fi iwe ti o ti fi forukọ silẹ si ṣọwọ si wọn.

Kàn sí ilé iforukọsilẹ NIMC to sunmọ ọ pẹlu ojulowo iwe idanimo to ba yẹ

Bi o ba ti debẹ kan si kanta oṣiṣẹ wọn ti yoo ṣe ayẹwo gbogbo ìwé tó kọ lọwọ

Ti gbogbo nkan rẹ bá pé daada oṣiṣẹ yi yoo gba oju ika rẹ mẹwẹwaa silẹ to fi mọ àwòrán oju rẹ. Lẹyìn naa lo wa lọ gba iwe ẹri pe o ti kọja ìpele yi.

3) Igbesẹ 3Gba nọmba NIN rẹ

Bi ọjọ meji sí mẹta ni wọn yóò lo ki o to le gba iwe ẹri nọmba yi lẹyin ti wọn gba oju ika rẹ àti àwòrán oju rẹ silẹ

O ṣeeṣe ki o pe ki o to ri nọmba yi gba nigba miran nitori NIMC yoo ni lati ṣe ayẹwo to peye.

O ni lati fi iwe ẹri yi pamọ daada ki o ba le fi han asiko to ba fẹ gba iwe ẹri nọmba NIN rẹ

Bi o ti ṣe lè mọ ti kaadi Nimc rẹ bá ti ṣetán fún gbígba?

Kan sí oju opo ajọ National Identity Management Commission [NIMC] tii ṣe www.nimc.gov.ng

Sun si oju ikansiraeni ìkíni káàbọ̀ ki o si tẹ ami afihan 'e-ID Card Status Portal' lati mọ ti kaadi rẹ ba ti wa nilẹ fún gbígba.

Lẹyìn náà kọ orukọ rẹ ti baba rẹ ki o si wo boya kaadi rẹ ti wa nilẹ fun gbigba.