Lagos-Ibadan Expressway: Ọ̀pá afẹ́fẹ́ gáàsì bẹ́ lópópónà márosẹ̀ Ibadan sí Eko

Iroyin ti jade bayii wipe ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA ti ri ọpa afẹfẹ gaasi to bẹ ni tosii ile iṣẹ iroyin Punch lagbegbe Magboro to wa ni opopona Eko si Ibadan.

A gbọ pe bi ọpa afẹfẹ gaasi naa ṣe bẹ wa latọwọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Julius Berger to n ṣiṣẹ ni opopona naa.

Gẹgẹ bi oludari agba ajọ LASEMA ṣe fi sita, nibayii, wọn ti di ọpa naa wọn si ti dena igbokegbodo ọkọ lagbegbe naa torii iṣẹ to n lọ lọwọ nibẹ.

Ṣaaju ni iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii n fiye ni pe ọpa afẹfẹ idana gaasi kan ti bẹ lagbegbe Magboro, nitosi ileeṣẹ iwe iroyin Punch lopopona marosẹ Eko si Ibadan.

Ajọ ẹsọ oju popo lagbegbe naa ni awọn oṣẹ ileeṣẹ aṣọna Julius Berger ni wọn bẹ ọpa gaasi naa lasiko ti wọn fi n wa ilẹ lagbegbe naa fun ibudo iṣẹ wọn.

Bi a ṣe n sọrọ yii lilọ bibọ ọkọ lagbegbe na ti wa ni iduro.

Ọga agba ajọ ẹṣọ oju popo loju ọna naa wa ke sawọn ọlọkọ lati maṣe jaya nitori pe wọn ti kan san akọṣẹmọṣẹ to mọ nipa rẹ lati gbe igbesẹ ti ko ni fi jasi ijamba nla miran ti yoo la ẹmi lọ.

Akọroyin BBC News kan to ti de ibẹ ṣalaye pe iye afẹfẹ gaasi to n fẹ jade nibẹ pọ pupọ, bi awọn alaṣẹ ko ba si gbe igbesẹ to ba tọ ni kiakia, afaimọ ki ijamba nla o maa waye nibẹ.