Ẹ gbájúmọ́ ètò ààbò ilẹ̀ Yorùbá dípò jíjà sí ipò - Sunday Igboho sáwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajúmọ̀ tó ń pè fún ìdásílẹ̀ Yorùbá nation, Sunday Adeyemo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sunday Igboho ti rọ àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá láti fi ìmọ̀ ṣọ̀kan lójúnà àti gbógunti àìsí ààbò tó ń bá ẹkùn náà fínra.

Igboho ní àwọn ọba nílò láti gbé ìfaǹfà tó bá ń wáyé láàárín ara wọn tì, kí wọ́n fowọ́sowọ́pọ̀ lójúnà àti mú ìdàgbàsókè bá ilẹ̀ Yorùbá.

Igboho nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun sọ pé kìí ṣe ohun ìwúrí rárá pé àwọn ọba lọ́balọ́ba ilẹ̀ Yorùbá tí ipò wọn ṣe pàtàkì sí ìtàn ilẹ̀ Yorùbá ń ba ara wọn fa onírúurú awuyewuye.

Ó sọ èyí látàrí ìfaǹfà tó wáyé láàárín Olubadan ilẹ̀ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja àti Alaafin ìlú Oyo, Ọba Akeem Owoade lórí ipò alága àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ Oyo.

Igboho wòye pé àwọn lọ́balọ́ba ilẹ̀ Yorùbá ní àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì ju bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n nílò láti kojú bíi àwọn agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí tí wọ́n ti fi àwọn igbó ẹkùn gúúsù ìwọ̀-oòrùn tó jẹ́ ilẹ̀ Yorùbá ṣe ibùgbé.

Ó wá rọ àwọn ọba náà láti ṣe ara wọn ní irinṣẹ́ ìṣọ̀kan àti ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé, kí wọ́n ṣiṣẹ́ pọ̀ láti dá ààbò bo àwọn èèyàn wọn lọ́wọ́ ìkọlù àwọn agbébọn dípò jíjàsí ipò.

Bákan náà ló tún pè fún ìdásí àwọn olórí ilẹ̀ Yorùbá míì bíi Ooni Ile Ife, Oba Enitan Adeyeye Ogunwusi, àti Olugbon ti Orile Igbon, Oba Francis Olushola Alao láti dá ọ̀rọ̀ ipò alága àwọn lọ́balọ́ba tó ń fa awuyewuye náà.

"Kí ló dé táwọn ọba wa ń gbájúmọ́ ọ̀rọ̀ ipò nígbà táwọn agbébọn, agbéṣùmọ̀mí àtàwọn ọ̀daràn míì ti gba gbogbo igbó tó wà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn tí a bá wo ìpànìyàn tó wáyé nínú igbó Old Oyo National Park àti apá ibìkan ní ìpínlẹ̀ Oyo.

"Àwọn lọ́balọ́ba ilẹ̀ Yorùbá láì fi ipò ṣe nílò mú ààbò àwọn ẹkùn ilẹ̀ Yorùbá ní òkúnkúndùn tako gbogbo àwọn tó ń da ilẹ̀ Yorùbá láàmú."

Bákan náà ló ní wíwá ní ìṣọ̀kan àwọn ọba alayé náà ni yóò mú ìdàgbàsókè bá ilẹ̀ Yorùbá.

"Kìí ṣe ohun tó tọ́ láti máa jà sípò nígbà tí àwọn aráàlú pàápàá àwọn àgbẹ̀ tó wà láwọn ìlú kéréje ń kojú ìpànìyàn ní gbogbo ìgbà."