Kí ni pàtàkì kíkó lọ sí ààfin tí Aláàfin Owoade ṣẹ̀ṣẹ̀ kó lọ?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aláàfin ìlú Oyo, Ọba Akeem Abimbola Owoade ti kó sí ààfin ìlú náà tó wà ní agbègbè Oke Afin ìlú Oyo.

Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn-án tí Aláàfin gorí àpèrè àwọn babańlá rẹ̀ nínú oṣù Kẹrin, ọdún 2025.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ààfin, Bode Durojaiye sọ pé láti ìgbà tí Aláàfin àná Ọba Lamidi Adeyemi ti gbésẹ̀ ni ààfin náà ti nílò àtúnṣe, tó sì jẹ́ pé gbogbo àwọn nǹkan tó wà nínú ààfin náà ni wọ́n ti jí kó tán.

Ó ní èyí ló mú kí Ọba Owoade, bí ó ṣe gorí ìtẹ́ àwọn bàbá rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti ṣàtúnṣe ààfin náà.

Ó ṣàlàyé pé olùrànlọ́wọ́ pàtàkì sí Aláàfin, Kolade Oladele ló ṣe àkóso ètò àtúnṣe ààfin ọ̀hún.

Ó fi kun pé ààfin náà ti wu ojú rí, tí wọ́n sì dùn-ún wò èyí tó ṣàfihàn àwọn iṣẹ́ ọnà ìlú Oyo àti ilẹ̀ Yorùbá lápapọ̀.

Ó ní gbogbo àwọn ibùgbé tó wà ní ààfin náà tó igba tó sì jẹ́ pé gbogbo wọn ló ní àgbàlá tó ju ẹyọ kọ̀ọ̀kan lọ.

Àtẹ̀jáde náà fi kun pé kò sí bí èèyàn ṣe máa ṣàbẹ̀wò sí ààfin náà tí kò ní ri pé àgbàlá àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Yorùbá ni òun wà.

"Ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ ọnà, tó fi mọ́ àwọn ère, àwọn ilé tí wọ́n fi igi gbẹ́ àti ilẹ̀kùn tó ṣàfihàn ọlá àti ọrọ̀ ilẹ̀ Yorùbá ló ti wà ní ààfin.

"Àwọn àwòrán àwọn kìnìún àti àwọn ọdẹ ni wọ́n fi àwo ṣe, tí wọ́n sì kun gbogbo àwọn ògiri rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àwọ̀ alárànbarà, tó fi mọ́ àwọn igbá àtàwọn ohun mèremère míì."

Ipa kíkó wọ ààfin sáwọn aráàlú ìlú Oyo

Durojaiye tẹ̀síwájú pé gbogbo àwọn aráàlú tó fi mọ́ àgbà àti ọmọdé ni wọ́n tú jáde láti kí Aláàfin nígbà tó ń wọ ààfin náà.

Kíkówọ ààfin náà jẹ́ àmì kan gbòógì lórí àṣà àti ìṣe ìlú Oyo àti àmì kan pàtàkì sí ìpadàbọ̀ ọba náà sí ilé ìṣura àṣà ilẹ̀ Yorùbá èyí tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ ọ̀kan gbòógì ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Africa.

"Àwọn aráàlú tó fi mọ́ àgbà àti ọmọdé ni wọ́n fẹ́ràn Aláàfin, tí wọ́n sì mọ rírì fún ìfarajìn rẹ̀ ìdàgbàsókè, àlááfíà, ìṣọ̀kan tó ń mú bá ìlú Oyo àti ilẹ̀ Yorùbá lápapọ̀."

Àwọn aráàlú gbàgbọ́ pé kíkó ló sí ààfin náà kìí ṣe ọ̀rọ̀ lílọ máa gbé ní ààfin nìkan bíkòṣe ìpadàbọ̀ ìtàn, àṣà àti ohun ìdánimọ̀ àwọn èèyàn Yorùbá.

Wọ́n ní ààfin yìí ni ọkàn ìdàgbàsókè ilẹ̀ Yorùbá àti pé rírí Aláàfin padà síbẹ̀ jẹ́ ohun ìwúrí fáwọn èèyàn.

Wọ́n fi kun pé pípadà sí ààfin náà jẹ́ ìfarajìn sí dídá ààbò bo àṣà, ìtàn àti ṣiṣé ìgbélárugẹ ọ̀kan lára àwọn ọba tó tóbi nílẹ̀ Africa.