Kí ló fa gbas-gbos láàárín Wizkid àti Seun Kuti?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ayodeji Ibrahim Balogun, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Wizkid tabi Wizzy ti sọ oko ọrọ si Seun Kuti, to jẹ ọmọ agba olorin Afrobeat ati ajafẹtọọmọniyan ṣaaju iku rẹ, Fela Anikulapo Kuti.

Ọrọ yii lo n waye lẹyin gbas-gbos to wa nilẹ fun ọjọ diẹ laarin awọn olofẹ Wizkid ati Seun Kuti.

Ariyanjiyan lori ẹni ti irawọ rẹ ta lẹnu julọ lo da ọrọ naa silẹ ki Seun to sọrọ ti Wizzy si fun un lesi pada.

Bi gbas-gbos naa ṣe bẹrẹ

Ọrọ naa bẹrẹ lẹyin ti Seun kilọ fun awọn ololufẹ Wizkid pe ki wọn dẹkun ati maa fi baba oun we Wizkid nitori awọn mejeji ko si ninu ẹgbẹ kan naa.

Seun sọ pe ogbontarigi ajafẹtọọmọniyan ni baba oun yatọ si pe o jẹ olorin to gbe odidi awo mejileelaadọta jade, nitori naa, o yẹ ki awọn eeyan bu ọla tirẹ fun.

O ni arifin ni ki awọn ọmọ aye ode oni maa fi baba oun we Wizkid.

Lẹyin naa ni awọn ololufẹ Afrobeat kan bẹrẹ si n ṣe fidio ti wọn si n fi ohun ranṣẹ si awọn obi Wizkid ki oun naa to tun sọrọ soke.

Agbaya ni ọ, mo ju Fela lọ - Wizkid fi eebu ṣọwọ si Seun Kuti

Ninu idahun rẹ, Wizkid fi ọrọ rabiti pẹlu awọn eebu ṣọwọ si Seun loju opo Instagram rẹ.

Ninu fidio ti Wizzy kọkọ fi lede loju opo naa ni obinrin kan ti n bu Seun to si n pe e ni "ọmọ baba onipata gigan."

Obinrin naa ke si awọn mọlẹbi Seun ki wọn tete mu u so lati dẹkun ohun to n ṣe lori ayelujara latari pe o n tabuku orukọ baba rẹ.

O fẹsun kan Seun pe o n ṣe epe fun awọn ọmọ ọlọmọ, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, pata ati igbo mimu nikan ni Seun jogun lọwọ Fela.

O sọ siwaju si pe Wizkid fẹran Fela lo mu ko ya awọran tatuu Fela si ara rẹ, eyii to yẹ ko mu inu Seun dun.

Lẹyin fidio naa ni Wizkid tun sọ pe oun ati Fela kii ṣe ẹgbẹ, to si tun pe Seun ni oponu ati ọmọ ale.

Ọrọ naa ti da ariyanjiyan silẹ laarin awọn ololufẹ orin Afrobeat ati awọn mejeji.

Bi awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹ lu Wizkid pe ọrọ to sọ ko bojumu, lawọn mii n segbe lẹyin rẹ pe ohun to yẹ Seun ni Wizkid ṣe fun.

Wayi o, Seun ko tun tii fesi mii lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.