You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé lóòótọ́ ni agbébọn jí èèyàn 177 lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì ní Kaduna?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ti sọ pe irọ ni iroyin to n lọ ni igboro pe awọn ajinigbe ji eeyan to le ni ọgọrun gbe lọ nini ile ijọsin kan niluu Kajuru.
Ọrọ naa lo jẹyọ lasiko ti kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa, Muhammad Rabiu, n ba awọn akọroyin sọrọ.
O ni awọn kọlọrọsi ẹda kan lo n gbe iroyin naa kiri lati mọọmọ da ipaya si ọkan awọn eeyan ipinlẹ naa.
Kọmiṣọna ọhun tun fi akoko naa kilọ fun awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri ki wọn ṣọ ara wọn, bi bẹẹ kọ, wọn yoo foju wina ofin.
Nibi ipade naa ni alaga ijọba ibilẹ Kajuru, Dauda Madaki, ti fi kun irọ ni iroyin naa pe ko si ohun to jọ ijinigbe lagbegbe ọhun rara.
O ni "A ṣabẹwo si ṣọọṣi ti wọn ni wọn ti ji awọn eeyan gbe ṣugbọn a ko ri apẹrẹ nnkankan to jọ bẹẹ rara.
"Mo bere lọwọ olori ilu naa, Mai Dan Zaria, nipa iṣẹlẹ ọhun, oun naa sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ.
"Mo tun ke pe olori ọdọ agbegbe naa, Bernard Bona, oun naa to ba awọn akọroyin sọrọ sọ pe irọ ni."
Lẹyin naa lo sọ pe ki ẹnikẹni to ba ni ẹri pe wọn ji awọn eeyan gbe lọ nibẹ mu eri wa, ki wọn si fi orukọ gbogbo awọn ti ọrọ naa kan ṣọwo si ijọba.
Ṣaaju ni ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ipinlẹ ọhun ti kọkọ sọ ninu atẹjade kan pe wọn ji olujọsin to le ni ọgọrun gbe lọ nibẹ.
Ọkan lara awọn olori ilu naa tun sọ fun BBC pe asiko ti isin n lọ lọwọ ni awọn agbesunmọmi ya bo ile ijọsin kan nibẹ ti wọn si ji eeyan 177 gbe lọ, amọ awọn mọkanla moribọ ninu wọn.
Èèyàn 160 ni agbébọn gbé ní ṣọ́ọ̀ṣì – CAN
Gẹgẹ bi ajọ Christian Association Of Nigeria (CAN), ẹka Kaduna ṣe ṣalaye iṣẹlẹ naa, wọn ni awọn ṣọọṣi naa wa ni abule Kurmin Wali, nijọba ibilẹ Kajuru, ipinlẹ Kaduna.
CAN Kaduna sọ pe lasiko ti awọn eeyan n jọsin lọwọ ni awọn ajinigbe ọhun ya de ti wọn si n gbe wọn jade wọgbo lọ.
Akọwe apapọ fun ẹgbẹ CAN ni Kaduna, Ẹni ọwọ Joseph John Hayab, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ fun ẹka AFP lọjọ Aje, sọ pe:
"Bo tilẹ jẹ pe mi o fẹ sọ pato iye eeyan ti awọn agbebọn naa gbe lọ, ohun ti mo gbọ lati agbegbe naa ni pe o to eeyan mejilelaadọsan-an (172) ti wọn ji gbe lọ.
"Ṣugbọn awọn mẹsan-an ninu wọn ti rọna sa wale, nigba ti eeyan 163 ṣi wa nibẹ ti a n wa."
"Awọn to ṣekọlu naa yade pupọ, wọn si di ẹnu ọna abawọle awọn ṣọọṣi naa, wọn si n fipa gbe awọn olujọsin wọnu igbo lọ."
Ẹni ọwọ Hayab sọ pe ohun yowu to le mu awọn agbebọn naa ji awọn eeyan lọ bi eyi ko ni I mu awọn dẹyin.
"A ko ni i juwọ silẹ, a maa tẹsiwaju lati maa sowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo ati ijọba lati ri i pe a ri awọn eeyan to wa nigbekun naa gba."
Àwọn ṣọọṣi wo ni wọn doju kọ?
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ijinigbe naa waye ni nnkan bii aago mọkanla kọja iṣẹju mẹẹẹdọgbọn, laaarọ ọjọ isinmi, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii.
Abule Kurmin Wali to ti waye yii si jẹ igbo kan ni Kajuru, ipinlẹ Kaduna.
Awọn ile ijọsin ti wọn doju sọ bi a ṣe gbọ ni Evangelical Church Winning All (ECWA), ṣọọṣi Katoliiki kan ati ijọ Kerubu ati Serafu kan.
Nipa awọn to ṣe ikọlu ọhun, agbebọn to dihamọra ogun ni wọn pe wọn.
Awọn nnkan ija igbalode ni wọn si lo.
Iroyin sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa Kaduna ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣugbọn wọn ko ti i fi iye eeyan to wa nigbekun lede lasiko ti a n kọ iroyin yii.
Tẹ o ba gbagbe, ni oṣu Kọkanla ọdun 2025, o le ni ọọdunrun (300) akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe nile ẹkọ Katoliiki St Mary, Papiri, nipinlẹ Niger.
Bẹẹ ni agbebọn ji awọn akẹkọọ gbe ni Kebbi, wọn ṣọṣẹ nipinlẹ Kwara pẹlu, bi wọn ṣe ji awọn eeyan gbe ni wọn pa awọn miran, ki ijọba too kede pe oun ti fi ilana asọye (Non Kinetic) yanju rẹ, ti awọn to wa nigbekun si pada sile wọn.