Ìyá ló gbé bẹtiróòlù sí ṣọ́ọ̀bù ní Kwara tí iná fi jó ọmọ mẹ́ta pa-Iléeṣẹ panápaná

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara ti ṣalaye ohun to fa ina to jo awọn ọmọ mẹta kan pa nile kan lagbegbe Laduba, Ogidi, niluu Ilorin, lọjọ Satide ana ti i ṣe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.

Alukoro ati olori ẹka ikede nileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara, PFO Hassan Hakeem Adekunle, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita, pe nnkan bii yara marun-un, ṣọọbu mẹfa lo wa ninu ile naa.

O ni ṣọọbu mẹta to wa nisalẹ ile yii ni ina ọhun kan. Ati pe ina to ṣẹyọ naa ko ṣẹyin epo bẹtiroolu ti iya kan gbe sinu ṣọọbu tawọn ọmọ sun si.

Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?

Nigba to n ṣalaye bi ina ọhun ṣe ṣẹyọ gan-an, Alukoro ileeṣẹ panapana Kwara sọ pe iwadii fi han pe obinrin kan to ni ọmọ mẹta lo ra epo bẹtiroolu to to lita aadọta (50 litres) to si gbe e pamọ sinu ṣọọbu tawọn ọmọ sun si.

"Niwaju ṣọọbu naa, obinrin miran n dana eedu, bi eedu naa ṣe n kẹ lo ta de ibi ti wọn gbe epo bẹtiroolu pamọ si, eyi to mu ina ṣẹyọ to si pada gbina, to fa ijamba ina naa.

"Ina yii lo gba ẹmi awọn ọmọde mẹta, ti ẹnikan to n kọja lọ to si fẹẹ ran wọn lọwọ naa tun fi ara kona, to balẹ sile iwosan ki panapana too de."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade awọn panapana Kwara naa ṣalaye.

Wọn fi kun un pe olori agbegbe ọhun ni awọn gbe oku awọn ọmọde to di oloogbe naa fun.

Orúkọ àti ọjọ́ orí àwọn ọmọ tíná jó pa

Gẹgẹ bi ileeṣẹ panapana Kwara ṣe darukọ ati ọjọ ori awọn ọmọ naa, ẹni akọkọ ni

Abdulraman Jamiu Jeje, ọmọ ọdun mẹjọ.

Ikeji ni Islamiya Abdulwahab, ọmọ ọdun mẹtadinlogun (17) iya rẹ lo ni ṣọọbu.

Ẹnikẹta si ni Hadizah AbdulAzeez Raji, ọmọ ọdun mẹtadinlogun (17).

Ọga agba nileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara CFS Alabi Muhammed, ba awọn ti iṣẹlẹ naa kan kẹdun, bẹẹ lo ni ijamba to ṣee dena ni.

O kilọ fun araalu lati yee tọju epo sile tabi ohunkohun to ba le gbina, paapaa lawọn ibi ti wọn ba ti n ta ọja, ti ina dida ko si jinna rara.

Bi wọn ba kẹẹfin ẹnikẹni to n tọju epo sinu ile gbigbe, tabi to n huwa to le fa ijamba, olori ileeṣẹ panapana Kwara rọ awọn araalu lati tete fi ẹjọ ẹni bẹẹ sun, lati dena ijamba iru eyi lọjọ iwaju.