You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
NDLEA ti mú Kanmo-Kanmo,afurasí olóògùn olóró tí wọ́n ló pa òṣìṣẹ́ àjọ náà mẹ́ta lọ́dún méjìlá sẹ́yìn
Ajọ to n gbogun ti gbigbe oogun oloro lorilẹede Naijiria, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ti pada mu ọkunrin afurasi kan, Lekan Jimoh ti inagijẹ rẹ n jẹ Kanmo-Kanmo.
Atẹjade ti Femi Babafemi, agbẹnusọ ajọ NDLEA, fi sita lọjọ Aiku oni, ṣalaye pe ogbologboo ni Kanmo-Kanmo ninu oogun oloro gbigbe lọ silẹ ibomiran, ati pe o pa mẹta lara awọn oṣiṣẹ NDLEA lọdun mejila sẹyin.
Agbẹnusọ NDLEA yii sọ pe latigba naa ni awọn ti n wa afurasi yii, kọwọ too ba a lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.
Nipa ibi ti wọn ti ri Lekan Jimoh mu, Babafemi sọ pe ilu Owode, nipinlẹ Ogun ni ọwọ ti ba a, lẹyin iwadii ikọ ọtẹlẹmuyẹ ajọ NDLEA.
Oriṣi oogun oloro ti a mọ si Skunk lo ni awọn ba ni ibuba Kanmo-Kanmo, iwọn rẹ si jẹ mọkandinlaadọrin (69 kilograms)
Bawo ni Kanmo-Kanmo ṣe pa oṣiṣẹ NDLEA mẹta ni 2014?
Gẹgẹ bi agbẹnusọ NDLEA ṣe ṣalaye, o ni lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹfa ọdun 2014, ni Kanmo-Kanmo ko awọn janduku to dihamọra ogun wa lati koju awọn oṣiṣẹ ajọ naa to gbiyanju lati mu un ni ibuba rẹ to farapamọ si.
" Ikọlu naa lo fa iku awọn oṣiṣẹ NDLEA mẹta, lara wọn ni Rabiu Usman Kazaure, pẹlu awọn meji mi-in.
"Awọn tọọgi ti dihamọra ti Jimoh ko wa lo pa wọn, oun si rọna sa lọ lọjọ naa, ṣugbọn ajọ yii pinnu lati ri I mu, nitori idajọ ododo fawọn akọni to sun loju ija.''
Bẹẹ ni agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi, ṣalaye ninu atẹjade naa.
O fi kun un pe latigba naa ni Jimoh ti n sa kiri ti ọwọ ko si ba a, bẹẹ ni ko jawọ ninu gbigbe oogun oloro kiri.
Babafemi sọ pe aṣeyọri nla lo jẹ fun NDLEA bi ọwọ ṣe pada ba Jimoh yii, ti wọn yoo si gbọ ẹsun rẹ labẹ ofin.
O ni ṣaaju ni NDLEA tun ti gbiyanju lati mu Kanmo-Kanmo, iyẹn lọjọ kejila, oṣu Kẹjọ ọdun 2023, nibi to farapamọ si l'Ado-Odo, ipinlẹ Ogun.
Apo oogun oloro skunk mọ́kàndínlógóje (139), ti iwọn rẹ din diẹ lẹgbẹrun meji (1,922 kilograms) lo ni awọn ba nibẹ, ṣugbọn Kanmo-Kanmo tun yọ mọ wọn lọwọ lọjọ naa bo ṣe sọ.
Ile to fi n ko oogun oloro naa si ni ijọba apapọ gbẹsẹ le nigba naa gẹgẹ bi alaye agbẹnusọ NDLEA, gẹgẹ bi ile ẹjọ ṣe paṣẹ.
Ṣugbọn ni bayii, Kanmo-Kanmo funra rẹ ti bọ sọwọ, bi NDLEA ṣe fi lede.