You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilé ẹjọ́ gba béèlí Portable pẹ̀lú mílíọ́nù kan náírà àti onídúró méjì, ohun tó ṣẹlẹ̀ ní kóòtù rèé
Ile-ẹjọ Majisireeti akọkọ to wa niluu Ota, ipinlẹ Ogun ti paṣẹ pe ki wọn gba beeli ilu-mọ-ọn-ka olorin takasufe nni, Habeeb Okikiola tọpọ mọ si Portable.
Portable lo n jẹjọ lori ẹsun mẹsan ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu iwa ọdaran, eyi ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi kan an.
Laipẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi ẹsun kan Portable, lara rẹ ni lilu awọn ọlọpaa ati ole jija.
Ṣaaju ni Okikiola ti sọ fun ile-ẹjọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun, ti ile-ẹjọ si paṣẹ pe ki wọn lọ fi si ọgba ẹwọn Ibara to wa niluu Abeokuta, titi digba ti igbẹjọ miran yoo waye.
Nile-ẹjọ lonii, ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2026, oniduro meji ọtọọtọ ni ọlọpaa pe lati wa jẹri tako olorin naa.
Agbefọba M. Abdulkareem to fẹsun kan olorin naa jẹ ko di mimọ pe ọlọpaa meji ni Okikiola lu lalubami nigba ti wọn lo fi ṣikun ofin gbe e lọjọ kẹwaa, oṣu Kinni, ọdun yii.
O ni awọn meji kan, Ebuka Odah ati Adeyanju Busayo ni wọn lọ fi ẹjọ Portable sun ni teṣan ọlọpaa to wa ni Ọta.
Abdulkareem sọ pe latigba naa ni wọn ti n fiwe pe Portable, ṣugbọn ti ko yọju.
Ki lo ṣẹlẹ ni kootu?
Nigba to n pe awon ẹlẹri meji lati wa sọ tẹnu wọn, awọn ọlọpaa meji to yọju sọ pe alubami ni Portable lu awọn lọjọ naa, to si jẹ pe ile iwosan ni awọn ti lọ gba itọju, ko to di pe ara wọn balẹ.
Ọlọpaa-binrin Ogungbe Olayemi to kọkọ sọrọ, jẹ ko di mimọ pe ẹṣẹ nla ni Portable fun oun loju, to si tun da apa si gbogbo ọwọ oun.
O ni ka ni ki i ṣe nipa iranlọwọ awọn ọlọpaa akẹgbẹ oun ni, boya lilu naa ko ba kọja ohun ti ẹnikẹni ko lero.
"Lọjọ keji, oṣu Kinni ọdun 2026 ni awọn meji kan, Ebuka Odah ati Adeyanju Busayo wa fi ẹsun kan Habeeb Okikiola pe o lu awọn, bẹẹ lo tun ja wọn lole.
"Oniruuru iwe la fi ranṣẹ si Portable lati wa sọ tẹnu rẹ, ṣugbọn ti ko yọju. Idi ree ti wọn fi sọ pe ka lọ fi ọwọ ofin gbe e.
"Awọn kan lo ta wa lolobo pe Okikiola wa nilẹ ounjẹ igbalode kan lagbegbe Osi, to wa ni Ọta. Loju ẹsẹ ni SP Hamzat Bashir, ASP Apata Musibar, Aremu Odunola ati emi ti dide lati lọ ba a.
"Bi a ṣe debẹ, a sọ fun Okikiola pe ọga wa fẹẹ ri i ni teṣan, o si sọ pe yoo tẹ oun lọrun lati ku, ju koun tẹle wa lọ. Loju ẹsẹ nibẹ lo ti gba emi ati ẹnikeji mi, Aremu Odunola lẹṣẹ loju, to si lu wa lalubami lọjọ naa.
"Awọn ọlọpaa to ku ni wọn ṣe iranwọ ti a fi gbe e de teṣan lọjọ naa."
Olayemi sọ bẹẹ niwaju ile-ẹjọ.
Ẹlẹri keji toun naa jẹ ọlọpaa, Odunola, ni iyalenu lo jẹ foun pe nigba ti Portable n ba awọn lagidi, niṣe lo bọ ṣokoto rẹ, to si loun yoo ku sawọn lọrun bi wọn ba fẹẹ gbe oun ni tipatipa.
Agbẹjọro Okikiola, Ọgbẹni Arasanmi, nigba to n gbe lẹyin onibara rẹ, sọ pe yoo wu oun ki ile ẹjọ foju aanu wo olorin naa nipa gbigba beeli rẹ.
Arasanmi sọ pe Okikiola ni anfaani si ẹtọ mẹta, lara rẹ si ni ki wọn da ẹjọ naa nu, pe ko ni ẹjọ kankan lati jẹ.
Onidajọ ile-ẹjọ naa, Adajo O. A Sodunke, nigba to n foju aanu wo olorin takasufe ọhun, paṣẹ pe ki wọn gba beeli Portable pẹlu miliọnu kan naira ati oniduro meji.
Ile-ẹjọ sọ pe Portable yoo wa ni ọgba atunṣe to wa ni Ibara niluu Abeokuta titi digba ti yoo fi ri ọrọ beeli rẹ yanju.
O wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ keji, oṣu Keji, ọdun 2026.
Oni ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni gbajumọ olorin, Habeeb Okikiola Badmus ti gbogbo eeyan mọ si Portable, tabi Were olorin, yoo tun foju bale ẹjọ lẹyin aṣẹ kootu pe ki wọn ju u si ahamọ fun ọsẹ kan.
Tẹ o ba gbagbe, ile ẹjọ majisreeti to wa niluu Ota, nipinle Ogun ni wọn ti gbọ ẹjọ miran ti Portable tun n jẹ, lọjọ Aje ọsẹ to kọja.
Ọmọ Ọlalọmi bo ṣe tun maa n pe ara rẹ, foju ba kootu lọjọ naa lori ẹsun ṣiṣe ọkan ninu awọn obinrin to bimọ fun un, Ashabi Simple, baṣubaṣu.
Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan Portable pe o huwa abuku si ọlọpaa obinrin kan to wa lara awọn agbofinro to fẹ mu un lori ẹsun ti wọn kọkọ fi kan an.
Lapapọ, koko ẹsun mẹsan-an ni wọn fi kan Portable lati jẹjọ rẹ.
Lẹyin igbẹjọ naa ni adajọ kọ lati yọnda rẹ pe ko maa gba ile waa jẹjọ, o ni afi toun ba ri ọlọpaa to fi abuku kan ni kootu.
Eyi ni wọn fi ju u si ahamọ ọsẹ kan.
Ki ni Portable ṣe gan-an?
Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo fi ẹsun onikoko mẹsan-an kan Portable, gẹgẹ bi iwe ẹsun lati olu ileeṣẹ agbofinro naa ṣe kede.
Ileeṣẹ ọlọpaa naa sọ pe Were olorin fiya jẹ ọlọpaa obinrin, Inspector Ogunge Olayemi ati awọn eeyan marun-un miran, lọjọ akọkọ ninu oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii.
Bakan naa ni wọn fẹsun jiji mọto ayọkẹlẹ, Benz E300 kan olorin naa, wọn ni miliọnu mejila naira niye owo ọkọ ọhun, ati pe ẹnikan to n jẹ Ileyemi Damilola David, lo ni mọtọ naa.
Wọn tun fi ẹsun kikọ lati jẹ ki ọlọpaa mu un kan Portable pẹlu.
Ile igbafẹ rẹ to wa ni Iyana Ilogbo, niluu Ota ni Ọmọ Olalomi ti huwa naa bawọn ọlọpaa ṣe wi.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe Portable tun fiya jẹ ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Ileyemi Damilola David, wọn lo ṣa a ni aake ni gbogbo ara, eyi to lodi labẹ ofin ipinlẹ Ogun, abala 383.
Obinrin kan ti wọn pe ni Akinyanju Oluwabusayomi naa tun fara gba ninu ijiya Portable, wọn lo gba a leti .
Wọn loun atawọn eeyan rẹ naa tun ṣa ẹnikan to n jẹ Olowu Olamide ni aake ni gbogbo ara lọjọ kan ṣoṣo yii naa.
Eyi ati awọn ẹsun miran ni wọn fi kan Portable ati awọn marun-un miran ti wọn ti sa lọ bayii.
Gbogbo awọn ẹsun wọnyi lo lodi labẹ ofin ipinlẹ Ogun bi kootu ṣe wi, ti wọn si ni ijiya labẹ ofin 516, 351, 383, 389, ati 390 ofin iwa ọdaran ti wọn ṣe ni 2006.
BBC News Yoruba yoo maa mu abọ kootu oni wa bo ba ṣe lọ.