Awakọ̀ Anthony Joshua tún fojú ba ilé ẹjọ́, bí ìgbẹ́jọ́ náà ṣe lọ rèé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Igbẹjọ awakọ to wa ọkọ gbajugbaja afẹṣẹkubiojo ọmọ Naijiria nni, Anthony Joshua, Kayode Adeniyi to ni ijamba lọdun to kọja eyi to ṣokunfa iku awọn eeyan meji tun waye ni Ile ẹjọ Majisireeti akọkọ to wa niluu Sagamu, ipinlẹ Ogun.

Ni ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu Kiini, ọdun 2026 ni igbẹjọ naa tun waye ti Onidajọ Olufunmilayo Somefun to n gbọ ẹjọ naa si sun siwaju lẹyin ti agbefọba Richard Nigiwe bẹbẹ pe ki wọn fun awọn laaye lati le ṣe awọn ẹda ẹjọ naa sọwọ.

Ṣaaju ni Nigiwe ti sọ fun ile-ẹjọ pe awọn ko nii le tẹsiwaju ẹjọ naa nitori awọn igbesẹ ti awọn n gbe lọwọ, lara rẹ ni ti imọran to lawọn fẹẹ gba lati ọdọ ajọ DPP, iyẹn Director of Public Prosecution.

O sọ pe awọn yoo kọwe si ajọ DPP pẹlu aṣẹ adajọ agba nipinlẹ naa, lati le fun wọn ni aṣẹ lati ṣe awọn ẹda iwe ipẹjọ naa ko to o di pe awọn yoo tẹsiwaju.

"Lẹyin ti a ṣagbeyẹwo awọn ohun to wa ninu iwe ipẹjọ naa, a rii pe a nilo lati ṣe awọn ẹda rẹ, lati le gba aṣẹ lọdọ ajọ DPP lati pe mọ boya a maa tẹsiwaju lori ẹjọ naa," Nigiwe sọ bẹẹ fun ile-ẹjọ.

Bi o tilẹ jẹ pe agbẹjọro awakọ naa, Olalekan Abiodun ko kọkọ gba sisun ẹjọ naa siwaju, pẹlu bo ṣe sọ pe ọna lati jẹ ki ẹjọ naa di ti ọlọjọ gbọọrọ lai nidii ni ọlọpaa n wa.

Abiodun sọ pe niwọn igba to jẹ pe ijọba lo pe onibaara oun lẹjọ, o yẹ ki wọn ti ṣe gbogbo eto wọn lọna to yẹ, ati pe awọn ṣetan lati tẹsiwaju ẹjọ naa.

Siwaju sii lo sọ pe gbogbo awọn ẹlẹrii mẹta ti ọlọpaa ranṣẹ pe ni wọn ti wa nile ẹjọ lati sọ tẹnu wọn, toun ko si ri idi kan ni pato lati sun ẹjọ ọhun siwaju.

Nigba to n gbe aṣẹ rẹ kalẹ, Onidajọ Somefun paṣẹ pe ki ẹjọ naa tẹsiwaju lọjọ Karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2026.

Ẹsun mẹrin ni Adeniyi n jẹjọ le lori to fi mọ wiwa ọkọ niwakuwa àti àìní ìwé àṣẹ láti fi wakọ̀ lábẹ́ òfin.

Kókó ẹ̀sùn mẹ́rin tí wọ́n fi kan awakọ̀ Anthony Joshua nílé ẹjọ́

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ṣalaye koko ẹsun mẹrin ti wọn fi kan awakọ Lexus SUV ti Anthony Joshua atawọn alabaṣiṣẹpọ rẹ meji wa ninu rẹ, eyi to ni ijamba lọna marosẹ ilu Eko si Ibadan lọjọ Aje ọsẹ yii.

Lonii ọjọ keji oṣu Kinni ọdun 2026 ni awakọ naa, Adeniyi Kayode, foju ba ile ẹjọ majisireeti to wa niluu Sagamu nipinlẹ Ogun.

Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan awakọ naa ni pe o wa ọkọ lọna to lewu eyi to ṣokunfa iku awọn eeyan.

Eleyii ni igbimọ olupẹjọ sọ pe o tako abala 5(1) ofin ọna marosẹ ijọba apapọ ti ọdun 2004.

Ẹsun keji ti wọn fi kan Ọgbẹni Kayode ni ẹsun aibikita ati wiwa ọkọ ni iwakuwa eyi to lodi sofin ọna marosẹ ijọba apapọ ti ọdun 2004.

Wiwa ọkọ lai na-an ni nnkan to le ṣẹlẹ lẹsun kẹta ti wọn fi kan Ọgbẹni Kayode, ati pe wọn lo tun ṣakoba fawọn to wa ninu ọkọ naa ti wọn fi farapa.

Labẹ ẹsun yii kan naa ni wọn tun ti sọ pe awakọ naa ba dukia jẹ eyi to lodi si abala 7(1) ofin ọna marosẹ ijọba apapọ ti ọdun 2004.

Ẹsun kẹrin ti wọn fi kan awakọ Anthony Joshua ni pe o n wa ọkọ lai ni iwe ẹri iwakọ to yanranti lọwọ, eyi to lodi abala 10(1) ofin ọna marosẹ ijọba apapọ.

Lẹyin o rẹyin, ile ẹjọ fun awakọ naa ni beeli pẹlu miliọnu marun un naira (N5m) ati oniduro meji eyi ti wọn ti ṣe amuṣẹ rẹ to si n jẹjọ lati ile.